ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 4/15 ojú ìwé 32
  • Wọ́n Ṣeyebíye Ju Iyùn Lọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wọ́n Ṣeyebíye Ju Iyùn Lọ
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 4/15 ojú ìwé 32

Wọ́n Ṣeyebíye Ju Iyùn Lọ

Iye tí ó túbọ̀ ń pọ̀ síi lára àwọn olùṣèbẹ̀wò ni ìmọ̀lára wọn ti rusókè sí irú àwọn àṣefihàn bí irú èyí nínú omi Òkun Pupa.

Àìlóǹkà àwọn ẹja tí wọ́n ní àwọ̀ òṣùmàrè fa ojú àwọn òmùwẹ̀ tí wọ́n wà ninu omi mímọ́gaara náà mọ́ra. Ṣùgbọ́n ṣàkíyèsí pé ní àyíká àwọn ẹja mèremère tí a rí níhìn-⁠ín ni àwọn ohun ìyanu abẹ́ inú omi mìíràn tí wọ́n jojúnígbèsè wà, tí ó ní nínú àwọn iyùn aláwọ̀ títànyòò.

Àwọn iyùn dáradára náà ni a ń rí ní oríṣiríṣi ìrísí àti àwọ̀. Gẹ́gẹ́ bí o ṣe lè finúwòye, àwọn iyùn mèremère ni a kà sí iyebíye, àní ní àwọn ìgbà àtijọ́ pàápàá. Àwọn oníṣọ̀nà ń lò wọ́n láti fi ṣe àwọn ohun-ọ̀ṣọ́ dídára, àwọn òǹkọ̀wé Bibeli dárúkọ iyùn papọ̀ pẹ̀lú wúrà, fàdákà, àti òkúta rúbì. (Owe 3:​14, 15; Esekieli 27:16) Ṣùgbọ́n àwọn òǹkọ̀wé yẹn ràn wá lọ́wọ́ láti ríran rékọjá ẹwà àti ìníyelórí àwọn iyùn yẹn fúnraawọn.

Wọ́n tẹnumọ́ ọn pé àwọn ohun kan tilẹ̀ tún níyelórí ju wọ́n lọ àti pé ó yẹ kí a túbọ̀ mọyì wọn lọ́pọ̀lọpọ̀. Aya rere kan tí ó dáńgájíá jẹ́ ọ̀kan, nítorí tí a kà pé: “Ta ni yóò rí obìnrin oníwàrere? nítorí tí iye rẹ̀ kọjá iyùn.” (Owe 31:10) Iwọ ha jẹ́ ọkùnrin kan tí ó ti gbéyàwó bí? Tún àwọn iyùn tí wọ́n jojúnígbèsè tí wọ́n wà níhìn-⁠ín wò dáradára, kí o sì ronú lórí bóyá ìwọ ń bu iyì fún aya rẹ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe tọ́ sí i.

Bóyá a jẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin, ẹni tí ó ti ṣe ìgbéyàwó tàbí àpọ́n, àwòrán àwọn iyùn tí ó lógo ẹwà yẹ kí ó ràn wá lọ́wọ́ láti mọrírì ìníyelórí tí ó túbọ̀ ga jù ti ọgbọ́n, ìfòyemọ̀, àti òye Ọlọrun. Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sọ pé: “Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó wá ọgbọ́n rí, àti ọkùnrun náà tí ó gba oyè. Nítorí tí owó rẹ̀ ju owó fàdákà lọ, èrè rẹ̀ sì ju ti wúrà dáradára lọ. Ó ṣe iyebíye ju iyùn lọ: àti ohun gbogbo tí ìwọ lè fẹ́, kò sí èyí tí a lè fi wé e.”​—⁠Owe 3:13-⁠15; 8:⁠11.

Nítorí náà bóyá a rí wọn nígbà tí a ń lúwẹ̀ẹ́ fúnraawa tàbí nínú àwòrán, àwọn iyùn inú Òkun Pupa yẹ kí ó mú kí a mọ ẹwà kí a sì ronú jinlẹ̀ lọ́nà tí ń mú èrè wá.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́