Ìwọ Ha Mọyì Bibeli Bí?
NÍ KÌKÌ 200 ọdún sẹ́yìn, a bí Mary Jones ní Llanfihangel, abúlé Wales kan tí ó wà ní àdádó tí kò fi bẹ́ẹ̀ jìn sí bèbè etíkun Atlantic. Òtòṣì ahunṣọ ni àwọn òbí rẹ̀—wọ́n tòṣì púpọ̀ jù tí wọn kò fi lè ní Bibeli kan lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n wọ́n gbin ìfẹ́ fún Ọlọrun sínú ọmọbìnrin wọn nípa sísọ àwọn ìtàn Bibeli fún un àti ṣíṣe àsọtúnsọ àwọn ẹsẹ̀ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n bá rántí. Mary sábà máa ń ka Bibeli èdè Welsh kan tí ó jẹ́ ti aládùúgbò rẹ̀ ó sì bẹ̀rẹ̀ síí tọ́jú owo táṣẹ́rẹ́ tí agbára rẹ̀ ká, bí ó ti pinnu láti ra ọ̀kan tí yóò jẹ́ tirẹ̀.
Ní ọdún 1800, nígbà tí Mary jẹ́ ẹni ọdún 16, ó gbọ́ pé àwọn Bibeli díẹ̀ lédè Welsh wà fún títà ní Bala ìlú kékeré tí ó jìn tó 40 kìlómítà. Láìkáàárẹ̀, ó pinnu láti rìn lọ síbẹ̀. Ẹsẹ̀ lásán ni ó fi rìn sọdá àwọn òkè kékeré. Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí ó fi máa débẹ̀, wọ́n ti ta gbogbo ẹ̀dà náà tán. Mary tún lóye pé àpapọ̀ owó tí òun ti tójúpamọ́ ti kéré púpọ̀ púpọ̀ jù.
Ìmọ̀ àti ìfẹ́ tí Mary ní fún Bibeli wọ pásítọ̀ àdúgbò náà lọ́kàn lọ́nà jíjinlẹ̀. Ní rírí omijé ìjákulẹ̀ rẹ̀ lẹ́yìn gbogbo ìsapá tí ó ti ṣe, ó finúrere fún un ní ẹ̀dà tirẹ̀, ní wíwí pé: “Kà á dáradára, fi taápọntaápọn kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, tọ́jú àwọn ọ̀rọ̀ mímọ́-ọlọ́wọ̀ rẹ̀ sínú iyè ìrántí rẹ, kí o sì gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀.”
A tún ìtàn yìí sọ lẹ́yìn náà níbi ìpàdé Committee of the Religious Tract Society ti London. Níbẹ̀ ni wọ́n ti ṣe ìpinnu náà láti mú kí àwọn ìtumọ̀ Bibeli wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún gbogbo àgbáyé kìí ṣe fún àwọn ènìyàn ìlú Wales nìkan. Láti ìgbà ìbẹ̀rẹ̀ wẹ́rẹ́ yìí ni èyí àkọ́kọ́ nínú àwọn ẹgbẹ́ tí ń tẹ Bibeli jáde ti ọ̀rúndún kọkàndínlógún ti jáde wá. Lẹ́yìn ìgbà náà, àwọn Bibeli tí a kọ ní èdè àjèjì bẹ̀rẹ̀ síí farahàn lọ́nà tí ń yára pọ̀ síi.
Lónìí, Watch Tower Bible and Tract Society, tí a sọ di ẹgbẹ́ kan lábẹ́ òfin ní 1884, ń tẹ àwọn Bibeli àti àwọn ìwé tí ń rannilọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ní èdè tí ó ju 200 lọ. Kárí-ayé, ó ti ṣe ìpínkiri ẹ̀dà million 72 lára New World Translation of the Holy Scriptures tí a tẹ̀ ní èdè òde-òní. Bibeli New World Translation tí a túmọ̀ láti inú èdè Heberu àti Griki ìpilẹ̀ṣẹ̀ ti wà lárọ̀ọ́wọ́tó nísinsìnyí lódidi tàbí ní apákan ní èdè 18 a sì ń túmọ̀ rẹ̀ sí àwọn èdè 12 mìíràn ní àfikún ní lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí.
Nísinsìnyí tí Bibeli ti fẹ́rẹ̀ẹ́ wà lárọ̀ọ́wọ́tó gbogbo ènìyàn, ojú wo ni ìwọ fi ń wò ó? Ìwọ ha mọyì Bibeli bí? Ìwọ ha ni ẹ̀dà kan tí o kà sí iyebíye tí o sì ń kà bí?
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]
Láti inú ìwé náà The Story of Mary Jones and Her Bible