Iṣẹ Iranlọwọ Itura Si Ukraine
LẸẸKAN sii awọn irohin aláìmúni lori yá gágá kún inu orisun eto irohin. Rúdurùdu ti ọrọ ajé, àìtó ounjẹ, ati ebi ń yọ́kẹ́lẹ́ dọdẹ ilẹ-aye—ni akoko yii ni awọn apa Soviet Union tẹlẹri. Ẹgbẹ Oluṣakoso ti Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lẹnu aipẹ yii sọ fun ẹka ọfiisi Watch Tower Society ni Denmark lati ṣeto fun iranlọwọ-itura fun awọn Ẹlẹ́rìí ti wọn wà ninu aini ni Ukraine. Ki ni awọn ará ni Denmark ṣe?
Wọn bẹrẹ iṣẹ lọ́gán! Kíá ni ẹ̀ka ọfiisi rán awọn ará jade lati yára wá awọn ọjà kiri fun awọn ohun jijẹ didara julọ lati rà. Ọrọ jade lọ si gbogbo ijọ awọn eniyan Jehofa ni Denmark, ni fifi aini naa tó wọn létí. Ẹka naa rohin pe: “Gbogbo ijọ ṣe ju mimuratan lati ṣe itọrẹ lọ. Nikẹhin, ó ṣeeṣe fun wa lati fi ẹ̀rí ìbánikẹ́dùn gidi ti a ní fun awọn wọnni ti ń jiya hàn.” Ọkọ ẹrù marun-un papọ pẹlu ọkọ ẹrù kekere meji ati awọn awakọ oluyọnda ara-ẹni 14, jẹ́ ìpè ni ẹka [ọfiisi] ni Denmark ni Saturday, December 7, 1991. Awọn oṣiṣẹ ẹka di awọn ẹrù ounjẹ naa ti wọn ti rà sinu awọn ọkọ ẹrù naa.
Ni ọ̀sán Monday, December 9, awujọ ọkọ arinrin-ajo naa gbéra ìrìn-àjò gígùn la Europe já lọ si Ukraine. “Ó jẹ́ ìran kan tí ó wọnilọ́kàn bí gbogbo idile Bẹtẹli ti pejọ lati juwọ́ ó-dàbọ̀-o sí wọn,” ni ẹka naa kọwe. “Ni mímọ̀ pe ọpọlọpọ iṣẹ iranlọwọ-itura ni ó ti ṣe kongẹ ìfipákọluni, a fi ọpọlọpọ adura kín awọn ará wa lẹhin ni gbogbo ọna naa.”
Ni December 18 ipo aniyan ṣiṣe naa dopin. Ẹka ti Denmark gba irohin pe awujọ ọkọ arìnrìn-àjò naa ti gúnlẹ̀ laisewu sí Lviv, Ukraine. Awọn ará ni Ukraine ti gba ohun afiṣeranwọ naa. Ara ti tù wọn tó lati já 1,100 awọn ẹrù oníwọ̀n 44 pound, ti wọn tobi gbàǹgbà—ti ọkọọkan ni ẹran, iyẹfun, irẹsi, ṣuga, ati awọn ounjẹ wíwọ́pọ̀ miiran ninu! Lapapọ, awujọ ọkọ arìnrìn-àjò naa fi awọn ipese ti ó tó iwọn tọọnu 22 jiṣẹ. Ẹka ti Denmark kọwe pe: “Ayọ wa ga, bi a ti ń dupẹ lọwọ Jehofa fun aabo rẹ̀ ati fun fifun wa ni anfaani yii lati nawọ iranlọwọ jade.”
Fifi aṣọ wíwọ̀ ranṣẹ ni a tun ti wéwèé. Ẹka naa rohin pe ni ọna yii bakan naa, “idahunpada awọn ijọ ti pọ̀ jaburata.” Niti gidi ni Jehofa ń ‘sọ awọn eniyan rẹ̀ di ọlọ́rọ̀ fun gbogbo oniruuru iwa ọ̀làwọ́.’ (2 Kọrinti 9:11) Awọn, ni ipa tiwọn, nimọlara jijinlẹ fun ayọ ti ń wá lati inu fifun awọn arakunrin ati arabinrin wọn lọfẹẹ. Ifẹ ti wọn tipa bayii fihan jẹ́ ami idanimọ awọn ọmọlẹhin Jesu. (Johanu 13:35) Iru ifẹ bẹẹ jẹ́ gbogbo ohun ti ó ṣọ̀wọ́n ninu ayé ti ó kún fun aini yii.