ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 9/15 ojú ìwé 31
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jẹ́ Kí “Ìrètí Ìgbàlà” Wà Lọ́kàn Rẹ Digbí!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Iwọ Yoo Ha Dahun Pada Si Ifẹ Jesu Bi?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ọjọ́ Ìgbàlà Nìyí!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Àwọn Kristẹni àti Ayé Aráyé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 9/15 ojú ìwé 31

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Nínú Romu 9:3, aposteli Paulu kọ̀wé pé: “Mo fẹ́rẹ̀ẹ́ lè gbàdúrà pé kí á ké èmi tìkáraàmi kúrò lọ́dọ̀ Kristi, nítorí àwọn ará mi, àwọn ìbátan mi nípa ti ara.” Ó ha ní i lọ́kàn pé òun yóò fi ìwàláàyè rẹ̀ lélẹ̀ láti gba àwọn Ju ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ là bí?

Jesu fi àpẹẹrẹ ìfẹ́ gíga jùlọ lélẹ̀. Òun fẹ́ láti fi ẹ̀mí, tàbí ìwàláàyè rẹ̀ lélẹ̀, fún aráyé ẹlẹ́ṣẹ̀. Nígbà iṣẹ́-òjíṣẹ́ ìtagbangba rẹ̀, ó fi ara rẹ̀ lélẹ̀ fún àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè ẹlẹgbẹ́ rẹ̀—àwọn Ju—kí ó baà lè jẹ́ pé iye púpọ̀ bí ó bá ti lè ṣeéṣe tó yóò wà lára àwọn wọnnì tí wọn yóò jàǹfààní láti inú ẹbọ ìràpadà rẹ̀. (Marku 6:30-34) Àìdáhùnpadà àti àtakò wọn sí ìhìn-iṣẹ́ ìgbàlà náà kò mú kí àníyàn onífẹ̀ẹ́ Jesu fún àwọn ènìyàn Ju di tútù láé. (Matteu 23:37) Ó sì fi ‘àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún wa, kí á lè máa tọ ipasẹ̀ rẹ̀.’—1 Peteru 2:21.

Ó ha ṣeéṣe fún àwọn ènìyàn aláìpé láti tẹ̀lé àpẹẹrẹ ìfẹ́ Jesu bí? Bẹ́ẹ̀ni, a sì lè rí àkàwé èyí nínú aposteli Paulu. Ó dàníyàn tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ nípa àwọn Ju ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ débi pé, láti inú ìfẹ́ fún wọn, ó sọ pé òun ì bá dàníyàn pé “kí á ké” òun tìkáraarẹ̀ “kúrò lọ́dọ̀ Kristi” nítorí tiwọn.

Paulu lo irú ọ̀rọ̀ àkàwé, tàbí àsọdùn kan níbẹ̀, láti sọ kókó ọ̀rọ̀ rẹ̀. Jesu lo irú àsọdùn kan-náà nínú Matteu 5:18, nígbà tí ó sọ pé: “Títí ọ̀run òun ayé yóò fi kọjá lọ, ohun kín-ń-kínní kan nínú òfin kì yóò kọjá, bí ó ti wù kí ó rí, títí gbogbo rẹ̀ yóò fi ṣẹ.” Jesu mọ̀ pé ọ̀run àti ayé kì yóò kọjá lọ. Bákan náà ni Paulu kì yóò di ẹni àkékúrò, bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn Ju kì yóò gba ìsìn Kristian. Ṣùgbọ́n kókó ọ̀rọ̀ Paulu ni pé òun yóò ṣe ohunkóhun tí ó bá ṣeéṣe láti ran àwọn Ju lọ́wọ́ láti jọ̀wọ́ araawọn sílẹ̀ fún ọ̀nà ìgbàlà Ọlọrun nípasẹ̀ Jesu Kristi. Abájọ tí aposteli náà fi lè rọ àwọn Kristian ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ máa ṣe àfarawé mi, àní gẹ́gẹ́ bí èmi ti ń ṣe àfarawé Kristi”!—1 Korinti 11:1.

Lónìí, àwọn Kristian gbọ́dọ̀ ní àníyàn kan-náà gẹ́gẹ́ bí Jesu àti Paulu ti ní fún àwọn aláìgbàgbọ́. A kò gbọ́dọ̀ fi ààyè gba àìní ọkàn-ìfẹ́ tàbí àtakò délẹ̀délẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn ní ìpínlẹ̀ ìjẹ́rìí wa láti mú kí ìfẹ́ wa fún àwọn aládùúgbò wa àti ìtara wa fún ríràn wọ́n lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ ọ̀nà ìgbàlà di tútù.—Matteu 22:39.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́