Ọ̀nà Dídíjú Lati Dé Ọdọ Ọlọrun
“EMI ni ọ̀nà, ati otitọ, ati ìyè: ko si ẹnikẹni ti o le wa si ọdọ Baba, bikoṣe nipasẹ mi,” ni Jesu Kristi wi. Oun fi kun un pe: “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wi fun yin, ohunkohun ti ẹyin ba beere lọwọ Baba ni orukọ mi, oun o fi fun yin.”—Johanu 14:6; 16:23.
Bi o ti wu ki o ri, fun ọpọ ọrundun, awọn isin Kristẹndọm, paapaa Ṣọọṣi Roman Katoliki, pẹlu awọn ẹkọ-igbagbọ iná ọrun àpáàdì, Purgatory, ati Mẹtalọkan rẹ, ti mu “ọna” naa dojúrú. Jesu ni a nfihan ninu àwòrán kii ṣe gẹgẹ bi onílàjà ti o muratan fún awọn eniyan ẹlẹṣẹ, ṣugbọn gẹgẹ bi ọmọ àṣẹ̀ṣẹ̀bí ti a gbé lọ́wọ́ tabi gẹgẹ bi onidaajọ ti o ni irisi ẹ̀rù kan, ti o ni aṣa dídáni lẹbi ati fífìyà jẹ awọn ẹlẹṣẹ ju ki o gbà wọn là lọ. Bawo, nigba naa ni ẹlẹṣẹ kan ṣe le de ọdọ Ọlọrun?
Iwe naa The Glories of Mary (1750) ṣàlàyé. Ni fífi Jesu wé oòrùn idajọ-ododo ti nranyoo, pope Innocent Kẹta ti ọrundun kẹtala polongo pe: “Ẹniyoowu ti o ba wa ni òru ẹ̀ṣẹ̀, jẹ ki o yi oju rẹ si oṣupa naa, jẹ ki o bẹ Maria.” Ninu Maria, iya Jesu, onilaja miiran ni a hùmọ̀. Boya nipasẹ agbara idari ti wọn rò pe o ni nitori pe o jẹ iya, oju rere ni wọn lè jèrè lati ọdọ Jesu ati lati ọdọ Ọlọrun. Nipa bayi, ninu awọn ọrọ Laurence Justinian, alufaa kan ni ọ̀rúndún kẹẹ̀dógún, Maria di “àtẹ̀gùn lọ si Paradise, ìlẹ̀kùn sí ọrun, alárinà obinrin tootọ julọ láàárín Ọlọrun ati eniyan.”
Pẹlu gbogbo ìpọ́nni ti a fi fun un, nigba tí ó ṣe a ko wò ó gẹgẹbi “Maria Wundia” nikan mọ ṣugbọn o di “Ọbabinrin Mimọ, Ìyá Àánu,” ti a sọ lorukọ gẹgẹbi aláìlẹ́ṣẹ̀ ti a si gbe e ga debi pe oun tun di ẹni ti o jẹ́ mimọ jù lati tọ̀ lọ tààràtà. Njẹ a le ri onilaja miiran? Ki ni nipa ti ìya rẹ̀?
Niwọnbi Bibeli kò ti sọ ohunkohun lori kókó ẹ̀kọ́ naa, ìdáhùn ni a wá lọ si ibomiran. Iwe ti kii ṣe apakan Bibeli naa Protevangelium of James sọ itan Anne (tabi Anna), aya Joakimu ẹni ti o jẹ àgàn lẹhin ọpọlọpọ ọdun igbeyawo. Nikẹhin, angẹli kan farahàn án o si kede pe oun yoo bi ọmọ kan. A sọ pe, ni akoko ti o yẹ, oun di iya “Maria Wundia” naa.
Nipa bayii ohun ijinlẹ awo Anne ẹni “mimọ.” Awọn Ojúbọ ati ṣọọṣi ni a kọ́ lati bọla fun un. Ibọwọ jijinlẹ fun Anne ẹni “mimọ” di eyi ti o gbilẹ ni Europe ni ọ̀rúndún kẹrinla.
“Bawo ni isin ti wa díjúpọ̀ to!” ni ìwé naa The Story of the Reformation sọ. “Awọn eniyan gbadura si Anna ẹniti yoo ṣalagbawi lọdọ Maria ẹni ti yoo bẹbẹ lọdọ ọmọkunrin rẹ ẹni ti yoo bẹbẹ lọdọ Ọlọrun fun awọn eniyan ẹlẹṣẹ. O jẹ ohun ti ko ṣee gbagbọ, ṣugbọn iyẹn ni iru igbagbọ ninu ohun asan ti a fi nbọ ọkàn awọn eniyan.” Nigba naa, nihin-in, ni ọran miiran wà ninu eyi ti awọn ọrọ Jesu ti ṣeé fisilo ni wẹ́kú pe: “Ẹyin sọ ọrọ Ọlọrun di asan nipasẹ ofin àtọwọ́dọ́wọ́ yin.”—Maaku 7:13.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 21]
The Metropolitan Museum of Art, Bequest of Benjamin Altman, 1913. (14.40.633)