ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 3/1 ojú ìwé 32
  • “Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa Ha Ni Bi?”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa Ha Ni Bi?”
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 3/1 ojú ìwé 32

“Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa Ha Ni Bi?”

IBEERE ti o wà loke yii farahan gẹgẹ bi àkọlé ninu iwe irohin Bulletin of the University of Helsinki ni ede Finnish. Labẹ àkọlé naa ni lẹta ti Ọjọgbọn Jorma Palo kọ wà, ó sì sọ ni apakan bayii pe: “Mo tun èdídí yunifasiti wa ti a tẹ̀ sara ẹhin iwe irohin Bulletin naa wà daradara. Ni agbedemeji ilaji apa oke, mo ri ọrọ ẹsẹ iwe lede Heberu itumọ eyi ti mo wadii wo lọwọ alejo mi kan ti o jẹ́ Juu. Gẹgẹ bi ọmọwe yii, ẹni ti o mọ ede Heberu ti sọ, ọrọ yii ni ‘Jehofa’ ni ede Finnish.”

Wiwa nibẹ orukọ ara-ẹni ti Ọlọrun lori èdídí yunifasiti Finnish yii ya awọn kan lẹnu. Bi o tilẹ jẹ pe, nitootọ yunifasiti naa jẹ 350 ọdun ni pipẹ, nigba ti a sì dá a silẹ, orukọ naa Jehofa ni a mọ̀ lọna gbigbooro ti a sì lò jakejado Europe. Orukọ naa farahan lara awọn ailonka ile, owo ẹyọ, ati awọn èdídí ti ọjọ rẹ̀ pẹ́ sẹhin si saa akoko yẹn.—Wo iwe pẹlẹbẹ naa Orukọ Atọrunwa naa Ti Yoo Wà Titilae.

Ni ọrundun wa, Kristẹndọmu kò lo orukọ Ọlọrun mọ́, ati pe ifẹ akọkọ ti o ni ninu rẹ̀ ni ó ti gbagbe lọna ti o pọ julọ. Kiki awujọ kan ni o ń lo orukọ atọrunwa naa ninu ijọsin ti wọn sì ń kede rẹ̀ kaakiri, ni ibamu pẹlu ẹbẹ akọkọ ninu Adura Oluwa: “Baba wa ti ń bẹ ni ọrun, ki a bọwọ fun orukọ rẹ.” (Matiu 6:9) Idi niyẹn, ti o fi jẹ pe nigba ti a fi orukọ naa han lara èdídí yunifasiti, awọn eniyan yara ronu nipa Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]

Yliopisto

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́