ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 6/1 ojú ìwé 32
  • “Ohùn-Orin Tí Ńmúniláradá”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Ohùn-Orin Tí Ńmúniláradá”
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 6/1 ojú ìwé 32

“Ohùn-Orin Tí Ńmúniláradá”

Obinrin kan lati Spain kọ̀wé sí ẹ̀ka Watch Tower ti Germany pe: “Mó kún fun ìmoore gan-an tí ó fi jẹ́ pe mo nilati kọ̀wé lati sọ fun yin nipa rẹ̀.” Eeṣe ti oun fi kún fun ìmoore tobẹẹ?

“Mo ti gbé ní Spain fun nǹkan bii ọdun mẹsan-an,” ni oun ṣalaye, “ọdun kan ati ààbọ̀ sẹhin, meji lára awọn ọ̀dọ́ yin bẹ̀rẹ̀ síi kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹlu mi. Bí mo ti kà ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ kan ninu Ilé-ìṣọ́nà nipa ohùn-orin tí ńmúniláradá, mo sọ fun wọn lati gbà awọn kasẹẹti naa fun mi.

“Ní àkókò kan lẹhin igba naa, bí mo ti ńnímọ̀lára ìsoríkọ́ ti mo sì wà ninu ìrora, mo gbé ohùn-orin naa sí i. Ẹ wo ìyàtọ̀ tí ó mú wá! Laaarin àkókò kúkúrú, ìrora èrò-ìmọ̀lára naa ti lọ, ipò ọkàn mi sì ti sunwọn sii jọjọ. Bawo ni inu mi ti dùn tó lati ní awọn kasẹẹti ohùn-orin wọnyẹn. Lati ìgbà naa wá, mo ti maa nfigbagbogbo fetisilẹ sí wọn laaarin awọn alẹ́ àìróorunsùn. Ó jẹ́ ohùn-orin tí ńmúniláradá nitootọ-gidi.”

Ọpọ eniyan ti wá mọriri album naa Sing Praises to Jehovah, tí ó ní-nínú kasẹẹti mẹjọ. Bí iwọ bá ní ọkàn-ìfẹ́ sí gbígbà album yii kọ ọ̀rọ̀ kún àlàfo tí ó wà ní ìsàlẹ̀ yii kí ó sì firanṣẹ.

Emi yoo fẹ́ lati gba album naa Sing Praises to Jehovah tí ó ní kasẹẹti mẹjọ ti teepu olóhùn-orin ninu. (Kọwe si adirẹsi tí ńbẹ nisalẹ fun isọfunni.)

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́