Imọ Ijinlẹ Ha Le Fihan Pe Irọ́ Ni Iṣẹ-iyanu Jẹ́ bí?
Njẹ awọn iṣẹ-iyanu ninu Bibeli ha ṣẹlẹ niti gidi bi? Ọpọlọpọ eniyan, papọ pẹlu awọn onimọ ijinlẹ ati awọn aṣaaju isin ni wọn wa, ti wọn dahun pe bẹẹkọ. Wọn nimọlara pe igbagbọ ninu iṣẹ iyanu jẹ ti sanmani ti o tubọ jẹ ti onigbagbọ ninu ohun asan ati pe imọ ijinlẹ ode oni ti fi ṣiṣeeṣe naa pe kí wọn ṣẹlẹ han bi irọ́. Fun idi yii, lẹta ti o tẹle e yii ti a tẹ jade ninu The Times ti London tí awọn onimọ ijinlẹ melookan sì fọwọsi yẹ fun afiyesi:
“Ko lẹsẹ nilẹ lọna ti o ba ọgbọn mu lati lo imọ ijinlẹ gẹgẹ bi koko ìjiyàn lodisi iṣẹ-iyanu. Lati gbagbọ pe awọn iṣẹ-iyanu ko le ṣẹlẹ jẹ iṣẹ igbagbọ gẹgẹ bi gbigbagbọ pe wọn le ṣẹlẹ. . . . Awọn iṣẹ iyanu jẹ iṣẹlẹ ti ko ṣẹlẹ rí. Ohun yoowu ki awọn ọna ironu ti lọwọlọwọ ninu ọgbọn imọ ọran jẹ tabi ohun yoowu ki iṣipaya iwadii ero awọn eniyan le damọran, o ṣe pataki lati tẹnumọ pe imọ ijinlẹ (bi a ti gbekari akiyesi awọn iṣẹlẹ ti o ti ṣẹlẹ ṣaaju) ko le ni ohunkohun sọ lori ọran naa. ‘Ofin’ rẹ̀ jẹ kiki akopọ awọn iriri wa ni. Igbagbọ sinmi lori awọn ipilẹ miiran.” (Ikọwe wínníwínní jẹ tiwa.) Nitootọ, ko si ọna kankan ti imọ ijinlẹ ode oni le gba fi awọn irohin iṣẹ-iyanu ti a ṣakọsilẹ sinu Bibeli ha bi irọ́.