A Ha Pọ́n Ìfàjẹ̀sínilára Jù Bí Ó ti Yẹ Lọ Bí?
Ìfàjẹ̀sínilára wọ́pọ̀ nínú ọ̀nà ìgbàṣe ìwòsàn òde-òní, ṣùgbọ́n wọ́n ha dára tó bí wọ́n ti gbayì tó bí? Kí ni èrò rẹ?
Nínú The American Journal of Medicine (February 1993), Dókítà Craig S. Kitchens béèrè pé: “Ìfàjẹ̀sínilára ni a ha ti pọ́n ju bí ó ti yẹ lọ bí?” Ó ṣàkíyèsí pé àwọn oníṣègùn sábà máa ń fìṣọ́ra kíyèsí yálà àǹfààní ìwòsàn kan pọ̀ ju ewu tí ó lè mú wá lọ. Kí ni nípa ìfàjẹ̀sínilára?
Kitchens ṣàtúnyẹ̀wò ẹ̀rí ọ̀pọ̀ àwọn ewu tí ó sopọ̀ mọ́ ìfàjẹ̀sínilára ẹnu àìpẹ́ yìí, irú bíi àrùn mẹ́dọ̀wú, agbára ìdènà àrùn tí a dílọ́wọ́, ìkùnà ètò-ìgbékalẹ̀ ẹ̀yà ara, àti ìhùwàpadà sẹ́ẹ̀lì ara àjèjì tí ń gbógun ti sẹ́ẹ̀lì inú ara. Ìwádìí kan tí ń ṣàkópọ̀ “àwọn àìlóǹkà ìlọ́júpọ̀” láti inú ìfàjẹ̀sínilára “parí-èrò pé ìfàjẹ̀sínilára kọ̀ọ̀kan ní ọgbọọgba ìwọ̀n ewu 20% fún àwọn ìhùwàpadà aláìbáradé kan, díẹ̀ lára èyí tí kò tó nǹkan ṣùgbọ́n tí àwọn mìíràn léwu fún ara,” tí ó tilẹ̀ lè ṣekúpani pàápàá.
Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn àǹfààní tí a gbàṣebí náà ha dáre fún dídojúkọ irú àwọn ìdágbálé-ewu bẹ́ẹ̀ bí?
Dókítà Kitchens ṣàtúnyẹ̀wò àwọn ìwádìí 16 tí a ròyìn tí ó ní 1,404 iṣẹ́-abẹ lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nínú, tí wọ́n kọ ìfàjẹ̀sínilára ní ìṣègbọràn sí àṣẹ Bibeli láti ‘fàsẹ́yìn kúrò nínú ẹ̀jẹ̀.’—Iṣe 15:28, 29.
Kí ni ìyọrísí rẹ̀? “Ìpinnu àwọn aláìsàn tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jehofa láti yáfì ìfàjẹ̀sínilára fún ọ̀nà-ìgbàṣe iṣẹ́-abẹ líléwu jọ bí pé ó fi 0.5% sí 1.5% iye àwọn ikú kún àpapọ̀ ewu iṣẹ́-abẹ. Èyí tí kò ṣe kedere tó ni bí àìsàn àti ikú tí a yẹra fún nípa ìṣe-àṣà yìí ti pọ̀ tó, ṣùgbọ́n ó ṣeéṣe kí wọ́n pọ̀ rékọja ewu jíjẹ́ ẹni tí a kò fàjẹ̀ sí lára.” (Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.) Kí ni kókó ọ̀rọ̀ rẹ̀? Ewu ìtọ́jú ìṣègùn èyíkéyìí nípa kíkọ ẹ̀jẹ̀ ni ó ṣeéṣe kí ó kéré sí àwọn ewu tí gbígba ìfàjẹ̀sínilára ní nínú.
Fún ìdí èyí, ìbéèrè Kitchen tí ó mọ́gbọ́ndáni pé: “Bí ṣíṣàìfàjẹ̀ sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa bá yọrísí àfikún àìsàn àti ikú mímúná tí kò tó nǹkan níti tòótọ́ tí ó sì yẹra fún iye owó tí ó jọjú kan àti àwọn ìlọ́júpọ̀ wíwà pẹ́títí, ṣé kí àwọn aláìsàn gba ìfàjẹ̀sínilára tí ó kéré síi ni bí?”
Àwọn wọnnì tí wọ́n kọ ìfàjẹ̀sínilára lórí ìpìlẹ̀ irú ẹ̀rí bẹ́ẹ̀ yóò tún máa hùwà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìdarí láti ọ̀dọ̀ Ẹlẹ́dàá wa.