Omi Ìyè
“ÀTI ẹni tí ó ń gbọ́ kí ó wí pé, Máa bọ̀. Àti ẹni tí òǹgbẹ ń gbẹ kí ó wá. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fẹ́, kí ó gba omi ìyè náà lọ́fẹ̀ẹ́.” (Ìfihàn 22:17) “Omi ìyè”—ìyẹn túmọ̀sí gbogbo ìpèsè Ọlọrun fún ìgbàlà wa tí a gbékarí ẹbọ ìràpadà Jesu Kristi. Àwọn ìpèsè wọ̀nyí wà lárọ̀ọ́wọ́tó, ọ̀fẹ́ sì ni wọ́n. Ẹ wo irú ọ̀làwọ́ àgbàyanu tí èyí jẹ́ ní ipa ti Ọlọrun wa! Bí ó ti wù kí ó rí, èéṣe tí a fi fi omi ṣàpẹẹrẹ wọn?
Ó dára, omiyòómi a máa mú kí ìdàgbàsókè àwọn ohun ọ̀gbìn ṣeéṣe nínú erùpẹ̀, ìyẹn sì mú kí ìwàláàyè ènìyàn ṣeéṣe. Láìsí omi, ìwàláàyè ohun ọ̀gbìn, àti nípa bẹ́ẹ̀ ìwàláàyè ènìyàn, kò lè sí. Síwájú síi, ara rẹ ní omi tí ó jẹ́ ìpín márùndínláàádọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún. Àwọn ògbógi kan nípa ìlera tilẹ̀ dábàá níní ìpíndọ́gba yẹn gẹ́gẹ́ déédéé nípa mímu nǹkan bíi lítà méjì àti ẹ̀sún mẹ́rin omi ní ọjọ́ kan. Gbogbo ìlànà ìṣiṣẹ́ inú rẹ—láti dídà oúnjẹ dé yíya ìdọ̀tí dànù—béèrè fún omi. Bí ìwọ kò bá mu omi fún ọ̀sẹ̀ kan, ìwọ ó kú.
Lọ́nà kan-náà, “omi ìyè” mú ìwàláàyè nípa tẹ̀mi ṣeéṣe ó sì ń fún un ní èròjà. Bí a bá kọ omi ìyè náà sílẹ̀, àwa kò ní ọjọ́-ọ̀la pípẹ́títí kan. (Johannu 3:36) Bí a bá tẹ́wọ́gbà á, a lè jèrè ìyè àìnípẹ̀kun. Abájọ tí obìnrin ará Samaria náà fi dáhùnpadà pẹ̀lú ìháragàgà nígbà tí Jesu wí fún un pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó bá mu nínú omi ti èmi ó fifún un òrùngbẹ kì yóò gbẹ ẹ́ mọ́ láé; ṣùgbọ́n omi tí èmi ó fifún un yóò di kànga omi nínú rẹ̀, tí yóò máa sun sí ìyè àìnípẹ̀kun”! (Johannu 4:14) Ǹjẹ́ kí àwa kí ó nàgà pẹ̀lú irú ìháragàgà kan-náà kí á sì gba omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]
Garo Nalbandian