ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 8/15 ojú ìwé 3-4
  • Ìdè Igbeyawo tí Ń Di Aláìlágbára

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìdè Igbeyawo tí Ń Di Aláìlágbára
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Ìkọ̀sílẹ̀ Ló Máa Yanjú Ìṣòro Yín?
    Jí!—2004
  • Ohun Mẹ́rin Tó Yẹ Kó O Mọ̀ Nípa Ìkọ̀sílẹ̀
    Jí!—2010
  • Ipa Tí Ìkọ̀sílẹ̀ Máa Ń Ní Lórí Àwọn Ọmọ
    Ìrànlọ́wọ́ fún Ìdílé
  • Bi A Ṣe Lè Mú Ìdè igbeyawo Lókun Sii
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 8/15 ojú ìwé 3-4

Ìdè Igbeyawo tí Ń Di Aláìlágbára

Ọ̀ṢỌ́Ọ́RỌ́ abiyamọ kan gbá ọmọ rẹ̀ olóṣù-méjì mọ́ra. Lẹhin naa, o fi igbonara ẹhanna jàn án mọlẹ, lojiji. Ọmọkunrin pólóró naa kú ní wakati melookan lẹhin naa. “Mo dìídì jàn án mọlẹ ni,” ni oun wí, “nitori pe ọkọ mi kò bikita nipa idile rẹ̀.” Dipo yiyanju ọ̀ràn naa pẹlu ọkọ rẹ̀, ó yòróró ibinu naa lara ọmọ rẹ̀ ti kò mọwọ́-mẹsẹ̀.

Diẹ ni awọn abiyamọ ti wọn maa ń lọ jinna debi gbígbé iru igbesẹ ti o rekọja ààlà bẹẹ, ṣugbọn bi imọlara pupọ ninu wọn ti ri niyẹn. O ti ń di ohun ti ń le siwaju ati siwaju sii fun awọn tọkọtaya ti wọn ti ṣegbeyawo lati ṣaṣeyọri ninu igbeyawo wọn. “Nigba ti ṣiṣeeṣe aṣeyọri igbeyawo kere tó bi o ti rí ni United States lonii,” ni iwe irohin Journal of Marriage and the Family sọ, “lati jẹ́jẹ̀ẹ́ adehun alagbara kan, ti kò láàlà fun igbeyawo . . . lewu tobẹẹ debi pe kò si eniyan kan ti o gbọ́n-nínú-gbọ́n-lẹ́hìn ti yoo ṣe bẹẹ.”

Ní awọn akoko oníyọnu wọnyi, iwapalapala, aibaramu, gbèsè, èdèkòyedè pẹlu awọn àna, ati imọtara-ẹni-nikan lapapọ ń ta epo si iná ìjà inu ile, eyi ti o sábà maa ń ga debi ikọsilẹ. Ipo naa lekoko ni Japan debi pe Ṣọọṣi Katoliki paapaa, ti o gbajumọ fun iduro rẹ̀ lilagbara lodisi ikọsilẹ, ti ni lati gbe igbimọ akanṣe kan kalẹ lati mu ọ̀ràn dẹrun fun awọn mẹmba Katoliki ti wọn ti gba ikọsilẹ ti wọn sì ti tun igbeyawo ṣe. Iye awọn olùre ṣọọṣi ti ń ga sii ni awọn iṣoro ti o jẹmọ́ ikọsilẹ ti ni ipa lé lori.

Bi o ti wu ki o ri, iye awọn ikọsilẹ fi kiki apa kekere ninu iṣoro ti o tobi gan-an naa hàn. Iwadii ni United States fihàn pe ilọsilẹ ijojulowo igbesi-aye igbeyawo funraarẹ ni o wà lẹhin ibisi ninu ikọsilẹ, dipo awọn itẹsi ẹgbẹ-oun-ọgba lasan ti ń mu ki ikọsilẹ tubọ rọrun. Pẹlu isapa ti kò tó nǹkan ati ẹ̀jẹ́ adehun ti o dinku, igbesi-aye igbeyawo ń padanu ifanimọra rẹ̀ gẹgẹ bi ohun kan ti o dara ju. Pupọ ń fi irisi jíjẹ́ tọkọtaya alajọṣegbeyawo lasan hàn, ṣugbọn wọn kò fi ẹ̀tọ́ lọ́kọláya fun araawọn, agbara kaka ni wọn sì fi ń bá araawọn sọrọ. Awọn kan nimọlara bii ti obinrin ilẹ Gabasi naa ti o ra ilẹ̀ fun isinku rẹ̀ lọ́tọ̀, ni wiwi pe, ‘Emi kò gbà lati wà pẹlu ọkọ mi ninu sàréè.’ Bí kò ti ṣeeṣe fun un lati kọ ọkọ rẹ̀ silẹ nisinsinyi, ó fi í ṣe gongo rẹ̀ lati gba ikọsilẹ lẹhin ikú. Ó banininujẹ pe, bi a kò tilẹ fun iru awọn eniyan bẹẹ ni ikọsilẹ, igbesi-aye igbeyawo kìí ṣe orisun ayọ fun wọn.

Bí ọ̀ràn ti ri pẹlu Isao niyẹn. Ó gbé aya rẹ̀ niyawo pẹlu ìfẹ́-ọkàn ojiji, nitori naa oun kò ni isunniṣe kankan lati yí ọ̀nà igbesi-aye igbera-ẹni-larugẹ rẹ̀ pada. Bi o tilẹ jẹ pe owó geregere ń wọle fun un gẹgẹ bi awakọ akẹ́rù kan, ó ń fi gbogbo owó ti ń wọle fun un ṣòfò sori ounjẹ ati ọti mimu, laibojuto idile rẹ̀. Gẹgẹ bi abajade eyi, ìjà pẹlu aya rẹ̀ kò dopin rí. “Nigbakigba ti awọn nǹkan kò ba ṣẹnuure fun mi,” ni Isao ranti, “emi yoo lọ si ile, emi yoo sì tú ibinu mi dà sori idile mi.” Gẹgẹ bi oke oníná ti ń rú èéfín laidawọduro, ọ̀rọ̀ nipa ikọsilẹ ń bẹ́ silẹ lojoojumọ.

Pupọ awọn ọkunrin ati awọn obinrin ń farada igbeyawo ti kò dara. Yala wọn kọrasilẹ tabi bẹẹkọ, wọn kò rí ayọ. Ọ̀nà kan ha wa fun wọn lati ṣaṣeyọri ninu igbeyawo wọn bi? Ki ni ohun ti wọn lè ṣe lati fun igbeyawo wọn lókun?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́