ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 7/1 ojú ìwé 32
  • Akoko naa Lati Wá Ọlọrun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Akoko naa Lati Wá Ọlọrun
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 7/1 ojú ìwé 32

Akoko naa Lati Wá Ọlọrun

AWORAN oju-iwe yii jẹ ti Acropolis ni Ateni, ti o jẹ́ ọgangan idari ijọsin ọpọlọpọ awọn ọlọrun ati abo-ọlọrun nigbakanri. Nisalẹ Acropolis ni Areopagu, ti a sọ pe o jẹ ọgangan kóòtù idajọ ni akoko igbaani. Lori ibi yii gan-an, ni nǹkan bii 2,000 ọdun sẹhin, ni aposteli Paulu ti duro ti ó sì sọ ọrọ awiye ti o pẹtẹri kan nitootọ. Eyi ti o tẹle e yii ni diẹ lara ohun ti o sọ:

“[Ọlọrun] sì ti fi ẹ̀jẹ̀ kan-naa dá gbogbo orilẹ-ede, lati tẹ̀dó si oju agbaye, o sì ti pinnu akoko ti a yàn tẹlẹ, ati ààlà ibugbe wọn; ki wọn ki o lè maa wá Oluwa, boya bi ọkàn wọn bá lè fà sí i, ti wọn sì rí i, bi o tilẹ ṣe pe kò jinna si olukuluku wa: nitori ninu rẹ̀ ni awa gbé wà ni ààyè, ti awa ń rìn kiri, ti a sì ni ẹmi wa.”—Iṣe 17:26-28.

Ìtàn yoo ti yatọ tó bi araye ni gbogbogboo bá ti ṣakiyesi awọn ọ̀rọ̀ Paulu! Ọpọ ogun meloo, ọpọ ijiya meloo, ni a bá ti ṣèdíwọ́ fun bi awọn eniyan bá ti mọ ohun wiwọpọ julọ ti wọn nifẹẹ si gẹgẹ bi ọmọ fun ọkunrin kan tí Oluwa Ọba-alaṣẹ dá.

Lonii, araye ni ẹmi ifẹ orilẹ-ede ẹni, iyasọtọọtọ kẹlẹgbẹmẹgbẹ, ikoriira ẹ̀yà iran, ati aidọgba ẹgbẹ-oun-ọgba ti pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ. Sibẹ, awọn ọrọ Paulu ṣì ṣee fisilo. Gbogbo wa ni atọmọdọmọ ọkunrin kan ti Ọlọrun dá yẹn. Ni èrò itumọ yẹn, gbogbo wa jẹ́ arakunrin ati arabinrin. Kò sì tíì pẹ́ ju lati wá Ọlọrun nigba ti a lè rí i.

Awọn ọ̀rọ̀ Paulu tubọ gba ironujinlẹ sii nigba ti a bá gbé awọn ọ̀rọ̀ ikẹhin Paulu ninu awiye rẹ̀ yẹwo. Ó sọ pe: “[Ọlọrun] ti dá ọjọ kan, ninu eyi ti yoo ṣe idajọ ayé ni ododo, nipasẹ ọkunrin naa ti o ti yàn, nigba ti o ti fi ohun idaniloju fun gbogbo eniyan, niti o jí i dide kuro ninu òkú.”

Ajinde Jesu jẹ́ otitọ ìtàn kan, gẹgẹ bi Paulu sì ti fihan, ó jẹ́ ẹ̀rí idaniloju pe ọjọ idajọ kan yoo wà fun araye. Nigba wo? Ó dara, a mọ pe o ti fẹrẹẹ fi 2,000 ọdun sunmọ wa sii ju ìgbà ti Paulu duro lori Areopagu ti o sì sọ awọn ọrọ wọnyi. Nitootọ, imuṣẹ asọtẹlẹ Bibeli fihan pe o ti sunmọ gan-an. Èrò amúnigbéjẹ́ẹ́-ṣe-wọ̀ọ̀ wo ni eyi jẹ́! Ó ti ṣe kanjukanju tó pe ki a wá Ọlọrun pẹlu gbogbo ọkàn rere, niwọn bi, gẹgẹ bi Paulu ti sọ fun awọn ará Ateni, “nisinsinyi ó paṣẹ fun gbogbo eniyan nibi gbogbo lati ronupiwada”!—Iṣe 17:30, 31.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́