ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 10/15 ojú ìwé 3
  • Awọn Idile Ń fojúwiná Ìfipákọluni!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Awọn Idile Ń fojúwiná Ìfipákọluni!
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àṣírí Kan Ha Wà fún Ayọ̀ Ìdílé Bí?
    Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
  • Ìdílé—Ohun Kòṣeémánìí fún Ẹ̀dá Ènìyàn!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Idaamu Idile Àmì Awọn Akoko
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Máa Lépa Àlàáfíà Ọlọ́run Nínú Ìgbésí Ayé Ìdílé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 10/15 ojú ìwé 3

Awọn Idile Ń fojúwiná Ìfipákọluni!

“IDILE ni eto ti ọjọ rẹ̀ pẹ́ julọ ti a dasilẹ laaarin eniyan. Ni ọ̀nà pupọ, oun ni o ṣe pataki julọ. Oun gan-an ni ipilẹ, ní ori rẹ̀ ni gbogbo ìlú duro lé. Odidi ilẹ̀ ọ̀làjú ti yèbọ́ nitori tí igbesi-aye idile lagbara laaarin wọn, odidi ọ̀làjú sì ti parẹ́ nigba ti igbesi-aye idile laaarin wọn di alailagbara.”

Bi iwe gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia ṣe sọ nigba naa lọhun-un ni 1973 niyẹn. Bi o ti wu ki o ri, bi a bá fi oju ode-iwoyi wò ó, awọn ọ̀rọ̀ wọnni ti ní itumọ bibanilẹru, ti o fẹrẹẹ jẹ́ ọ̀kan tí ń kininílọ̀ nipa wahala ti ń bọ̀wá. Ẹnu iwọnba ọdun diẹ ti o kọja ti ṣe ẹlẹ́rìí ohun ti ó parapọ jẹ́ ìfipákọlù taarata si igbesi-aye idile. John Bradshaw olugbaninimọran gbigbajumọ kan kọwe pe: “Yánpọnyánrin wà ninu idile lonii. . . . Ìwọ̀n ikọsilẹ giga, rudurudu awọn ọ̀dọ́ aláìtọ́mọ-ogún-ọdún, ilokulo oogun lọpọ rẹpẹtẹ, ajakalẹ ibalopọ laaarin ibatan ti ó sunmọra, àṣà jíjẹun lọna òdì ati ìlùni bátabàta jẹ́ ẹ̀rí pe ohun kan ṣaitọ patapata gbáà.”

Nitootọ, “ẹ̀rí pe ohun kan ṣaitọ patapata gbáà” pẹlu idile ni a lè rí jakejado ayé. The Unesco Courier sọ nipa ipo ọ̀ràn ni Europe pe: “Lati 1965, ibisi titobi ńlá ti wà ninu iye ikọsilẹ jakejado agbaala-ilẹ yẹn. . . . Ibisi ti [wà] ninu iye awọn idile anìkàntọ́mọ.” Awọn ilẹ ti wọn ṣẹṣẹ ń goke àgbà bakan naa ń rí ibisi ninu idaamu idile. Onkọwe Hélène Tremblay ṣakiyesi pe: “Fun araadọta-ọkẹ awọn eniyan ti wọn ń gbé ninu ẹgbẹ́ awujọ ti o ti mọ ọ̀nà igbesi-aye ti kìí yipada, ti a lè sọ bi yoo ti rí, ti ń rí bakan naa nigba gbogbo ṣáá fun ọpọ ọrundun, akoko ode-oni jẹ́ ti ìrọ́kẹ̀kẹ̀.”

Eyi ti ń janilaya ní pataki ni iru ipo igbesi-aye idile ti o lè ri ninu ọpọlọpọ ile lonii. Ni United States nikan, araadọta-ọkẹ lọna araadọta-ọkẹ awọn ọmọ ni awọn òbí onímukúmu ń tọ́ dàgbà. Ibisi ti ń danilọ́kànrú tún ti wà ninu iwa-ipa idile pẹlu. Ninu iwe wọn Intimate Violence, awọn oluwadii Richard Gelles ati Murray Straus rohin pe: “Iwọ ni ó ṣeeṣe ki a fipá kọlù, kí á nà, kí a sì pa ninu ile tirẹ funraarẹ lati ọwọ́ awọn olólùfẹ́ kan ju ki o jẹ lati ibomiran, tabi nipasẹ ẹnikẹni miiran láwùjọ wa lọ.”

Bi lilaaja ọ̀làjú bá sinmi lori okun idile nitootọ, idi wà lati bẹru fun ọjọ-ọla ọ̀làjú. Sibẹ, kadara ọ̀làjú lè jẹ́ ohun ti iwọ kò kà sí tobẹẹ ju bẹẹ lọ. Ó sì daju hán-ún-hán-ún pe àníyàn-ọkàn rẹ jẹ́ ohun ti iru wahala bẹẹ lè mú wá fun idile rẹ. Ki ni abajade naa yoo jẹ́? Idahun lati orisun kan ti ó ṣeé gbarale lè yà ọ́ lẹnu gidigidi gan-an.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́