Atètèjí
LAAARIN awọn igi eléso ti agbegbe Meditereniani, igi almondi jẹ́ ọ̀kan lara eyi ti ó pàfiyèsí julọ. Ni apá ipari oṣu January tabi February—tipẹ ṣaaju ọpọ julọ awọn igi miiran—ó ń tají kuro ninu ìrànrán ìgbà ẹ̀rùn rẹ̀. Ẹ sì wo irú ìtají ti eyi jẹ́! Gbogbo igi naa ni ó da aṣọ ìtànná-òdòdó pupa rẹ́súrẹ́sú tabi funfun bora, eyi ti ó gbẹhin naa ń jọ ohun kan bi irun funfun ori arugbo.—Fiwe Oniwasu 12:5.
Awọn Heberu igbaani pe igi almondi ni “olùyárají” naa, ni sísọ̀rọ̀ bá ìyára yọ òdòdó rẹ̀. Animọ yii ni Jehofa lò lati ṣakawe ihin-iṣẹ pataki kan. Ni ibẹrẹ iṣẹ-ojiṣẹ rẹ̀, Jeremiah ni a fi ìran èèhù almondi hàn. Ki ni o tumọsi? Jehofa ṣalaye pe: “Emi ń jí kalẹ nipa ọ̀rọ̀ mi ki n baa lè mú un ṣẹ.”—Jeremiah 1:12, NW.
Gan-an bi igi almondi ti ń yára ‘tají,’ bẹẹ ni Jehofa ti ń “dide ni kutukutu” lati rán awọn wolii rẹ̀ lati kilọ fun awọn eniyan rẹ̀ nipa awọn iyọrisi aigbọran. (Jeremiah 7:25) Oun kò sì ní sinmi—oun yoo ‘jí kalẹ̀’—titi di ìgbà ti ọ̀rọ̀ alasọtẹlẹ rẹ̀ bá tó ṣẹ. Bẹẹ ni ó rí pe ni 607 B.C.E., ni akoko ti a yàn tẹlẹ naa, idajọ Jehofa wá sori orilẹ-ede apẹhinda ti Judah.
Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sọtẹlẹ ṣaaju pe idajọ ti o rí bakan naa yoo wá lodisi eto-igbekalẹ buburu ninu eyi ti a ń gbé. (Orin Dafidi 37:9, 10; 2 Peteru 3:10-13) Ni titọka si iru igbesẹ onidaajọ bẹẹ, wolii Habakkuku mú un da wa loju pe: “Nitori ìran naa jẹ ti ìgbà kan . . . Duro dè é, nitori ni dide, yoo dé, kì yoo pẹ́.” (Habakkuku 2:3) Ìtànná-òdòdó mèremère almondi rán wa leti pe Jehofa yoo jí kalẹ̀ nipa ọ̀rọ̀ rẹ̀ ki ó baa lè mú un ṣẹ.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]
Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.