Oun Rí Ìwé-Àṣàrò-Kúkúrú kan Loju Ọna Rélùwéè
ỌDUN naa jẹ́ 1921. Ní awọn ilẹ̀ gíga ti Transvaal, ẹkùn-ìpínlẹ̀ kan ni South Africa, awujọ awọn ọkunrin ti ntọju ọna reluwee ńṣiṣẹ́ wọn lọ ni ipa ọna reluwee kan ti o lọ rangbọndan. Olùṣàbójútó agbo òṣìṣẹ́ naa, ara South Africa kan tí orukọ rẹ njẹ Christiaan Venter, kíyèsí abala pépà kan ni kikapọ tí a tìbọ abẹ́ lagalaga irin ọna reluwee. Ó jẹ́ ìwé-àṣàrò-kúkúrú tí a tẹ̀jáde lati ọwọ́ Watch Tower Bible and Tract Society.
Lẹhin pípàṣẹ fun awọn oṣiṣẹ rẹ̀ lati dáwọ́dúró, Christiaan ka ìwé-àṣàrò-kúkúrú naa pẹlu ọkàn-ìfẹ́ mímúná. Oun sáré lọ bá ọkọ ọmọbinrin rẹ̀, Abraham Celliers, ó sì polongo pẹlu ìgbónára: “Abraham, lonii mo ti rí otitọ!”
Kété lẹhin igba naa, wọn kọ̀wé sí awọn ti wọn tẹ ìwé-àṣàrò-kúkúrú naa jade fun ìsọfúnni síi. Ní ìdáhùnpadà, ẹ̀ka Watch Tower Society ni South Africa fi àfikún ìwé-ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ranṣẹ. Awọn ọkunrin mejeeji kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ papọ̀ láàárín àkókò ounjẹ ọ̀sán wọn ati wọnú wákàtí òru. Láìpẹ́ wọn bẹrẹsii ṣàjọpín otitọ naa pẹlu awọn ọ̀rẹ́ ati àlejò.
Àsẹ̀hìnwá-àsẹ̀hìnbọ̀, Christiaan ati Abraham di Ẹlẹrii olùṣèyàsímímọ́ fun Jehofa. Gẹgẹbi ìyọrísí ìtara ati ìṣòtítọ́ wọn, ọpọlọpọ awọn ara South Africa miiran ni a ranlọwọ lati wá sínú ìmọ̀ otitọ naa. Siwaju síi pẹlu, iye tí ó ju ọgọrun-un ninu awọn atọmọdọmọ wọn jẹ́ Ẹlẹrii Jehofa agbekankanṣiṣẹ lonii! Ọ̀kan ninu wọn ńṣiṣẹ́sìn ní orílé-iṣẹ́ awọn Ẹlẹrii Jehofa ní Brooklyn, New York, òmíràn ní ilé-iṣẹ́ Watch Tower Society ní South Africa.
Lonii, ní nǹkan bíi 70 ọdun lẹhinnaa, ìwé-àṣàrò-kúkúrú Bibeli nbaa lọ lati kó ipa pàtàkì ninu títan ìhìn-iṣẹ́ Ijọba naa kálẹ̀.