Awọn Olupokiki Ijọba Rohin
Wiwaasu “Itusilẹ Kan Fun Awọn Òǹdè” Ni Brazil
ẸMI Jehofa nṣiṣẹ pẹlu agbara lori awọn eniyan rẹ ni Brazil bi wọn ṣe nwaasu ihinrere ti itusilẹ fun awọn wọnni ti wọn wa ninu onde isin eke. (Aisaya 61:1, 2; Luuku 4:18) Ni 1947 kiki 648 awọn Ẹlẹrii ni wọn wa ni orilẹ-ede naa. Ni 1967 iye naa ti roke dé 41,548. Pẹlu ibukun Jehofa, ni ibẹrẹ 1991 o de gongo ti o rekọja 302,000! Nitootọ, ‘Ọlọrun nmu ki o dagba.’ (1 Kọrinti 3:7) Ni ọdun iṣẹ-isin 1990 nikan, 27,068 ni a baptisi.
Iru idagbasoke bẹẹ mu iṣeto ayika titun kan pọndandan loṣooṣu, ti a si nya 150 awọn Gbọngan Ijọba titun si mimọ ni kiki ọdun kan pere. Ju bẹẹ lọ, ẹka ile iṣẹ ra 450 sarè ilẹ lati mu ki awọn ohun eelo itẹwe wọn gbooro si, nibi ti wọn ti ntẹ awọn Bibeli nisinsinyi lori ẹrọ itẹwe tiwọn funraawọn. Nipa bayii awọn Ẹlẹrii ni Brazil nṣiṣẹ kára lati ran awọn ẹni ọlọkan tutu lọwọ lati jade kuro ni “Babiloni Nla” ṣaaju “ipọnju nla naa.”—Iṣipaya 7:9, 10, 14; 18:2, 4.
□ Akede ọmọ ọlọdun mẹjọ fi iwe kan silẹ fun iyawo ọga agba awọn ọlọpaa ati lẹhin naa, ni oun nikanṣoṣo, o ṣe ipadabẹwo. Ete rẹ jẹ lati mu ki iyaafin naa kà ninu awọn itan naa fun un ki o si mu ki o sọ fun oun ohun ti o ti loye lati inu itan kọọkan. Bi o ṣe nṣalaye awọn itan naa fun un, oun funraarẹ bẹrẹ sii mọriri iwe naa ti o si sọ fun un pe ki o mu oun mọ iya rẹ. Ó ṣe bẹẹ, nisinsinyi iyaafin naa ngbadun ikẹkọọ Bibeli inu ile deedee kan.
□ Ni 1984, agabagebe tí Maria kiyesi ninu awujọ ti sú u, a si mu un sọ ireti nù nitori awọn ijaba ti ó nka nipa rẹ ti nṣẹlẹ ninu aye. Nitori naa ó nawọgan ọna igbesi-aye awọn olorin ẹhanna. Ó wipe: “Gongo wa ni lati lodisi ohun gbogbo ati olukuluku eniyan. Irisi mi ni a humọ kiki lati dayafo awọn eniyan—awọn aṣọ alawọ dudu ti o ṣajeji, ori ti a fá apakan rẹ. Mo kọ ọkọ mi, awọn ọmọ, ati ile mi tì ti mo si bẹrẹ sii mu igbo ti mo si nlo kokeeni lati le yẹra fun ohun ti o jẹ otitọ. Ṣugbọn eyi wulẹ mu ki nnimọlara lọna ti o buru sii, mo sọkun. Nigba ti mo ka Bibeli, nko loye ohunkohun. Nitori naa mo gbadura si Ọlọrun fun iranlọwọ.
“Ni ọjọ kan, awọn Ẹlẹrii meji ṣebẹwo si ile mi, lẹhin ijiroro kukuru kan, wọn fi iwe irohin meji lọ̀ mi. Ni ṣiṣi ọkan ninu wọn gaaraga, mo ṣakiyesi ọrọ ẹkọ kan ti a fun ni akori naa ‘Àìfarati Ọlọrun—Eeṣe Tí Kò Fi Yẹ Bẹẹ?’a Ọrọ-ẹkọ naa gun ọkan aya mi ni kẹṣẹ. Mo nimọlara pe Ọlọrun ti dahun adura mi, ni ọjọ yẹn gan an, awọn Ẹlẹrii naa bẹrẹ si kẹkọọ Bibeli pẹlu mi. Lati igba yẹn siwaju mo ti ṣe awọn iyipada fun rere. Ọkọ mi ati idile mi tako ikẹkọọ Bibeli mi lakọọkọ, ṣugbọn bi wọn ṣe ri awọn iyipada ti mo nṣe, wọn bẹrẹ sii fun mi ni iṣiri. Nisinsinyi emi jẹ iranṣẹ Ọlọrun ti a ti baptisi.”
Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni Brazil, gẹgẹ bi o ṣe ri ni gbogbo apa ibomiran lori ilẹ-aye, jafafa ninu wiwaasu “itusilẹ kan fun awọn òǹdè.” Ogunlọgọ awọn eniyan ndahunpada, ti wọn si nri itusilẹ ati ayọ tootọ ninu ṣiṣiṣẹsin Jehofa.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Itẹjade Ji! August 22, 1986 oju-iwe 12.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 30]
BRAZIL
Iye Eniyan Ilu - 150,367,800
Gongo Akede ni 1990 - 293,466
Ipin, Akede 1 si - 512
Iye Ti O Se Iribọmi ni 1990 - 27,068
Ipindọgba Awọn Akede Aṣaaju-ọna - 30,115
Iye Awọn Ijọ - 4,625
Ipindọgba Awọn Ikẹkọọ Bibeli - 341,305
Iye Awọn Ti Wọn Wá Si Iṣe-iranti - 790,926