Ìgbà Ìkórè!
ÈÉṢE tí ó fi jẹ́ pé ìtàn “Ìsìn Kristian” ti jẹ́ èyí tí kò rí bíi ti Kristian? Ọ̀pọ̀ àwọn onírònú ènìyàn ń béèrè ìbéèrè yìí, ṣùgbọ́n Jesu dáhùn rẹ̀ ní nǹkan bíi 2,000 ọdún sẹ́yìn nínú òwe àkàwé kan. Ó sọ nípa “ọkùnrin tí ó fún irúgbìn rere sí oko rẹ̀.” Lẹ́yìn náà, “ọ̀tá rẹ̀ wá, ó fún èpò sínú àlìkámà.” Nígbà tí èso náà hù jáde, àwọn òṣìṣẹ́ ṣàkíyèsí àwọn èpò náà wọ́n sì fẹ́ láti fà wọ́n tu. Ṣùgbọ́n ọkùnrin náà sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí àwọn méjèèjì kí ó dàgbà pọ̀ títí di ìgbà ìkórè.” Ni ìgbà ìkórè, àwọn èpò ní a ó yàsọ́tọ̀ kúrò lára àlìkámà.—Matteu 13:24-30.
Jesu, ní ṣíṣàlàyé òwe àkàwé náà, sọ pé òun fúnra òun ni ẹni náà tí ó fún “irúgbìn rere”—àwọn Kristian tòótọ́. Satani ni ọ̀tá náà, tí ó fún àwọn “èpò”—ní mímú kí àwọn àdàmọ̀dì Kristian yọ́ wọnú ìjọ wá. Jesu yọ̀ọ̀da fún àwọn Kristian tòótọ́ àti èké láti wà papọ̀—ṣùgbọ́n kìkì títí di ìkórè. Nígbà náà ní a ó yà wọ́n sọ́tọ̀.—Matteu 24:36-44.
Fún ìdí yìí, kò yà wá lẹ́nu nígbà tí a mọ̀ pé àwọn ètò-àjọ “Kristian” jálẹ̀ àwọn ọ̀rúndún ti tàbùkù sí Ọlọrun nípa títẹ́wọ́gba àwọn ẹ̀kọ́-ìgbàgbọ́ abọ̀rìṣà, gbígba ìwà pálapàla láyè, ṣíṣètìlẹ́yìn fún àwọn ogun àjàṣẹ́gun, àti ṣíṣe àwọn ìwádìí-gbógunti-àdámọ̀ oníwà-ìkà. Nínú èyí ní a ti rí irúgbìn búburú tí Eṣu gbìn ní kedere. Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí a bá kà nípa àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan tí wọ́n jìyà ìfisẹ́wọ̀n tàbí ikú dípò kí wọ́n fi àwọn ìlànà Bibeli bánidọ́rẹ̀ẹ́, a rí i pé irúgbìn rere náà ni a kò parẹ́ ráúráú.
Jesu sọ pé ìkórè jẹ́ “òpin ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan.” Níwọ̀n bí a ti ń gbé lákòókò òpin ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ti ayé ìsinsìnyí, èyí gbọ́dọ̀ jẹ́ ìgbà ìkórè! Nítorí náà ìyàsọ́tọ̀ kan ti gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn Kristian tòótọ́ àti èké. Lónìí, ó yẹ kí àwọn ènìyàn kan wà, kìí wulẹ̀ ṣe àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan tí wọ́n wà káàkiri ṣáá, tí wọ́n bá àpèjúwe àwọn Kristian tòótọ́ mu—tí wọ́n jẹ́ ọmọ-abẹ́ Ìjọba Ọlọrun tí wọ́n sì wàásù ìhìnrere nípa rẹ̀, tí wọ́n gbé ìwàrere tí a gbékarí Bibeli lárugẹ tí wọ́n sì kọ àwọn ẹ̀kọ́-ìgbàgbọ́ abọ̀rìṣà sílẹ̀ ní ìtìlẹ́yìn fún òtítọ́ Bibeli, tí wọ́n sọ orúkọ Ọlọrun di mímọ̀ tí wọn kìí sìí ṣe apákan ayé.—Matteu 6:33; 24:14; Johannu 3:20; 8:32; 17:6, 16.
A mú un dá ọ lójú pé, irúfẹ́ àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ wà! Ìwọ ha fẹ́ láti ṣiṣẹ́sin Ọlọrun lọ́nà tí o ṣètẹ́wọ́gbà bí? Nígbà náà wá àwọn ènìyàn yìí rí, kí o sì ṣiṣẹ́sin Ọlọrun pẹ̀lú wọn.