Wíwá Ìṣúra ti Ó Farasin
NI 1848 wúrà ni a ṣàwárí ni ibi Ẹ̀rọ-Ìlagi ti Sutter ni California, U.S.A. Nigba ti o fi maa di 1849 ẹgbẹẹgbẹrun ti ń kórí jọ sí agbegbe naa ni ireti lati di ọlọ́rọ̀ laipẹ-laijinna, ti ìlébú-ọrọ̀ wúrà ti o ga julọ ninu ìtàn United States si wá ń tẹsiwaju. Ni ọdun kan sii, èbúté San Francisco, ti o sunmọ julọ, gbèrú lati ìwọ̀n ilu kekere kan si ilu-nla ti o ní 25,000 eniyan. Ifojusọna fun ọrọ̀ òjijì wá di ohun ẹ̀tàn lilagbara.
Ọba Solomoni ti Israeli igbaani mọ bi awọn eniyan ti ń gbẹ́lẹ̀ fun iṣura ti a fi pamọ tokunra-tokunra tó, ó sì tọka si eyi nigba ti o kọwe pe: “Àní bi iwọ bá ń ké tọ ìmọ̀ lẹhin, ti iwọ sì gbé ohùn rẹ soke fun òye; bi iwọ bá ṣafẹri rẹ̀ bi fadaka, ti iwọ sì ń wá a kiri bi iṣura ti a pamọ; nigba naa ni iwọ ó mọ ibẹru Oluwa, iwọ ó sì rí ìmọ̀ Ọlọrun.”—Owe 2:3-5.
Pupọ nǹkan ni o lè ṣe pẹlu wura ati fadaka, ṣugbọn iwọ lè ṣe pupọ sii pẹlu òye ati ìfòyemọ̀. Iwọnyi yoo ràn ọ́ lọwọ lati ṣe awọn ipinnu titọna, yanju awọn iṣoro, ṣaṣeyọri ninu igbeyawo, ki o sì rí ayọ. (Owe 2:11, 12) Bakan naa, ìmọ̀ ati ọgbọ́n tootọ yoo ràn ọ́ lọwọ lati mọ Ẹlẹdaa rẹ, lóye awọn ète rẹ̀, lati ṣegbọran sii ki o sì wù ú. Wúrà kò lè fun ọ ni eyikeyii ninu awọn nǹkan wọnyi.
Awọn ọ̀rọ̀ Bibeli jẹ́ otitọ pe: “Ààbò ni ọgbọ́n, gẹgẹ bi owó ti jẹ́ ààbò, ṣugbọn èrè ìmọ̀ ni eyi: pe ọgbọ́n pa iwalaaye awọn ti o ní i mọ́.” (Oniwasu 7:12, New International Version) Nigba ti ọpọlọpọ ń lálàá nipa ọrọ̀ òjijì, ó ti lọ́gbọ́n-nínú lọpọlọpọ tó lati ṣí Bibeli ki a sì gbẹ́lẹ̀ fun ìfòyemọ̀, òye, ìmọ̀, ati ọgbọ́n tii ṣe ọrọ̀ tootọ.