Isin ‘Onigbagbọ Ti Ó Ṣee Tẹ̀síhìn-ín Tẹ̀sọ́hùn-ún’
“Agbara isin Mormon lati jere ifẹsẹmulẹ ninu awọn awujọ onijọba alagbada ati onijọba bóofẹ́-bóokọ̀ jẹ́ iyanu kan.” Bẹẹ ni The Wall Street Journal sọ nigba ti ijọba Hungary fi ìdámọ̀ kikun fun Church of Jesus Christ of Latter-day Saints. Bawo ni ọwọ́ ṣọọṣi naa ṣe tẹ eyi? Gẹgẹ bi Journal naa ti wi, “kọkọrọ naa ki i wulẹ ṣe iwọn ìbímọ bíbí giga tabi ìtànkálẹ̀ oníjàgídíjàgan ti ihinrere wọn. Kaka bẹẹ, ó jẹ́ ìṣeétẹ̀síhìn-ín tẹ̀sọ́hùn-ún tí ó jẹ́ apakan igbagbọ naa.” Bawo ni o ṣe ri bẹẹ?
Ni sisọrọ nipa sáà akoko ṣaaju awọn iyipada oṣelu ẹnu aipẹ yii ni Ila-oorun Europe, Journal naa sọ pe: “Nipa lilo ohùn orin ati awọn awujọ oníjó ìbílẹ̀ lati Brigham Young University, Awọn Mormon ti dọ́gbọ́n kọja ikimọlẹ ati aisi ifọwọsowọpọ ti awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun sábà maa ń dojukọ julọ ni awọn orilẹ-ede Kọmunisti,” ni Journal naa sọ. Awujọ akọrin wọn ti rọ́ wọnu Romania, Czechoslovakia, Hungary, Poland, Russia, ati China, ati bakan naa si Saudi Arabia, Libya, Egypt, Jordan, Somalia, ati Israel. Siwaju sii, “ọrọ̀ Ṣọọṣi Mormon ni a ti lò gẹgẹ bii ọ̀nà lati lo agbara idari lori iwarere lati rí àyè wọle sinu awọn orilẹ-ede Atẹ̀lé Ilana Marx ati Ayé Kẹta.” Kíkọ́ adágún-odò ati gbígbẹ́ kànga wà lara awọn idawọle ti ìdáwó awọn Mormon ṣetilẹhin fún.
Ninu ayé onifẹẹ faaji tí ebi owo ń pa lonii, kò yanilẹnu pe iru orin ati ijó bẹẹ ati awọn ọgbọn ẹ̀wẹ́ ti nínáwó bi ẹlẹ́dà ni ifanilọkan mọra ti ó lagbara. (2 Timoti 3:2, 4) Ṣugbọn awọn ẹni bi agutan nitootọ ni ohùn Oluṣọ-Agutan Rere naa, Jesu Kristi famọra. (Johanu 10:27) Idi niyẹn, nigba ti ó fi paṣẹ fun awọn ọmọlẹhin rẹ̀ lati “sọ awọn eniyan orilẹ-ede gbogbo di ọmọ-ẹhin,” kò sọ pe kí wọn ṣe bẹẹ ni ọ̀nà eyikeyii tabi ni iye kíye ti yoo náni ṣugbọn nipasẹ ‘kíkọ́ wọn lati kiyesi gbogbo awọn ohun ti ó ti palaṣẹ.’ (Matiu 28:19, 20, NW) Ni ṣiṣe iṣẹ-aṣẹ yii, kò sí àyè fun fifi awọn ọ̀pá idiwọn Bibeli bánidọ́rẹ̀ẹ́.