Alẹ́ Kan Láti Rántí
Í ỌJỌ́ mánigbàgbé kan ní ohun tí ó ju 3,500 ọdún sẹ́yìn, Jehofa Ọlọrun mú kí àwọn ọmọ Israeli tí wọ́n ń sìnrú ní Egipti pa ọ̀dọ́-àgùtàn kan kí wọ́n sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sára àwọn òpó-ìlẹ̀kùn àti àtẹ́rígbà ilé wọn. Ní alẹ́ yẹn gan-an, angẹli Ọlọrun rékọjá àwọn ilé tí a sàmì sí lọ́nà yìí ṣùgbọ́n ó pa àwọn àkọ́bí ọmọkùnrin nínú ilé gbogbo àwọn ará Egipti. Nígbà náà ni a dá àwọn ọmọ Israeli sílẹ̀. Láti ìgbà náà wá, ní àyájọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn, ni àwọn Ju ti ń ṣayẹyẹ Ìrékọjá.
Ní kété lẹ́yìn tí Jesu Kristi parí ṣíṣayẹyẹ Ìrékọjá tí ó ṣe gbẹ̀yìn pẹ̀lú àwọn aposteli rẹ̀, ó dá oúnjẹ kan sílẹ̀ tí yóò jẹ́ ìṣèrántí ikú ìrúbọ rẹ̀. Ó fún àwọn aposteli rẹ̀ olóòótọ́ ní búrẹ́dì ó sì wí pé: “Gbà, jẹ; èyíyìí ni ara mi.” Lẹ́yìn náà ni ó fún wọn ní wáìnì ó sì wí pé: “Gbogbo yín ẹ mu nínú rẹ̀; nítorí èyí ni ẹ̀jẹ̀ mi ti májẹ̀mú titun, tí a ta sílẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ènìyàn fún ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀.” Jesu tún sọ pé: “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” (Matteu 26:26-28; Luku 22:19, 20) Nítorí náà Jesu pàṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti ṣe ayẹyẹ ikú rẹ̀ yìí.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fi tọ̀yàyà tọ̀yàyà késí ọ láti darapọ̀ mọ́ wọn láti ṣayẹyẹ Ìṣe-Ìrántí ikú Jesu yìí. O lè pésẹ̀ síbẹ̀ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tí ó súnmọ́ ilé rẹ jùlọ. Béèrè fún àkókò pàtó àti ibi tí a óò ti ṣe é lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí àdúgbò rẹ. Ọjọ́ ayẹyẹ náà ní ọdún 1994 jẹ́ Saturday, March 26, búrẹ́dì àti àkàrà ní a óò gbékiri lẹ́yìn tí oòrùn bá ti wọ̀.