Ọjọ Kan Lati Ranti
Alẹ́ ṣaaju kí ó tó kú, Jesu ṣajọpin ìṣù àkàrà aláìwú kan ati ago waini kan pẹlu awọn apọsiteli rẹ̀ ó si wi pe: “Ẹ maa ṣe eyi ni iranti mi.”—Luuku 22:19.
Ní ọdun yii àyájọ́ ohun ti o beere fun yii bọ́ si April 17, lẹhin ti oòrùn bá wọ̀.
Gẹgẹ bi iyọrisi eyi, Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa yika ayé yoo kórajọpọ̀ ni alẹ̀ akanṣe yii lati tún Iṣe-Iranti yii ṣe ni ọ̀nà ti Jesu beere. A fi tọyayatọyaya julọ ké sí ọ lati pade pẹlu wa. Jọwọ wadii lọdọ Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nibi ti o ń gbé fun akoko ati ọgangan ibi pàtó fun ipade naa.