Alákòókò Kan Náà Fún Ọdún Mẹ́wàá!
NÍGBÀ tí a béèrè bí ìmọ̀lára rẹ̀ ti rí ní ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn nígbà tí ìtẹ̀jáde Ilé-Ìṣọ́nà ní èdè Spanish bẹ̀rẹ̀ síí jáde ní àkókò kan náà pẹ̀lú ti èdè Gẹ̀ẹ́sì, arábìnrin ọ̀wọ́n kan tí ń sọ èdè Spanish dáhùnpadà pé: ‘A nímọ̀lára pé ìbùkún ni ó jẹ́ nítorí pé nísinsìnyí, ṣe ẹ ríi, a wà ní ìpelè kan náà pẹ̀lú èdè Gẹ̀ẹ́sì. Nígbà tí mo bá sọ pé èdè Gẹ̀ẹ́sì, mo máa ń ronú ètò-àjọ náà nígba gbogbo. A ń tọ́kasí ètò-àjọ náà gẹ́gẹ́ bí “Ìyá.” A nímọ̀lára sísúnmọ ọn, pẹ́kípẹ́kí. Ó wuni, ó kàmàmà!’
Arábìnrin olùṣòtítọ́ yìí sọ ìmọ̀lára ọ̀pọ̀ àwọn òǹkàwé tí kìí ka èdè Gẹ̀ẹ́sì jáde. Ní àwọn ọdún tí ó ti kọjá, àwọn ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ máa ń farahàn nínú ìtẹ̀jáde Ilé-Ìṣọ́nà ní èdè Spanish lẹ́yìn nǹkan bí oṣù mẹ́fa tí a ti tẹ̀ wọ́n jáde ní èdè Gẹ̀ẹ́sì. Àwọn èdè mìíràn ní ìrírí irú ìfàsẹ́yìn kan náà. Lọ́nà tí ó yéni, ìfẹ́-ọkàn gíga wà fún títẹ àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ kan náà, ní àkókò kan náà, ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ èdè.
Nítorí náà bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìtẹ̀jáde April 1, 1984, ìtẹ̀jáde èdè Spanish ni àkọ́kọ́ láti jáde ní àkókò kan náà pẹ̀lú ìtẹ̀jáde ti èdè Gẹ̀ẹ́sì. Àwọn èdè mìíràn tẹ̀lé e láìpẹ́. Nígbà tí ó fi di ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1985, àwọn ìtẹ̀jáde ní èdè 23 ti ń jáde ní àkókò kan náà. Bí a tí ń rí àwọn olùtúmọ̀ tí a sì ń kọ́ wọn, àwọn ìtẹ̀jáde ní èdè púpọ̀ síi bá ti èdè Gẹ̀ẹ́sì ṣe déédéé.
Ẹ̀dá Ilé-Ìṣọ́nà yìí sàmìsí ọdún kẹwàá ti ìtẹ̀jáde alákòókò kan náà. Ilé-Ìṣọ́nà ní a ń tẹ̀ jáde ní 116 èdè, 85 nínú wọn jẹ́ onígbàkan náà. Èyí túmọ̀sí pé ìpín 99.3 nínú ọgọ́rùn-ún àròpọ̀ ìpíndọ́gba ẹ̀dà 16,100,000 Ilé-Ìṣọ́nà ni a ń pèsè pẹ̀lú àwòrán èèpo ẹ̀yìn àti ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ kan náà. Níti àwọn tí wọ́n ń pésẹ̀ síbi Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé-Ìṣọ́nà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀, ìpín tí ó ju 95 nínú ọgọ́rùn-ún ní wọ́n ń gbé àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ kan náà yẹ̀wò ní àkókò kan náà.
Jí!, ìwé ìròyìn tí ó ṣìkejì Ilé-Ìṣọ́nà, ní a ń tẹ̀ jáde ní àkókò kan náà ní 37 nínú 74 èdè rẹ̀. Ìwé ọdọọdún náà Yearbook of Jehovah’s Witnesses ni a ń tẹ̀ jáde ní èdè 18. Irú àwọn ìtẹ̀jáde alákòókò kan náà bẹ́ẹ̀ ń ṣiṣẹ́ láti so àwọn ènìyàn Ọlọrun pọ̀ ṣọ̀kan “ní inú kan náà, àti ní ìmọ̀ kan náà.”—1 Korinti 1:10.