Asọtẹlẹ ní Imuṣẹ
NIGBA ti awọn ọmọ-ẹhin Kristi Jesu beere lọwọ rẹ̀ fun àmì wíwàníhìn-ín rẹ̀ alaiṣeefojuri ninu agbara Ijọba, Jesu sọtẹlẹ pe “ẹsẹ yoo di pupọ.” (Matteu 24:3, 12) Asọtẹlẹ yii ha ti ń ni imuṣẹ ni ọjọ wa bi?
Niti gidi ó ti ń ní imuṣẹ! Iwe naa The United Nations and Crime Prevention, tí Iparapọ Awọn Orilẹ-ede tẹjade ni October 1991, sọ pe: “Iwa-ọdaran gígogò ni iṣoro ara-ọtọ fun eyi ti o pọ julọ ninu awọn orilẹ-ede ayé. Awọn iwa-ọdaran abẹ́lé ti kọja agbara ọpọ awọn orilẹ-ede kọọkan ti iwa-ọdaran laaarin awọn orilẹ-ede sì ti yára kankan ju ibi ti awujọ lagbaye dé ni lọwọlọwọ lọ. . . . Iwa-ọdaran lati ọwọ́ àjọ ẹgbẹ́ ọdaran ti gbooro de ipo amunigbọnriri, pẹlu awọn abajade lilagbara ni ero itumọ iwa-ipa ojukoju, ìdáyàjáni ati iwa-ibajẹ awọn lọ́gàálọ́gàá lawujọ. Ìkópayàbáni ti gba ẹmi ẹgbẹrun-un mẹwaa-mẹwaa awọn olufarapa alaimọwọmẹsẹ. Ṣiṣe fàyàwọ́ awọn oogun olóró aṣenileṣe ti di ọ̀ràn ibanujẹ kari-aye. Iwa-ọdaran ti pipa ayika run lọna aibikita ti ní irisi adániniji ti o sì ti pọ̀ tobẹẹ debi pe iwa-ọdaran ni a ti wá mọ̀ ọ́n si ilodisi ayé funraarẹ.”
Ìfipákọluni: Ibisi lati ori ìfipákọluni 150 ninu 100,000 eniyan ni 1970 si ohun ti ó fẹrẹẹ tó 400 ninu 100,000 ni 1990.
Olè-jíjà: Ibisi lati ohun ti o wulẹ ju 1,000 ninu 100,000 ni 1970 si 3,500 ninu 100,000 ni 1990.
Ìmọ̀ọ́mọ̀pànìyàn: Ni awọn ilẹ ti ń goke àgbà, ibisi lati 1 si 2.5 ninu 100,000 laaarin 1975 ati 1985. Ni awọn ilẹ ti wọn ti goke àgbà ibisi fun akoko kan-naa jẹ́ lati ohun ti ó dín si 3 si ohun ti ó ju 3.5 lọ.
Iwa-ọdaran ti ó tanmọ́ oogun olóró: Iwe naa ṣakiyesi pe: “Òwò fàyàwọ́ kàǹkàkàǹkà lapapọ lè gbọ́n àpò Ijọba awọn orilẹ-ede kekeke gbẹ ki ó sì doju rẹ̀ bolẹ̀, ó sì ti ṣeeṣe fun wọn titi di bayii lati ṣediwọ fun ìfàṣẹkàléèwọ̀ ati isapa awọn amofin ni awọn orilẹ-ede onile-iṣẹ ńláńlá.”
Apapọ iye iwa-ọdaran: A reti pe ki o di ilọpo lati 4,000 ninu 100,000 ni 1985 si ohun ti ó sunmọ 8,000 ni ọdun 2000.
Ibisi ninu iwa-ọdaran yika ilẹ̀-ayé jẹ́ kiki apa ẹ̀ka kan lara awọn asọtẹlẹ Jesu ti ń fihàn pe a ń gbé ni “ipari opin eto-igbekalẹ awọn nǹkan.” (Matteu 24:3, NW) Jesu sọ pe: “Nigba ti ẹyin bá ri nǹkan wọnyi ti ń ṣẹ, ki ẹyin ki o mọ̀ pe, ijọba Ọlọrun kù sí dẹ̀dẹ̀.”—Luku 21:31.