Ibeere Lati Ọwọ Awọn Onkawe
◼ Bawo ni Kristian kan ṣe nilati sapa gidigidi tó lati dena ifajẹsinilara tí ile-ẹjọ kan ti palaṣẹ tabi ti faṣẹ sí?
Ipo kọọkan ko baramu, nitori naa ko si ofin ti ó de gbogbo rẹ lori eyi. Awọn Kristian ni a mọ fun fifi ọwọ ‘san ohun ti í ṣe ti Kesari pada fun Kesari,’ ni ṣiṣegbọran si awọn ofin ijọba aye. Sibẹ, wọn mọ daju pe iṣẹ aigbọdọmaṣe wọn ti o ṣe pataki ju ni lati fi “ohun ti Ọlọrun fun Ọlọrun,” ni ṣiṣai ré ofin rẹ kọja.—Maaku 12:17.
Roomu 13:1-7 (NW) jiroro ipo ibatan awọn Kristian si “awọn alaṣẹ onipo gigaju” ti ijọba. Iru awọn ijọba bẹẹ ní aṣẹ lati ṣe awọn ofin ati lati mu awọn itọni jade, niye igba lati gbé ire alaafia awọn ara ilu ga ni gbogbogboo. Awọn ijọba si “gbé ida” lati fipa mu awọn ofin wọn ṣẹ ati ‘lati fi ibinu han lori awọn wọnni ti wọn sọ ohun ti o buru daṣa ni ibamu pẹlu awọn ofin wọn.’ Ni wiwa ni itẹriba si awọn alaṣẹ onipo gigaju, awọn Kristian fẹ lati ṣegbọran si awọn ofin ati awọn aṣẹ ile-ẹjọ, ṣugbọn itẹriba yii gbọdọ jẹ́ alaala. Bi a ba sọ fun Kristian kan lati juwọsilẹ fun ohun kan ti yoo ré ofin gigaju ti Ọlọrun kọja, ofin atọrunwa gbọdọ gba ipo kìn-ínní; o gba ipo iwaju.
Awọn ofin ode oni kan ti o dara ni ipilẹ ni a le ṣìlo fun fifaṣẹ si fifi ipa fa ẹjẹ sara Kristian kan. Ninu ọran yii awọn Kristian gbọdọ mu iduro kan naa ti apọsteli Peteru mu: “Awa ko gbọdọ ma gbọ ti Ọlọrun ju ti eniyan lọ.”—Iṣe 5:29.
Jehofa paṣẹ fun awọn ọmọ Isirẹli pe: “Pinnu laiyẹsẹ lati maṣe jẹ ẹ̀jẹ̀ nitori pe ẹjẹ ni ọkan, iwọ ko si gbọdọ jẹ ọkan pẹlu ẹran.” (Deutaronomi 12:23, NW) Itumọ Bibeli Juu kan ti 1917 kà pé: “Kiki ki o duroṣinṣin ninu aijẹ ẹjẹ.” Isaac Leeser si ṣetumọ ẹsẹ naa pe: “Kiki ki o duro gbọnyingbọnyin ki o ma baa jẹ ẹjẹ.” Njẹ iyẹn ha dun bi ẹni pe awọn iranṣẹ Ọlọrun ni wọn nilati fọwọ yẹpẹrẹ mu tabi ṣai ni itara nipa pipa ofin rẹ mọ?
Pẹlu idi rere awọn Kristian ti pinnu patapata lati ṣegbọran si Ọlọrun, ani bi ijọba ba tilẹ fun wọn ni itọni lati ṣe odikeji. Ọjọgbọn Robert L. Wilken kọwe pe: “Awọn Kristian ko wulẹ kọ iṣẹ-isin ologun [ti Roomu] silẹ nikan ni ṣugbọn wọn ko ni gba ipo iṣẹ ilu tabi tẹ́rígba ẹru-iṣẹ eyikeyi fun ṣiṣakoso awọn ilu.” (The Christians as the Romans Saw Them) Kíkọ̀ le tumọ si jíjẹ́ ẹni ti a sami arufin si lara tabi didi ẹni ti a dálẹbi fun papa iworan Roomu.
Awọn Kristian lonii gbọdọ tun jẹ aduroṣinṣin, ki wọn pinnu laiyẹsẹ lati maṣe ré ofin atọrunwa kọja, ani bi iyẹn ba tilẹ fi wọn sinu ewu awọn ijọba aye paapaa. Ofin giga julọ ni agbaye—ofin Ọlọrun—beere pe ki awọn Kristian yẹra fun aṣilo ẹjẹ, gan an gẹgẹ bi a ti pa a laṣẹ fun wọn lati yẹra fun agbere (iwa palapala takọtabo). Bibeli pe awọn ikaleewọ wọnyi ni “awọn ohun ti o pọndandan.” (Iṣe 15:19-21, 28, 29, NW) Iru ofin atọrunwa bẹẹ ni a ko nilati fọwọ dẹngbẹrẹn mu, gẹgẹ bi ohun kan ti a nilati ṣegbọran si kiki bi o ba dẹ̀ wá lọrun tabi ti ko ba gbé awọn iṣoro ka iwaju wa. Ofin Ọlọrun ni a gbọdọ ṣegbọran si!
Awa le mọriri, nigba naa, idi ti ọdọ Kristian ti a mẹnukan ni oju-ewe 17 fi sọ fun ile-ẹjọ kan pe “oun ka ifajẹsinilara si fífín ara rẹ níràn ti o si fi we ìfipábánilòpọ̀.” Obinrin Kristian eyikeyi, lọmọde tabi lagba, yoo ha fi irọwọrọsẹ juwọ silẹ fun ìfipábánilòpọ̀ bi, ani bi iyọnda nipasẹ ofin ba tilẹ wà pe agbere nipa ifipa kọluni ibalopọ takọtabo ni a le ṣe?
Lọna ti o farajọra, ọmọ ọdun 12 ti a mẹnukan ni oju-ewe kanna ko fi iyemeji kankan silẹ pe ‘oun yoo gbógun ti aṣẹ ifajẹsinilara ile-ẹjọ eyikeyi pẹlu gbogbo ipa ti oun ba lè sà, pe oun yoo figbeta ti oun si jà fitafita, ati pe oun yoo fa ohun eelo ifa nǹkan sinu ara naa jade kuro ni apa oun ti oun yoo si gbiyanju lati jo ẹjẹ ti o wà ninu apo naa loke ibusun oun.’ O pinnu laiyẹsẹ lati ṣegbọran si ofin atọrunwa naa.
Jesu fà sẹhin kuro ni agbegbe naa nigba ti ogunlọgọ kan fẹ lati sọ ọ́ di ọba. Lọna ti o fara jọra, bi ifajẹsinilara ti ile-ẹjọ kan paṣẹ rẹ ba dabi eyi ti yoo ṣeeṣe, Kristian kan le yan lati yẹra fun wiwa nitosi fun iru ìré ofin Ọlọrun kọja bẹẹ. (Matiu 10:16; Johanu 6:15) Ni akoko kan naa, Kristian kan nilati fi ọgbọn wá ọna abajade itọju iṣegun, ni titipa bayii ṣe isapa olotiitọ inu lati pa iwalaaye mọ ati lati jere ilera kikun pada.
Bi Kristian kan ba sapa gidigidi lati yẹra fun rire ofin Ọlọrun lori ẹjẹ kọja, awọn alaṣẹ le ka a si arufin tabi mu ki o dojukọ ipelẹjọ. Bi o ba yọri si ijiya, Kristian naa le wo o gẹgẹ bi ijiya nitori iwa ododo. (Fiwe 1 Peteru 2:18-20.) Ṣugbọn ni ọpọjulọ awọn ọran, awọn Kristian ti yẹra fun ifajẹsinilara ati pẹlu itọju iṣegun ti o múnádóko wọn ti jere ilera pada, ti o fi jẹ pe ko yọrisi awọn iṣoro ofin pipẹtiti. Ati ni pataki julọ, wọn ti pa iwatitọ wọn mọ si Olufunni ni Iye ati Onidajọ wọn ti Ọrun.