“Bii Kinniun Tí ń ké Ramuramu”
IWỌ HA gbagbọ pe Satani wà bi? Lonii, ọpọlọpọ ni kò ṣe bẹẹ. Ó dabi ẹni pe wọn ka iru igbagbọ bẹẹ si “alaiba imọ-ijinlẹ mu.” Koda tipẹtipẹ sẹhin ni 1911, iwe naa Encyclopædia Britannica sọ pe: “Imọ-ijinlẹ ti ṣalaye ọpọ iṣeto gbangba ojude ayé ati ti igbesi-aye eniyan ninu lọ́hùn-ún tobẹẹ gẹẹ ti kò fi sí ààyè kankan fun irin iṣẹ́ àmúlò Satani.” Awọn ẹlẹkọọ-isin ronu pe Satani wulẹ jẹ́ àmì iṣapẹẹrẹ kan, arosọ-atọwọdọwọ kan. Iwe naa The World Book Encyclopedia ṣalaye pe: “Ọpọ awọn ẹlẹkọọ-isin ode-oni ka Eṣu si àmì apẹẹrẹ agbara ibi kan, ti animọ iwa eniyan biburu julọ.”
Bi o ti wu ki o ri, ki ni awọn otitọ iṣẹlẹ? Bi iwọ bá gbagbọ ninu Bibeli, iwọ nilati gbagbọ pe Satani jẹ́ ẹni gidi. Jesu kò wulẹ gbagbọ pe ó wà nikan ṣugbọn ó pè é ni “alade ayé yi.” (Johannu 14:30) Aposteli Paulu pe Satani ni “ọlọrun ayé yii.” (2 Korinti 4:4) Aposteli Johannu arugbo naa sì sọ pe: “Gbogbo ayé ni ó wà ni agbara ẹni buburu nì.”—1 Johanu 5:19.
Bi iwọ kò bá gbà pẹlu Johannu, ronu nipa ìtàn lọ́ọ́lọ́ọ́ yii. Gbé awọn ikọ̀ apanirun ati idaniloro tí awọn ijọba ń lò yẹwo. Ranti awọn ogun ati awọn iparun ẹ̀yà tí ìran wa ti foju rí. Ki sì ni nipa awọn iwa-ọdaran abèṣe ti ó jẹ́ akori gadagba awọn iwe-irohin wa—awọn ipakupa rẹpẹtẹ, awọn ifipabanilopọ, awọn iṣekupani ti ó tò tẹlera, ilokulo awọn ọmọde nipasẹ ibalopọ, lati wulẹ mẹnuba diẹ? Ẹnikan yatọ si Satani ha lè jẹ́ ọlọrun ayé yii bi?
Kristian aposteli Peteru kilọ pe: “Ẹ maa ṣọra; nitori Eṣu, ọ̀tá yin, bii kinniun ti ń ké ramuramu, ó ń rìn kaakiri, ó ń wá ẹni ti yoo pa jẹ kiri.” (1 Peteru 5:8) Bi a bá tú kinniun kan silẹ ni adugbo rẹ, iwọ yoo ha maa jiroro boya oun wà tabi oun kò sí bí? Tabi iwọ yoo salọ lati foripamọ?
Jẹ ki o dá ọ loju pe Satani wà. Oun jẹ́ alailaaanu ati abèṣe, oun sì lagbara jù wá lọ. Nitori naa salọ sabẹ aabo lọdọ Ẹni ti ó tun lagbara jù. “Orukọ Oluwa, ile-iṣọ agbara ni: olododo sá wọ inu rẹ̀, ó sì là.” (Owe 18:10) Wá ibòòji sọdọ Jehofa Ọlọrun, ki o sì mọ̀ pe laipẹ iran eniyan yoo dominira kuro labẹ idari ẹni ibi naa, Satani. Ẹ wo iru ìtura aládùn ti eyi yoo jẹ́!—Ìfihàn 20:1-3.