A Nilo Ẹnikan Lati Fetisilẹ
GẸGẸ BI ẹ̀dá eniyan, a ń gbiyanju lati ri ayọ ati itẹlọrun ninu igbesi-aye. Ṣugbọn nigba ti awọn iṣoro ara-ẹni bá dide, ó ti ṣeranwọ ó sì ti tuni ninu tó lati ní ẹnikan ti a lè bá jiroro awọn iṣoro wa!
Dokita George S. Stevenson sọ pe: “Fífi ikùn lu ikùn a maa ṣeranwọ lati mú ìgalára rẹ fúyẹ́, ó ń ràn ọ́ lọwọ lati tubọ loye idaamu rẹ̀ ni kedere, ó ń ràn ọ́ lọwọ niye ìgbà lati rí ohun ti iwọ lè ṣe nipa rẹ̀.” Dokita Rose Hilferding sọ pe: “Gbogbo wa nilati ṣajọpin awọn iṣoro wa. A nilati ṣajọpin idaamu. A nilati nimọlara pe ẹnikan wà ninu ayé ti ó muratan lati fetisilẹ tí ó sì lè loye.”
Ni tootọ, kò sí eniyan tí ó lè kájú ìwọ̀n aini yii patapata. Nitori awọn ààlà lori akoko ati awọn okunfa miiran, awọn eniyan alábàárò wa lè má sìí larọọwọto nigba ti a nilo wọn julọ, tabi a lè lọ́ tìkọ̀ lati jiroro awọn ọ̀ràn kan ani pẹlu awọn ọ̀rẹ́ wa timọtimọ julọ paapaa.
Bi o ti wu ki o ri, awọn Kristẹni tootọ ní gbogbo ọ̀nà kò ṣalaini ẹni ti ń fetisilẹ, nitori pe ọ̀nà lati gbadura wà larọọwọto nigba gbogbo. Bibeli fun wa niṣiiri leralera lati gbadura si Ọlọrun, Ẹlẹdaa wa, ẹni ti orukọ rẹ̀ ń jẹ́ Jehofa. A paṣẹ fun wa lati gbadura pẹlu otitọ-inu, ni orukọ Jesu, ati ni ibamu pẹlu ifẹ-inu Ọlọrun. Kódà awọn ọ̀ràn ara-ẹni ati ti ìkọ̀kọ̀ paapaa jẹ́ awọn koko bibojumu fun adura. “Ninu ohun gbogbo, . . . ẹ maa fi ibeere yin hàn fun Ọlọrun,” ni a sọ fun wa ni Filipi 4:6. Ẹ̀bùn ńláǹlà wo ni eyi jẹ́! Oluṣakoso Ọba-Alaṣẹ agbaye wa wà ni sẹpẹ́ ni gbogbo ìgbà lati fi idunnu dahunpada ati lati tẹwọgba adura awọn iranṣẹ rẹ̀ onirẹlẹ nigbakigba ti wọn bá fẹ́ lati wá sọdọ rẹ̀.—Saamu 83:18; Matiu 6:9-15; Johanu 14:13, 14; 1 Johanu 5:14.
Sibẹ, Ọlọrun ha ń fetisilẹ nitootọ bi? Awọn kan lè ṣe kayefi bi a bá fi ìgbéṣẹ́ adura mọ si agbara òye eniyan: Ẹnikan ń gbadura, ó ń ṣeto awọn èrò rẹ̀ ó sì ń sọ wọn jade ni ọrọ. Lẹhin ti o ti ṣapejuwe iṣoro rẹ̀ ni pàtó tan, ó lepa ojútùú ti ó bá a mu ó sì wà lojufo si ohun gbogbo ti ó lè ṣeranlọwọ siha wíwá a kàn. Nigba ti iṣoro rẹ̀ bá ti yanju tan, ó lè fi ìyìn fun Ọlọrun, ṣugbọn èrò ati isapa tirẹ̀ fúnraarẹ̀ ni ó mú abajade ti a fẹ́ naa jade niti gidi.
Ọpọlọpọ lonii rò pe gbogbo ohun ti ó wà niti gidi si adura niyẹn. Iwọ ha rò bẹẹ bi? Ṣe ibi ti agbara adura mọ sí niyẹn? A gbà pe, awọn isapa ẹnikan niti ara ìyára ati ero-ori ní ibamu pẹlu awọn adura rẹ̀ kó ipa pataki kan ninu rírí idahun gbà. Bi o ti wu ki o ri, ki ni nipa ipa tí Ọlọrun fúnraarẹ̀ kó ninu ọ̀ràn naa? Ọlọrun ha ń fetisilẹ nigba ti iwọ bá gbadura sí i bi? Ó ha ka adura rẹ sí pataki, ni fifun awọn ọrọ inu rẹ̀ ni igbeyẹwo ati didahun pada sí wọn bi?
Idahun si awọn ibeere wọnyi ṣe pataki. Bi Ọlọrun kò bá fi afiyesi sí awọn adura wa, nigba naa adura kò niyelori ju ọgbọ́n ironu lọ. Ni ọwọ keji ẹ̀wẹ̀, bi Ọlọrun bá ń gbà ti ó sì ń fetisilẹ pẹlu ifẹ-ọkan si awọn adura wa kọọkan, a ti gbọdọ kun fun imoore tó fun iru ipese bẹẹ! Ó gbọdọ sún wa lati lo ipese naa lojoojumọ.
Nigba naa, a ké sí ọ, lati maa bá kíkà lọ, niwọn bi ó ti jẹ pe a bojuto awọn ọ̀ràn wọnyi ninu ọrọ-ẹkọ ti o tẹle e.