Akoko Dídárajùlọ Ninu Igbesi-Aye
Ọdọmọde kan lati Nigeria, Iwọ-oorun Africa, kọwe lẹnu aipẹ yìí pe: “Tẹlẹri, mo lérò pé igba ewe ni akoko tí ó le julọ ninu igbesi-aye eniyan ati pe ọjọ ori aláyọ̀ julọ ni ọjọ ori naa nigba ti eniyan bá jẹ́ baba tabi iya tabi nigba ti oun bá jẹ́ agbalagba atójúúbọ́ kan.”
Ṣugbọn lẹhin naa ọdọmọde ara Africa yii gba ẹ̀dà kan iwe naa Igba Ewe rẹ—Bi o ṣe le Gbadun rẹ̀ Julọ. “Ẹ ṣeun pupọ gan-an,” ni oun kọwe. “Iwe yii ti ràn mí lọ́wọ́ ní ọpọlọpọ ọna.” Ó fikun un pe: “Nisinsinyi, lẹhin kíka iwe yii, mo mọ lẹkun-unrẹrẹ pe igba ewe ni ọjọ ori dídárajùlọ.”
Awọn èwe tí wọn ndagbasoke ní awọn akoko onídààmú wọnyi dojúkọ ọpọlọpọ ipò titun wọn sì gbọdọ ṣe awọn ipinnu títẹ̀wọ̀n. Ewe kan ha nilati mu sìgá tabi tẹwọgba oògùn bí? Iwa wo ni ó bojumu pẹlu ọ̀kan ninu ẹ̀yà keji? Ki ni nipa ìdánìkanhùwà ibalopọ ati ìbẹ́yà-kannáà-lòpọ̀?
Awọn ipinnu tí kò tọ̀nà lè yọrisi oniruuru ibanujẹ ọkàn gbogbo ati idaamu. Igba Ewe rẹ—Bi o ṣe le Gbadun rẹ̀ Julọ gbé gbogbo awọn ibeere òkè yii yẹ̀wò ati ọpọlọpọ síi. Bí iwọ yoo bá fẹ́ lati gba ẹ̀dà kan, jọwọ kọ ọ̀rọ̀ kún àlàfo kí o sì fi ranṣẹ fun isọfunni.
Emi yoo fẹ́ ki ẹ fi isọfunni ti bi mo ṣe lè gba ẹ̀dà iwe ẹlẹ́hìn-líle olójú-ewe 192 naa Igba Ewe rẹ—Bi o ṣe le Gbadun rẹ̀ Julọ ranṣẹ si mi.