ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 12/1 ojú ìwé 32
  • ‘Wọn Saba Maa Nrẹrin-in’

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • ‘Wọn Saba Maa Nrẹrin-in’
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 12/1 ojú ìwé 32

‘Wọn Saba Maa Nrẹrin-in’

Ọkunrin kan ti ó nṣiṣẹsin gẹgẹ bi ologun ni Hungary sọ pe ni eyi ti ko pẹ́ pupọ sẹhin awọn eniyan ti maa nfi awọn wọnni ti nsọrọ nipa Bibeli rẹrin-in. Ṣugbọn akoko ti yipada. Ṣọja naa kọwe si ọfiisi ẹka ile-iṣẹ Society ni Budapest laipẹ yii, ni sisọ pe:

“Ọjọ melookan sẹhin, mo ka itẹjade yin naa Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. Ẹnikan ti fi yá mi titi di igba ti emi yoo fi kà á tan. Ohun ti a kọ sinu iwe naa fami lọkan mọra lọna jijinlẹ ti o si ti mu mi ronu.” Ṣọja naa nfẹ Bibeli kan ati isọfunni siwaju sii. Iru idahunpada bẹẹ kii ṣe ohun àrà mọ́ ni Eastern Europe.

Lẹta miiran ti a gba ni ọfiisi ni Budapest sọ pe: “Emi ti ka iwe naa Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. Iwe naa ti ni ipa lori mi lọna jijinlẹ gidi gan-an, emi sì nkọwe si yin lati beere fun Ẹlẹ́rìí kan lati ṣebẹwo si ile mi ki emi baa lè ni ikẹkọọ Bibeli kan deedee.”

Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye jẹ́ iwe kan ti ó nfi ireti funni nipa titọka si awọn idahun inu Bibeli fun ọ. O ti jẹ ohun eelo ninu yiyi igbesi-aye ọpọlọpọ pada. Bi iwọ yoo ba fẹ lati gba ẹ̀dà kan, jọwọ kọ ọrọ kún alafo ti ó wa ni isalẹ yii fun isọfunni ki o si fi ranṣẹ.

Emi yoo fẹ ki ẹ fi isọfunni ti bi mo ṣe lè ri iwe ẹlẹhin lile oloju-ewe 256 naa Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye gbà ranṣẹ si mi.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]

Pẹlu idi rere, obi yoo yọọda ki a ṣe iṣẹ-abẹ ti o ni irora fun ọmọ rẹ̀ olufẹ. Ọlọrun pẹlu ni awọn idi rere lati yọọda ki iran eniyan jiya fun igba diẹ.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́