ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 4/1 ojú ìwé 30
  • Iṣelu—O Ha Jẹ́ Apakan Iṣẹ́ Ihinrere Ti A Fi Ran ni Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Iṣelu—O Ha Jẹ́ Apakan Iṣẹ́ Ihinrere Ti A Fi Ran ni Bí?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 4/1 ojú ìwé 30

Iṣelu—O Ha Jẹ́ Apakan Iṣẹ́ Ihinrere Ti A Fi Ran ni Bí?

GẸGẸ BI Joachim Meisner, biṣọọbu agba Cologne ati gbajumọ alufaa Ila-oorun Germany tẹlẹri ti wi, “o jẹ́ àdámọ̀ lati pe iṣelu ni ohun idọti, iṣẹ òwò kan ti ẹnikan fi nsọ ọwọ rẹ di alaimọ.” Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan ni 1989, o sọ pe: “Iṣelu jẹ́ ohun kan ti o wa nitootọ ninu igbesi-aye ati nitori naa ó jẹ́ apakan iṣẹ ihinrere ti a fi ran wa. A gbọdọ mura lati koju ipenija naa. Lọna ti o gbeṣẹ, a gbọdọ wọnu gbogbo eto idasilẹ iṣelu, lati ori ẹgbẹ ati ajọ oṣiṣẹ titi de ori awọn ẹgbẹ iṣelu, ni fifi ipilẹ animọ Kristian lelẹ ninu awọn ẹgbẹ ati ajọ igbokegbodo wọnyi lati inú eyi ti ẹnikọọkan le jade wa lati wá mú ipo iwaju ninu gbigbe iṣelu Europe ati Germany ga.”

Awọn ọrọ ti a fayọ ti o tẹlee wọnyi lati inú Frankfurter Allgemeine Zeitung, iwe irohin ti o gba ipo iwaju ni Germany, fihan pe ọpọlọpọ awọn alufaa Europe—Katoliki ati Protestant lapapọ—ní oju iwoye tí Meisner ni yii.

“Kiki ọjọ mẹfa lẹhin ti a yan an sipo [October 1978], oun [Poopu] kede pe gẹgẹ bi ọmọ Ila-oorun Europe oun kò ni itẹsi ọkan lati faramọ ipo awọn nnkan ni Europe. . . . Awọn kan kà á si ọrọ iwaasu, ṣugbọn o jẹ eto oṣelu.”—November 1989.

“Ni awọn ibikan [ni Czechoslovakia] igbeniyi nlanla ni a fun ṣọọṣi gẹgẹ bi olewaju kan ninu irukerudo naa. Awọn akẹkọọ ni ile ẹkọ isin fun awọn alufaa Litomĕr̆ice, ilu oniṣọọṣi katidrali kan ni Ariwa Bohemia, . . . mu ipo ninu iyipada tegbòtigaga ti a ṣe wọ́ọ́rọ́wọ́ ni November ti o kọja.”—March 1990.

“Adura ọsọọsẹ fun alaafia ti a ngba ninu Ṣọọṣi [Protestant] ti Nikolai, eyi ti ko gba afiyesi ti o pọ̀ fun odidi ọdun mẹwaa, lojiji wá di ami irukerudo iyipada tegbòtigaga onirọwọrọsẹ ti ó ṣẹlẹ ni [German Democratic Republic] ninu ọdun yii. . . . Aimọye awọn alufaa ati awọn ọmọ ijọ ni wọn nkopa deedee ninu awọn iwọde ti a nṣe lati igba naa wá.”—December 1989.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo rẹ Biṣọọbu agba Meisner tun ṣakiyesi pe: “A ko le duro fun awọn Kristian oṣelu lati jábọ́ lati ọrun. . . . Emi ko ṣaarẹ ri lati fun awọn ọdọ Kristian niṣiiri . . . lati ko wọnu igbesi-aye oṣelu [tabi ti] . . . sisọ fun awọn agbaagba ọlọtọ pe: Ẹ ko gbọdọ jẹ ki idibo kan kọja laijẹ pe ẹ lọwọ ninu rẹ̀.”

Ni ibamu pẹlu eyi, mẹmba 19 ti wọn wà ninu Volkskammer (igbimọ aṣofin) Ila-oorun Germany ti a diboyan sẹnu iṣẹ ni March 1990 jẹ awọn alufaa. Isin ni a si ṣoju fun daradara ninu ẹgbẹ alajọṣakoso naa. Nipa ẹnikan lara awọn alufaa mẹtẹẹta rẹ̀, Alaboojuto Fun Idaabobo Ilu Lọwọ Igbogunti [Minister of Defense] Rainer Eppelmann, apolongo lodisi ogun, iwe irohin naa Nassauer Tageblatt kọwe pe: “Ọpọlọpọ ni o kà á sí ọkan lara awọn baba isalẹ iyipada tegbòtigaga onirọwọrọsẹ naa.”

Awọn Ẹlẹrii Jehofa ni Ila-oorun Europe, ti iye wọn pọ̀ to ọgọọgọrun lọna ẹgbẹẹgbẹrun, yọ ayọ si ominira isin ti o pọ sii ti wọn ni nisinsinyii. Ṣugbọn wọn ko lò ó lati kó wọnu awọn ariyanjiyan oṣelu tabi ti ẹgbẹ-oun-ọgba. Ni ibamu pẹlu iṣẹ ihinrere ti a fi ran wọn ti a sọ ninu Matiu 24:14, wọn ntẹle apẹẹrẹ Jesu ninu yiyẹra fun iṣelu eniyan, ni fifi itara waasu ihinrere Ijọba Ọlọrun nigba gbogbo gẹgẹ bi ireti kanṣoṣo fun araye. Awujọ alufaa Kristẹndọm—yala ni Ila-oorun Europe tabi nibomiran—yoo jẹ́ ọlọgbọn lati huwa lọna ti o farajọ eyi.—Johanu 6:15; 17:16; 18:36; Jakọbu 4:4.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́