ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 5/1 ojú ìwé 31
  • Ó Tẹ̀lé Ẹ̀rí-Ọkàn Rẹ̀ Tí A Fi Bibeli Kọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ó Tẹ̀lé Ẹ̀rí-Ọkàn Rẹ̀ Tí A Fi Bibeli Kọ́
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bó O Ṣe Lè Ní Ẹ̀rí Ọkàn Rere
    ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’
  • Ǹjẹ́ o Kọ́ Ẹ̀rí Ọkàn Rẹ Dáadáa?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Ṣé Ẹ̀rí Ọkàn Rẹ Ṣeé Gbára Lé?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Kọ́ Ẹ̀rí Ọkàn Mi?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 5/1 ojú ìwé 31

Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn

Ó Tẹ̀lé Ẹ̀rí-Ọkàn Rẹ̀ Tí A Fi Bibeli Kọ́

DAFIDI ọba Israeli gbàdúrà sí Jehofa fún ìrànlọ́wọ́ nígbà tí ó sọ pé: “Bí ó ṣe ti èmi, èmi ó máa rìn nínú ìwàtítọ́ mi: rà mí padà, kí o sì ṣàánú fún mi.” (Orin Dafidi 26:11) Ọlọrun fi ojúrere hàn sí i fún pípa ìwàtítọ́ rẹ̀ mọ́. Jehofa tún bùkún Jesu nítorí pé ó ṣe ìfẹ́-inú Baba rẹ̀ ọ̀run, Òun sì bùkún èwe kan tí ó tẹ̀lé ẹ̀rí-ọkàn rẹ̀ tí a fi Bibeli kọ́ tí ó sì pinnu láti ṣe ìfẹ́-inú Ọlọrun ní Colombia. Ọ̀dọ́mọkùnrin yìí ròyìn pé:

“Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ síí kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, mo jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ nínú ilé-ẹ̀kọ́ Katoliki kan. Bí ó ti wù kí ó rí, ẹ̀rí-ọkàn mi dà mí láàmú nígbà tí mo lọ síbi ìsìn Mass, nítorí náà mo lọ sọ́dọ̀ ọ̀gá ilé-ẹ̀kọ́ (tí ó jẹ́ àlùfáà), ẹni tí ń fún àwọn ọmọ ilé-ẹ̀kọ́ ní ìtọ́sọ́nà, àti ẹní tí ń ṣàbójútó àwùjọ tí mo wà pé kí wọ́n yọ̀ọ̀da mi láti máṣe máa lọ sí ibi ìsìn Mass. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n yọ̀ọ̀da mi, àwọn díẹ̀ gbìyànjú láti fipá mú mi lọ. Ìkìmọ́lẹ̀ náà ga síi ní kété lẹ́yìn ìrìbọmi mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Baba mi halẹ̀ pé òun yóò lé mi kúrò nílé bí wọ́n bá lé mi kúrò ní ilé-ẹ̀kọ́. Òun ní ẹ̀kọ́-ìwé yunifásítì àti iṣẹ́ ìgbésí-ayé gẹ́gẹ́ bí amọṣẹ́dunjú kan lọ́kàn fún mi.

“Ọ̀gá ilé-ẹ̀kọ́ náà fúnni ní ìkìlọ̀ léraléra nípa ẹnikẹ́ni tí ó bá kùnà láti pa àwọn ojúṣe àìgbọ́dọ̀máṣe ti Katoliki mọ́. Nígbà tí àkókò ìsìn Mass àkọ́kọ̀ nínú ọdún tó, mo farapamọ́ títí tí ó fi parí. Lẹ́yìn náà ni mo fún olùkọ́ náà (àlùfáà kan) ní ẹ̀dà kan ìwé-pẹlẹbẹ náà School and Jehovah’s Witnesses mo sì sọ fún un pé gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, èmi kò lè wá síbi ìsìn Mass. Ó wí pé: ‘O jẹ́ tètè máa wá ilé-ẹ̀kọ́ mìíràn.’ Mo mọ̀ pé lílé mi kúrò ní ilé-ẹ̀kọ́ yóò túmọ̀sí pé baba mi yóò lé mi jáde kúrò nílé. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, mo gbàdúrà sí Jehofa mo sì ń báa lọ láti máa jẹ́rìí ní kíkún fún àwọn ọmọ ilé-ẹ̀kọ́ ẹlẹgbẹ́ mi.

“Àkókò ìsinmi kúrò ní ilé-ẹ̀kọ́ dé. Lẹ́yìn náà, a padà sí ilé-ẹ̀kọ́ lẹ́yìn ìsinmi, àkókò ìsìn Mass tún tó. Ọ̀gá ilé-ẹ̀kọ́ àti àwọn àlùfáà mìíràn wà ní iwájú ṣọ́ọ̀ṣì kékeré, wọ́n ti múratán láti gbọ́ ìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀. Ìbẹ̀rù fẹ́rẹ̀ẹ́ ṣẹ́gun mi. Mo wọlé mo sì jókòó, ṣùgbọ́n ẹ̀rí-ọkàn mi dà mí láàmú. Nígbà tí orin kíkọ bẹ̀rẹ̀, mo ronú pé, ‘Kí ni mó ń ṣe níhìn-⁠ín? Jehofa ni Ọlọrun mi. Èmi kò lè jẹ́ ojo kí nsì sẹ́ ẹ. Èmi kò lè já a kulẹ̀. Òun kì yóò kọ̀ mí tì.’ Mo gbàdúrà fún ìgboyà. Lẹ́yìn náà, mo rìn jáde kúrò nínú ṣọ́ọ̀ṣì kékeré náà mo sì tò sórí ìlà ìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀. Nígbà tí mo dé ọ̀dọ̀ ọ̀gá ilé-ẹ̀kọ́, mo sọ fún un pé: ‘Olùkọ́, èmi kì yóò jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀.’ Ó wí pé: ‘Èmi náà ronú bẹ́ẹ̀.’ Mo sọ fún un pé mo múratán láti jìyà àwọn abájáde náà ṣùgbọ́n pé ẹ̀rí-ọkàn mi kò yọ̀ọ̀da fún mi láti kópa nínú ìsìn Mass. Èmi kò lè hùwà lòdìsí àwọn nǹkan tí mo ti kọ́ láti inú Bibeli.

“Ó wò mí, ó rẹ́rìn-⁠ín músẹ́, ó sì wí pé: ‘Mo kan sáárá sí ọ. Gbogbo ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ Ẹlẹ́rìí ni ẹ yẹ ní kíkan sáárá sí. Fún yín, Ọlọrun ni ó wà ní ipò àkọ́kọ́, ẹ sì ṣetán láti ṣègbọràn sí àwọn òfin rẹ̀ ohun yòówù kí ó ṣẹlẹ̀. Ẹ máa báa nìṣó. Ẹ ń ṣe dáradára. Mo dàníyàn pé kí gbogbo Katoliki dàbí tiyín, ní fífi irú ìtara, àti ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ hàn fún Ọlọrun. Láti ìsinsìnyí lọ, a yọ̀ọ̀da rẹ kúrò nínú lílọ́wọ́ sí àwọn ìpàdé ìjọsìn wa.’ Ẹ wo bí mo ti láyọ̀ tó! Jehofa ti bùkún ìpinnu mi láti ṣègbọràn sí ẹ̀rí-ọkàn mi tí a fi Bibeli kọ́.

“Ní ọjọ́ kejì ọ̀gá ilé-ẹ̀kọ́ náà sọ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ pé: ‘Àwọn ìsìn mìíràn ti yà wá sílẹ̀. Èéṣe tí àwa kò fi dàbíi wọn, kí a ní ìtara, pẹ̀lú ìfẹ́ jíjinlẹ̀ fún Ọlọrun àti ìfẹ́-ọkàn láti ṣiṣẹ́sìn-⁠ín borí ohun gbogbo yòókù? Èyí jẹ́ ohun kan tí ó yẹ kí ó wà nínú ọkàn-àyà wa.’

“Ní àkótán ọ̀gá ilé-ẹ̀kọ́ náà ni a gbé lọ sí Romu, ọ̀gá ilé-ẹ̀kọ́ títun náà sì wulẹ̀ ṣàìka àìkópa mi sí. Baba mi kó kúrò nínú ilé, ní fífún mi ní òmìnira láti lé góńgó iṣẹ́-òjíṣẹ́ alákòókò kíkún mi bá lẹ́yìn tí mo kẹ́kọ̀ọ́yege.”

Jehofa bùkún ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó tẹ̀lé ẹ̀rí-ọkàn rẹ̀ tí a fi Bibeli kọ́ yìí. Bákan náà ni òun yóò ṣe bùkún gbogbo àwọn wọnnì tí wọ́n bá wá ọ̀nà láti ṣe ìfẹ́-inú rẹ̀.​—⁠Owe 3:​5, 6.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́