ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 9/15 ojú ìwé 31
  • Ibeere Lati Ọwọ Awọn Onkawe

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ibeere Lati Ọwọ Awọn Onkawe
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìgbàgbọ́ Òdodo Máa Mú Kí O Ní Ayọ̀ Ayérayé
    Ìgbàgbọ́ Òdodo Ló Máa Mú Kó O Ní Ayọ̀
  • Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì Nípa Ọjọ́ Ọ̀la Wa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ìgbésí Ayé Nínú Ayé Tuntun Alálàáfíà Kan
    Ìgbésí Ayé Nínú Ayé Tuntun Alálàáfíà Kan
  • Walaaye Titilae Ninu Paradise Ori Ilẹ̀-ayé Kan
    Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 9/15 ojú ìwé 31

Ibeere Lati Ọwọ Awọn Onkawe

◼ Eeṣe ti Aisaya 11:6 ninu New World Translation of the Holy Scriptures fi wi pe: “Ikooko yoo gbé pọ fun igba diẹ pẹlu akọ ọdọ agutan”? Iru alaafia bẹẹ ko ha ni wà pẹtiti bi?

Alaafia atunilara ninu iṣẹda ẹranko ti a sọtẹlẹ ni Aisaya 11:6-9 (NW) yoo wà titilọ. Ṣugbọn itumọ oniṣọọra ti Aisaya 11:6 (NW) mu un ṣe kedere pe iru awọn ẹranko bẹẹ ki yoo maa wa papọ nigba gbogbo.

Ninu New World Translation of the Holy Scriptures, Aisaya 11:6 ka pe: “Nitootọ ni ikooko yoo gbé pọ̀ fun igba diẹ pẹlu akọ ọdọ agutan, ati pẹlu ọmọ ewurẹ ni ẹkùn funraarẹ yoo dubulẹ, ati ọmọ maluu ati ẹgbọrọ kinniun onígọ̀gọ̀ ati ẹran abọpa gbogbo wọn lapapọ; ọmọkunrin kekere kan lasan yoo si jẹ oludari wọn.”

Kika rẹ̀ ninu ọpọlọpọ Bibeli farapẹ́ ẹ: “Ikooko yoo tun gbé pẹlu ọdọ agutan.” Iru awọn itumọ bẹẹ le gbe aworan kan yọ ti o jẹ ti ikooko ati ọdọ agutan ti wọn jẹ alabaakẹgbẹ titilọ, bi ẹnipe wọn wa ninu idile tabi iṣeto gbigbepọ titun.

Bi o ti wu ki o ri, ọrọ Heberu ti a tumọ si “gbé” ni gur. Gẹgẹ bi olutumọ ede William Gesenius ti wi, o tumọsi “lati ṣe atipo, lati gbe fun akoko kan, lati gbe gẹgẹ bii ko si nile, iyẹn ni pe gẹgẹ bi ajeji kan, ara ita, alejo.” (A Hebrew and English Lexicon of the Old Testament, ti a tumọ lati ọwọ Edward Robinson) Itolẹsẹẹsẹ awọn itumọ ọrọ lati ọwọ F. Brown, S. Driver, ati C. Briggs funni ni itumọ naa “ṣe atipo, gbe fun igba (pàtó tabi alaiṣe[pàtó]) kan, gbe gẹgẹ bi ṣẹ̀ṣẹ̀dé kan . . . laisi awọn ẹtọ ipilẹṣẹ.”

Ọlọrun lo gur ni sisọ fun Aburahamu lati “gbe gẹgẹ bi alejo” ni Kenani. Babanla naa ki yoo ni ilẹ naa, ṣugbọn oun le jẹ olugbe ti a daabobo nibẹ. (Jẹnẹsisi 26:3, NW; Ẹkisodu 6:2-4; Heberu 11:9, 13) Bakan naa, Jakọbu sọ pe oun ‘ngbe gẹgẹ bi alejo’ ni agbegbe Harani, nitori oun yoo pada si Kenani.—Jẹnẹsisi 29:4; 32:4.

Ninu Paradise ti Ọlọrun yoo fidii rẹ̀ mulẹ laipẹ, awọn ẹranko ati eniyan yoo wa ni alaafia. Ọdọ agutan ki yoo wa ninu ewu lati wà pẹlu ikooko tabi ọmọ maluu pẹlu ẹkun kan. Gẹgẹ bi ẹni pe o fi iyatọ han pẹlu isinsinyi, ede naa tilẹ yọnda fun ero pe ikooko yoo jẹ olugbe kan ti ọdọ agutan daabobo.—Aisaya 35:9; 65:25.a

Sibẹ, iru awọn ẹranko bẹẹ ṣì le ni ibugbe yiyatọ. Awọn ẹranko kan dara fun igbo ẹgan, awọn miiran fun pẹtẹlẹ, sibẹ awọn miiran fun agbegbe etikun tabi ori oke. Ani ni akoko Paradise ipilẹsẹ paapaa, Ọlọrun sọrọ nipa “ẹran ọsin ati ẹranko ẹhanna.” (Jẹnẹsisi 1:24) Awọn ẹran ọsin ni kedere jẹ awọn wọnni ti o wọpọ pe wọ́n wa nitosi eniyan ati ibugbe wọn. Ẹranko ẹhanna, bi o tilẹ jẹ pe wọn ko roro, o han gbangba pe wọn yan lati gbe jinna si araye. Nitori naa, gẹgẹ bi asọtẹlẹ Aisaya ti sọ ṣaaju, ikooko yoo “gbe fun igba diẹ pẹlu akọ ọdọ agutan,” ṣugbọn ki yoo maa figba gbogbo wa layiika iru awọn ẹran ọsin bẹẹ.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a The Bible in Living English sọ awọn ọrọ Aisaya 11:6 lọna yii: “Ikooko yoo si jẹ ayalegbe ọdọ agutan.”

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 31]

Zoological Research Center, Tel-Aviv Hebrew University

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́