Ji!—Ni A Mọrírì Lọna Gbígbòòrò
Ji! ni a ńtẹ̀jáde ní 64 èdè, ó sì ní ìpíndọ́gba itẹjade 12,980,000 ẹ̀dà fun itẹjade kọọkan. Awọn onkawe lati apa ibi gbogbo ninu ayé ńgbádùn rẹ̀ wọn sì ńjèrè lati inú rẹ̀, gẹgẹbi awọn lẹ́tà ìmọrírì wọn ti fihan. Ẹ̀ka ilé-iṣẹ́ Watch Tower ni Thailand rí ìbéèrè tí ó tẹ̀lé e yii gbà:
“Ilé-ẹ̀kọ́ wa ńrí iwe-irohin Ji! [lédè Thai] gbà déédéé, a sì kiyesi pe itẹjade September 8, 1988, jẹ́ lori kókó-ọ̀rọ̀ naa ‘Ẹyin Òbí,’ eyi tí ó yẹ kí gbogbo awọn òbí tí wọn ní ọmọ ní ilé-ẹ̀kọ́ kà. Nitorinaa awa yoo fẹ́ pe kí ẹ fi 250 sí 400 ẹ̀dà ranṣẹ sí wa, bí wọn bá wà lárọ̀ọ́wọ́tó, fun ìpínkiri nigba ipade awọn òbí-ati-olùkọ́ tí ńbọ̀.”
Obinrin kan lati Roanoke, Virginia, U.S.A., kọ̀wé pe: “Emi jẹ́ olùfọkànsìn onísìn-Baptist . . . , ṣugbọn mo ṣalábàápàdé ọ̀kan lara iwe-irohin yin Ji! ninu Ilé-ìfọṣọ kan ní àdúgbò ó sì ti là mi lóye gan-an. Mo ti gbadun kíkà á.”
Awa nimọlara pe iwọ pẹlu yoo janfaani lati inu rẹ̀ iwọ yoo sì gbadun awọn ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí ńfanimọ́ra ninu Ji!
Emi yoo fẹ́ ìsọfúnni siwaju síi lórí bí emi ṣe lè maa gba Ji! déédéé ninu ilé mi. (Kọwe sí adirẹsi tí nbẹ nísàlẹ̀ fun ìsọfúnni.)