Ó Gba Ẹbun Ìdíje Naa
“ỌPẸLỌPẸ yin,” ni Kiyoe, ọmọ ile-ẹkọ giga kan kọwe si ẹ̀ka ọfiisi Watch Tower Society ti ó wà ni Japan. Ki ni ohun ti oun ń dupẹ tobẹẹ fun? Kiyoe laipẹ yii gba ẹbun titayọ julọ ninu arokọ jakejado orilẹ-ede, eyi ti Japan Traffic Safety Association ṣagbatẹru rẹ̀. Ẹbun oniyebiye naa ní ninu irin-ajo lọ si Sweden.
Kiyoe kọwe lati fi imọriri rẹ̀ hàn fun ọpọlọpọ awọn itẹjade didara ti Watch Tower Bible and Tract Society ti ṣe jade, ti oun ronu pe ó ti ran oun lọwọ lati ṣaṣeyọri. Yatọ si idije yii, oun ti ṣoju fun ile-iwe rẹ̀ ninu ọpọlọpọ idije ọrọ-sisọ ati arokọ. “Ninu ọpọlọpọ awọn idije yii,” ni oun wi, “akọle kan ni a fifunni, ti awọn akẹkọọ si ṣe iwadii fun arokọ wọn ni ibi akojọ-iwe-kika. Bi o ti wu ki o ri, emi kò nilati toríbọ gbogbo wahala yẹn. Emi ń ri awọn agbayanu akojọpọ-ọrọ nibi pẹpẹ iwe ninu ile!” Ó ń baa lọ pe: “Ohunkohun ti akọle naa ìbáà jẹ́, boya iṣoro ọjọ ogbó, ayika, ibaṣepọ jakejado awọn orilẹ-ede, tabi ìmúra-ẹni sunwọn sii, ijiroro ti o jinlẹ sábà maa ń wà ninu iwe-irohin Ilé-Ìṣọ́nà tabi Ji!”
Bi o tilẹ ri bẹẹ, kìí ṣe kìkì awọn itẹjade naa ni ó ran Kiyoe lọwọ. Ó wi pe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ti oun rigba nipasẹ itolẹsẹẹsẹ ikọnilẹkọọ ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ràn oun lọwọ lati mu iwe kíkà ati iwe kíkọ rẹ̀ sunwọn sii, eyi sì mu ki ó ṣeeṣe fun un lati tayọ ninu awọn idije naa. “Nigba kan, niti gidi mo fẹ lati gba ẹkọ-iwe yunifasiti,” ni oun jẹwọ. “Ṣugbọn nibo ni emi yoo ti ri iru itọni bii eyi gba?” Nisinsinyi oun nireti lati ṣiṣẹ alakooko kikun ni ríran awọn ẹlomiran lọwọ lati janfaani lati inu ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ti oun ti jere. Nigba ti gbigba ẹbun arokọ naa mú un layọ, ọkan-aya Kiyoe wà lori jijere ẹbun ìyè ainipẹkun.—Fiwe Filippi 3:14.