Itumọ Adura
“Ninu ede Heberu, ọrọ pataki ti a nlo fun adura wá lati inu gbòǹgbò ọrọ naa, ‘lati ṣedajọ’, iru ọrọ agbé ìṣe olùṣe yọ ti a saba maa nlo sì . . . tumọ ni olowuuru si, ‘lati ṣedajọ ara-ẹni.’” Bẹẹ ni The Authorised Daily Prayer Book ṣakiyesi. Itumọ ti o gbé yọ ni pe ọkan lara awọn ọna ti adura ngba ṣiṣẹ ni pe o nilati ran ẹni naa lọwọ lati ri i bi oun ba kún oju oṣunwọn ọpa idiwọn ododo ati awọn ohun ti Ọlọrun beere fún.
Fun idi yii, lati ibẹrẹ dopin Bibeli, a sọ fun wa pe ayafi bi ẹnikan ba nṣe ifẹ-inu Ọlọrun, adura rẹ ni a ki yoo gbọ́ pẹlu ojurere. “Oluwa [“Jehofa,” NW] jinna si awọn eniyan buburu; ṣugbọn o ngbọ adura awọn olododo.”—Owe 15:29; 1 Johanu 5:14.
Ayẹwo ara-ẹni niwaju Jehofa Ọlọrun dajudaju nilati mu ki ẹni ti ngbadura naa jẹ onirẹlẹ ati onirobinujẹ. Eyi fun akawe Jesu ti Farisi agberaga ati agbowo ode onirobinujẹ ọkan ti o wá sinu tẹmpili lati gbadura ni itumọ pataki.—Luuku 18:9-14.
Nipa bayii, yala a ngbadura lati dupẹ lọwọ Jehofa, yin in, tabi bẹ ẹ, adura jẹ akoko fun ayẹwo ara-ẹni nigba gbogbo. Ni ọna yii, adura fà wá sunmọ Jehofa pẹkipẹki o si fun ibatan wa pẹlu rẹ̀ lokun.