Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Ojoojúmọ́ Fún Ọdún1994
FEBRUARY
1. Kiyesi i, emi ó rán onṣẹ mi, yoo si tun ọ̀nà ṣe niwaju mi.—Mal. 3:1. w-YR 12/1/92 3, 4a
2. Ẹ pa araayin mọ́ kuro ninu oriṣa.—1 Joh. 5:21. w-YR 1/15/93 19, 20a
3. Nititori eyi mo fi awọn eékún mi kúnlẹ̀ fun Baba, ẹni ti olukuluku idile ní ọrun ati lori ilẹ̀-ayé jẹ ní gbèsè orukọ rẹ̀.—Efe. 3:14, 15. w-YR 10/15/92 1, 2
4. Nitori ayọ ni ẹ o fi jade, alaafia ni a o fi tọ́ yin.—Isa. 55:12. w-YR 9/15/92 3, 4
5. Ẹ lọ ki ẹ sì sọ awọn eniyan gbogbo orilẹ-ede di ọmọ-ẹ̀yìn, ki ẹ maa baptisi wọn ni orukọ Baba ati ti Ọmọkunrin, ati ti ẹmi mímọ́.—Matt. 28:19. w-YR 9/1/92 2-5
6. Ẹ yin Jah, ẹyin eniyan! Ẹ fi iyin fun un, Oo ẹyin iranṣẹ Jehofa, ẹ yin orukọ Jehofa. Ǹjẹ́ ki orukọ Jehofa di abùkún-fún lati isinsinyi lọ àní titilọ gbére.—Orin Da. 113:1, 2, NW. w-YR 11/15/92 4, 5
7. Ọmọ mi, fiyesi ọgbọ́n mi, ki o si dẹti rẹ si oye mi. Lati maa pa ironu mọ́ ati ki ètè rẹ le pa imọ mọ́.—Owe 5:1, 2. w-YR 11/1/92 5, 6a
8. Ranti ẹlẹdaa rẹ nisinsinyi ni ọjọ ewe rẹ.—Oniwasu 12:1. w-YR 1/1/93 13, 14
9. Nigba naa ni inu rẹ yoo dùn si ẹbọ ododo; pẹlu ọrẹ-ẹbọ sisun ati ọ̀tọ̀tọ̀ ọrẹ-ẹbọ sisun.—Orin Da. 51:19. w-YR 3/15/93 20, 21a
10. Ẹ tẹriba, fun Ọlọrun.—Jak. 4:7. w-YR 2/1/93 1, 2a
11. Ki ẹ si mu aṣibori igbala, ati idà ẹmi, ti i ṣe ọ̀rọ̀ Ọlọrun: Pẹlu gbogbo adura ati ẹbẹ ni ki ẹ maa gbadura nigba gbogbo ninu ẹmi, ki ẹ si maa ṣọra si i ninu iduroṣinṣin gbogbo, ati ẹ̀bẹ̀ fun gbogbo eniyan mímọ́.—Efe. 6:17, 18. w-YR 2/15/93 13a
12. Wọn ki yoo panilara, bẹẹni wọn ki yoo panirun ni gbogbo oke mímọ́ mi: nitori aye yoo kún fun imọ Oluwa gẹgẹ bi omi ti bo okun.—Isa. 11:9. w-YR 10/1/92 17, 18a
13. Lati ila-oorun titi o fi de ìwọ̀ rẹ̀ orukọ Oluwa ni ki a yìn.—Orin Da. 113:3. w-YR 11/15/92 6, 7
14. Bi awa ba mọọmọ dẹṣẹ lẹ̀yìn igba ti awa ba ti gba imọ otitọ kò tun si ẹbọ fun ẹṣẹ mọ́, bikoṣe ireti idajọ tí ó banilẹru.—Heb. 10:26, 27. w-YR 9/15/92 6
15. Èrò-inú wọn wà ninu okùnkùn, ti a si sọ wọn dàjèjì si ìyè tí ó jẹ ti Ọlọrun, nitori àìmọ̀kan ti ń bẹ ninu wọn, nitori àìmòye ọkàn-àyà wọn.—Efe. 4:18, NW. w-YR 3/1/93 10, 11
16. Bẹẹ gẹgẹ ẹyin ọkọ, ẹ maa fi òye bá awọn aya yin gbé, ẹ maa fi ọlá fun aya, bi ohun eelo ti kò lagbara, . . . ki adura yin ki o ma baa ni idena.—1 Pet. 3:7. w-YR 10/15/92 9, 10
17. Mo mọ̀ pe, oun o fi aṣẹ fun awọn ọmọ rẹ̀ ati fun awọn ara ile rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀, ki wọn ki o maa pa ọ̀nà OLUWA mọ́ lati ṣe ododo ati idajọ.—Gen. 18:19. w-YR 11/1/92 2-4
18. Bayii ni Ọlọrun Oluwa wi, ẹni tí ó dá ọrun, tí ó si nà wọn jade; ẹni tí ó tẹ́ aye, ati ohun tí ó ti inu rẹ̀ wá; ẹni tí ó fi èémí fun awọn eniyan lori rẹ̀, ati ẹmi fun awọn tí ó ń rin ninu rẹ̀.—Isa. 42:5. w-YR 12/1/92 2, 3
19. A o si waasu ihinrere ijọba yii ni gbogbo aye.—Matt. 24:14. w-YR 9/15/92 6-8b
20. Israeli, iwọ gbẹkẹle Oluwa: oun ni iranlọwọ wọn ati asà wọn. Ẹyin tí ó bẹru Oluwa, gbẹkẹle Oluwa: oun ni iranlọwọ wọn ati asà wọn.—Orin Da 115:9, 11. w-YR 11/15/92 17
21. Oluwa! emi mọ pe, ọ̀nà eniyan kò si ni ipa araarẹ̀: kò si ni ipá eniyan ti ń rin lati tọ́ iṣisẹ rẹ̀.—Jer. 10:23. w-YR 2/1/93 2, 3
22. Iwọ ti pèsè silẹ loju gbogbo eniyan, ìmọ́lẹ̀ kan fún mímú ìbòjú kuro loju awọn orilẹ-ede ati ògo awọn eniyan rẹ Israeli.—Luku 2:31, 32, NW. w-YR 1/15/93 4-6
23. Emi o yọ̀ gidigidi ninu Oluwa, ọkàn mi yoo yọ ninu Ọlọrun mi; nitori o ti fi [aṣọ ìgbàlà wọ mi, NW].—Isa. 61:10. w-YR 1/1/93 2, 3
24. Mu ọkàn-aya mi ṣọ̀kan lati bẹ̀rù orukọ rẹ.—Orin Da. 86:11, NW. w-YR 12/15/92 7a
25. Bi ẹnikẹni ninu yin láyé yii ba rò pe oun gbọ́n, ẹ jẹ ki o di aṣiwere, kí ó lè baà gbọ́n.—1 Kor. 3:18. w-YR 9/15/92 16, 17b
26. Ta ni ki yoo bẹru, Oluwa, ti kì yoo si fi ogo fun orukọ rẹ? nitori iwọ nikanṣoṣo ni mímọ́: gbogbo awọn orilẹ-ede ni yoo si wá, ti yoo si foribalẹ niwaju rẹ̀; nitori a ti fi ìdájọ́ rẹ hàn.—Ìfi. 15:4. w-YR 11/15/92 4-6b
27. Níwọ̀n bí wọ́n ti wá rékọja gbogbo agbára òye ìwàrere, wọ́n fi ara wọn fún ìwà àìníjàánu lati máa fi ìwà ìwọ̀ra hu onírúurú ìwà àìmọ̀ gbogbo.—Efe. 4:19, NW. w-YR 3/1/93 16
28. Kiyesi i, ninu aiṣedeedee ni a gbé bí mi: ati ninu ẹ̀ṣẹ̀ ni ìyá mi sì lóyún mi.—Orin Da. 51:5. w-YR 3/15/93 14, 15