Lati Ile-Iwosan Àfipìtàn Si Gbọngan Ijọba Alailẹgbẹ
NI 1770 gbajumọ oluṣewadii ara Gẹẹsi naa Lieutenant [oyè Badà] James Cook ń wa ọkọ̀ oju-omi Endeavour oníwọ̀n 369 tọọnu lọ ni eti bèbè Australia ti a kò ti rinrin-ajo iwadii lori rẹ̀ rí. Ni alẹ́ June 11, ọkọ̀ oju-omi naa forisọ apata kan ni ibi jijinna siha ariwa àgbáálá-ilẹ̀ naa. Ara ọkọ̀ naa ti a fi pátákó igi oak ṣe bajẹ lọna ti o buru gan-an. Atunṣe ni a nilo ni kiakia bi awọn ero ọkọ̀ naa yoo bá nilati laaja. Ibi itòsí kan tí odò ti ń ṣàn wọnu òkun ni o jásí ibi didara kan fun atunṣe naa, eyi ti o gba ọsẹ mẹfa. Ọgọrun-un ọdun ó lé mẹta lẹhin naa, wura ni a ṣawari rẹ̀ ni agbegbe yii. Ìjàgùdù fun ọrọ̀ wura naa bẹrẹ! Ẹgbẹẹgbẹrun mẹwaa-mẹwaa wá lati wá ọrọ̀. Cooktown ni a ṣe bayii dasilẹ.
Ni 1879 iyọnda ijọba lati kọ́ ile-iwosan wíwà titilọ kan lati bojuto awọn alaisan ati awọn ti wọn bá farapa nibi jamba iwakusa ni a tẹwọgba. Ni ọdun yẹn kan-naa, ni ibomiran ninu ayé, July 1 rí ibẹrẹ itẹjade Zion’s Watch Tower. Lati ìgbà yẹn, iwe-irohin yii ti pese itolẹsẹẹsẹ fun ilera tẹmi ọpọ million awọn eniyan olubẹru Ọlọrun. A kò mọ nigba yẹn pe ni ọjọ kan ile-iwosan Cooktown yoo ni isopọ timọtimọ kan pẹlu iwe-irohin yii.
Lẹhin ohun ti o ju ọrundun kan lọ, Ile-iwosan Cooktown nilo afidipo. Owó àkànlò ijọba wà larọọwọto fun kikọ ile lílò titun miiran, nitori naa awọn wọnni ti ó bá wù lati bojuto ìkókúrò ile iwosan atijọ naa ni a késí. The National Trust of Queensland [Ajọ tí ń bojuto iṣura aworan ile àfipìtàn ni Queensland], Australia fi ọkàn-ìfẹ́ hàn ninu ile atijọ yii. Bi o ti wu ki o ri, iye owó tí wiwa ààyè titun fun ile naa ati titun un kọ́ ní ninu jẹ́ eyi ti o ga jù. Adehun owó sísan kankan kò sí.
Ni nǹkan bi akoko kan-naa, ijọ kekere ti Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni Cooktown ń wá ibi ti o wà pẹtiti kan lati maa ṣe awọn ipade Kristian. Wọn kò ní ilẹ kankan ti ó jẹ́ tiwọn wọn sì ní kìkì $A800. Bawo ni wọn ṣe lè kọ́ Gbọngan Ijọba kan? Awọn aṣoju ijọ adugbo yọnda araawọn lati wá ibomiran fun ile iwosan naa laigba kọ́bọ̀. Bawo ni Jehofa yoo ṣe dari awọn nǹkan? Pabambarì! Àbá wọn ni a tẹwọgba!
Kókó miiran ti ó kàn ni—ilẹ fun ile naa. Bẹẹni, a sọ fun wọn pe, ó dabi ẹni pe ilẹ ijọba ni a lè mú wà larọọwọto lọfẹẹ, bi wọn bá ti lè pa ile naa mọ́ ki wọn sì tun-un kọ́. Bi o ti wu ki o ri, nigba ti o fi maa di akoko yii atako fun ìwéwèé-dáwọ́lé naa ń ga sii ni apá ibikan ti awọn aláìníwà-bí-ọ̀rẹ́ ninu awujọ naa. Iwe ẹ̀bẹ̀ kan ni wọn ṣeto lati mú idaduro deba ìwéwèé Awọn Ẹlẹ́rìí naa. Ọ̀rọ̀ àgbọ́sọ kan ni a gbé yika pe Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa yoo gba Cooktown, ti wọn yoo sì ti gbogbo awọn hotẹẹli ati ọgbà ile tẹ́tẹ́ pa, ti wọn yoo sì ka títa siga leewọ. Nitootọ, eyi kò ṣẹlẹ rara, ṣugbọn títún ayika ilẹ naa pín sí ìsọ̀rí ti ó yẹ fun ète naa ati rírí awọn ifọwọsi ti o pọndandan fun ile kíkọ́ naa gbà di eyi ti o tubọ ń ṣoro siwaju ati siwaju sii. Ọjọ ti a dá fun kíkó ilé naa kuro ń yára sunmọ. Ìdásí ọ̀ràn lati ọdọ Ijọba Ipinlẹ Queensland ni a wá. (Fiwe Romu 13:2.) Iyọnda fun lilo ilẹ ijọba ni a tètè fọwọsi, aṣẹ ile kíkọ́ kan ni a sì tẹjade. Pẹlu ilẹ ati ilé naa ni ìkáwọ́, ki ni ó kàn?
Òtú ọgọrọọrun Awọn Ẹlẹ́rìí, oniṣẹ-ọwọ ti wọn niriiri ati awọn oluranlọwọ lati apá oniruuru ni Ipinlẹ Queensland, ti wọn fi tinutinu yọnda akoko wọn ti wọn sì ti mú ìdáńgájíá dagba lati kọ́ Gbọngan Ijọba naa ni kiakia dé. Iwéwèé-dáwọ́lé yii gbe ipenija akanṣe kalẹ: ṣíṣí awọn abala ile-iwosan alájà meji naa lọ si ọgangan ààyè titun ati títún ilé naa tò. Ìgbà òjò alátẹ́gùn ti ń halẹ òjò alágbàrá mọ́ni, ń yára sunmọle. Iṣẹ naa ni a ó hà pari lakooko bi? Diẹ lara awọn eniyan ilu naa ń ṣiyemeji. Bi o ti wu ki o ri, ohun ti o farajọ ohun kan ti kò ṣeeṣe fun awọn kan ni a ṣaṣepari rẹ̀ laipẹ. Ni April 1986 ile naa ni a kó lọ sibomiran ti a sì mú un padabọ si ipo ẹlẹ́wà rẹ̀ ti akọkọ.
Gbogbo igbokegbodo yii ni a kò ṣaikiyesi, gẹgẹ bi o ti ṣe kedere nipasẹ awọn ọ̀rọ̀ ninu iwe irohin Anglican Newsletter ni Cooktown. Ni apakan ó sọ pe: “Kò sí iyemeji pe a o ṣe ariwisi si mi, ṣugbọn . . . ẹ wo yika inu Ṣọọṣi ki ẹ sì rí i bi ó ṣe joro tó ki ẹ sì gbojuwo awujọ awọn eniyan keji [Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa] ki ẹ sì rí i bi o ti ń kún tó . . . , ti o ń kún fun awọn onisin Anglican ati Roman Katoliki. . . . Njẹ iwọ mọ pe eto-ajọ kan bayii . . . [ti] ra Ile-iwosan atijọ kan lati tún un kọ́ si ohun ti wọn lè pè ni ile ṣọọṣi kan nitori pe Ile-ẹ̀kọ́ ti kere ju fun gbogbo wọn? . . . A ti jẹ́ aláìkáràmáásìkí tó, lati yọnda eyi lati ṣẹlẹ.”
Ẹgbẹẹgbẹrun awọn arinrin-ajo ibẹwo ń ṣebẹwo si Cooktown lọdọọdun. Wọn wá gbadun igbekalẹ igbó-olójò meremere ati Great Barrier Reef ati lati mọ̀ nipa ìtàn agbegbe naa. Ile Àkójọ Ohun Ìṣẹ̀m̀báyé Ọgágun Cook jẹ́ ibi fifanimọra ti o lokiki fun ọpọ julọ awọn olubẹwo. Lati 1989 Ile-iwosan atijọ ti Cooktown ninu ìlà iṣẹ rẹ̀ titun gẹgẹ bii Gbọngan Ijọba ti Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tún ti jẹ́ ibi fifanimọra pataki fun awọn arinrin-ajo ibẹwo. Awọn ile itaja ohun iranti ń ta awọn aṣọ ti a fi ń nu abọ́ ati ṣẹ́ẹ́tì alápá kukuru ti o ni aworan ti a ya Gbọngan Ijọba-Ile-iwosan Cooktown sí lara. Ni akoko irinrin-ajo ibẹwo naa, laaarin ẹgbẹta si ẹgbẹrun kan eniyan ni wọn ń bẹ ile naa wò lọsọọsẹ lati ri aworan ile yíyà alailẹgbẹ rẹ̀ ti 1879 funraawọn.
Iwe-irohin ti a mọ si Ilé-Ìṣọ́nà nisinsinyi ni o wà larọọwọto fàlàlà fun awọn olubẹwo. Lati 1879 iwe-irohin yii ti ga sii ni ipinkiri dé iye ti o ju 15 million ẹ̀dà itẹjade ẹlẹẹmeji loṣu ni 111 ede. Ó ń dari awọn eniyan si ileri Bibeli pe diẹ lara ìran 1914 yoo wà laaye lati ri imupadabọsipo ilera ara ati tẹmi fun araye. (Isaiah 33:24) Gbogbo ilẹ̀-ayé ni a o yipada si paradise kan nipasẹ awọn oluyọnda ara-ẹni ti wọn muratan. (Orin Dafidi 37:29) Eeṣe ti iwọ kò ṣebẹwo si Gbọngan Ijọba kan ni sàkáání rẹ? Iwọ yoo rí ohun kan ti o niyelori ju gbogbo wura ti a tíì wà jade ni ẹkùn Cooktown lọ.—Owe 16:16.