“Ìtẹ̀jáde Lati Ọwọ́ Awọn Ẹlẹrii Jehofah Yẹ ni Kíkà”
Eyi ni àkọlé ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ kan tí ó farahàn ninu Creston News Advertiser, ti Iowa, U.S.A., ní December 23, 1988. “Ìmọ̀-ọ̀ràn ati ìsìn fa ọkàn-ìfẹ́ mi mọ́ra,” ni ọ̀rọ̀ àkíyèsí Randy Porter tí ó jẹ́ onkọwe kan, “ṣugbọn awọn ìtẹ̀jáde naa tún ní awọn ìtàn tí wọn ko fi bẹẹ jẹmọ ti isin nipa oniruuru awọn àríyànjiyàn yiyanilẹnu ninu ayé. . . .
“Siwaju sii, ó lè ya awọn kan lẹ́nu lati mọ̀ pe awọn ìwé-ìròhìn naa saba maa nfa ọ̀rọ̀ yọ lati awọn orísun aláṣẹ miiran, yàtọ̀ sí Bibeli. . . .
“Lọna àkọsẹ̀bá, ẹ̀dà ìtẹ̀jáde ti July 22, 1989, pẹlu gbé ìtàn kúkúrú ati fọ́tò aláwọ̀ mèremère nipa àpáta ilẹ̀-ìjọba Iowa, ti njẹ geode jáde lọna àkànṣe. Ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ naa sọ pe awọn eniyan dabi geode. Bí ó tilẹ ní ìrísí ṣákálá lásán lẹhin òde, nigbati a bá ṣí inú rẹ̀ geode a maa ṣípayá ẹwà inú lọ́hùn-ún dídányanranyanran, ti crystal. Eniyan kan, pẹlu lè ní ìrísí ṣákálá lásán ní òde, kódà ó lè jẹ́ ẹni jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ati onítìjú; bí ó ti wù kí ó rí, nigbati ẹnikan bá lò ‘àkókò lati di ojúlùmọ̀ pẹlu rẹ̀, wọn a ṣísílẹ̀ wọn a sì fi ẹwà inú lọ́hùn-ún hàn ọ eyi tí ó ńtànyòò.’ . . .
“Ìtẹ̀jáde ti July 22, 1989, naa ní ọ̀pọ̀ awọn ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ miiran ninu eyi tí ó jẹ́ pé o ṣeeṣe ki wọn ma ti kọjá lórí tábìlì mi, pẹlu! Fun apẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ julọ awọn eniyan ti gbọ́ nipa awọn oyin apani ti Africa, ṣugbọn ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ kan sọ̀rọ̀ nipa bí awọn onímọ̀ nipa kòkòrò ṣe ‘ńdọdẹ’ awọn oyin naa. Eyi tí a wéwèé lati ọwọ́ awọn onímọ̀-iṣẹ́-ẹ̀rọ America, ẹ̀rọ kọ̀m̀pútà bín-íntín kan ti o kere tobẹẹ lati somọ́ ẹ̀hìn oyin kan yoo ran awọn onímọ̀-ìjìnlẹ̀ lọwọ lati tọpasẹ ìfòkáàkiri kòkòrò oyin naa lati kilomita kan sí meji.”
Ji! ní awọn onkọwe-onirohin rẹ̀ ní ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè yíká-ayé ati nitori naa ó ní awọn orísun ìròhìn tí kò sí ní àrọ́wọ́tó fun ọpọlọpọ. Awa nímọ̀lára pe iwọ lè jàǹfààní lati inú rẹ̀ kí o sì gbádùn awọn ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ Ji! tí wọn fa ìfẹ́ mọ́ra. Ó ní ìpíndọ́gba ẹ̀dá ìtẹ̀jáde 12,980,000 fun ìtẹ̀jáde kọọkan a sì ńtẹ̀ ẹ́ jáde ní 64 èdè.
Emi yoo fẹ́ ìsọfúnni siwaju síi lórí bí emi ṣe lè maa gba Ji! déédéé ní ilé mi. (Kọwe sí adirẹsi tí nbẹ nísàlẹ̀ fun ìsọfúnni.)