Ayọ Ńláǹlà ni Soviet Union
ỌMỌDEBINRIN kekere yii ni Lvov ni idi lati yọ̀. Ó jẹ́ ọ̀kan lara awọn 74,252 eniyan ti wọn pade fàlàlà ni Soviet Union lati gbadun apejọpọ Kristẹni ti wọn sì gba ẹ̀dà itẹjade titun meremere yii Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí ni èdè Russia. Bi o tilẹ jẹ pe Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni a kò tíì yọnda fun nigba kan rí lati ṣe awọn apejọpọ ni Soviet Union, ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ti ó kọja wọn ṣe meje.
Ọ̀kan lara awọn ìlú-ńlá apejọpọ naa ni Alma-Ata, Kazakhstan, nibi ti awọn olùpéjọpọ̀ lati Soviet republics of Russia, Uzbekistan, Kirghizia, Tadzhikistan, ati Turkmenistan pẹlu ti wá. Ni Alma-Ata iye ti ó ju 6,000 lọ layọ lati gba iwe titun naa. Nigba ti ọkọọkan iye ti ó ju 4,000 awọn eniyan ti wọn pésẹ̀ ni Usolye-Sibirskoye, Siberia, gba ẹ̀dà ọ̀fẹ́ tiwọn, olùṣekòkáárí pápá iṣere naa kigbe jade pe: “Iyanu ni eyi!”
Ni Kiev, nigba ti ọpọ iye awọn ọlọpaa ati panapana ri iwe naa, wọn bẹ̀bẹ̀ fun ẹ̀dà kan, ni wiwi pe: “Ó ṣetán, a ṣáà daabobo yin; a wà pẹlu yin ni apejọpọ naa.” Aṣaaju ọlọpaa kan fẹ́ lati mọ, “Ibo ni a ti tẹ̀ ẹ́? Ẹ̀dà meloo ni a ti tẹjade?”
Titi di bayii, iye ti ó ju ẹ̀dà 12 million lọ ni a ti tẹjade ni 60 èdè, tí ó ni ninu awọn wọnni ti a kò ṣe bẹẹ mọ iru bii Bislama, Efịk, Ewe, Ga, Igbo, Rarotongan, Sepedi, Shona, Tsonga, Tswana, Twi, ati Venda.
Araadọta-ọkẹ jakejado ayé ń rí idunnu ninu kíka itẹjade meremere titun oloju-ewe 448 yii lori ìtàn igbesi-aye ati iṣẹ-ojiṣẹ Jesu Kristi. Bi iwọ yoo bá tẹwọgba isọfunni siwaju sii nipa Jesu ati ipa tí ó kó ninu mimu ète Ọlọrun ṣe siha ilẹ̀-ayé, jọwọ kọwe si Watch Tower, P.M.B. 1090, Benin City, Edo State, tabi si adirẹsi ti a tò lẹsẹẹsẹ ni oju-ewe 2.