Ìhìnrere Láti Malawi!
ÓMÚNILỌ́KÀNYỌ̀ láti gbọ́ pé ní November 15, 1993, Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania ni a forúkọ rẹ̀ sílẹ̀ lábẹ́ òfin ní gúúsù ìlà-oòrùn orílẹ̀-èdè Africa náà Malawi. Èyí yóò fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní ìdámọ̀ lábẹ́ òfin àti òmìnira láti wàásù àwọn òtítọ́ Bibeli fún àwọn ènìyàn Malawi.
Nígbà náà lọ́hùn-ún ní ọdún 1948, a fìdí ọ́fíìsì ẹ̀ka Watch Tower Society kan múlẹ̀ ní Malawi láti ṣe kòkáárí iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní ilẹ̀ yẹn. Ní January 8, 1957, a fi orúkọ Watch Tower Society sílẹ̀ níbẹ̀ fún ìgbà àkọ́kọ́. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa gbádùn ìdàgbàsókè yíyára kánkán fún àwọn ọdún mélòókan. Ṣùgbọ́n inúnibíni oníwà-ipá bẹ́sílẹ̀ ní 1964. Èéṣe?
Ní ìṣègbọ́ràn sí Ọlọrun, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa di ipò àìdásítọ̀tún-tòsì nínú ìṣèlú mú láìgbagbẹ̀rẹ́. (Johannu 17:16) Lọ́nà tí ó hàn gbangba, àwọn kan kò lóye ipò tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu yìí wọ́n sì fi àwọn Ẹlẹ́rìí hàn lọ́nà òdì gẹ́gẹ́ bí ìsìn olójú-ìwòye àṣerégèé àti gẹ́gẹ́ bí arúfin. Nípa báyìí, àwọn kan rò pé inúnibíni tí wọ́n ń ṣe sí àwọn Kristian olùfẹ̀ẹ́ àlááfíà wọ̀nyí bá ìdájọ́-òdodo mu. Ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí ni a lé dànù lẹ́nu iṣẹ́ wọn, ni a lù, tí a sì tẹ́ lógo ní ọ̀nà mìíràn. Àwọn díẹ̀ ni a fagbára yà nípá kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ wọn.
Ní 1972 iye àwọn Ẹlẹ́rìí tí ó ju 30,000 lọ àti àwọn díẹ̀ tí wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú wọn níláti fi orílẹ̀-èdè náà sílẹ̀ nítorí ìbẹ̀rù pípàdánù ìwàláàyè wọn. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún fìdíkalẹ̀ sí àwọn ibùdó olùwá-ibi-ìsádi ní ilẹ̀ Mozambique tí ó múlégbè wọ́n. Ṣùgbọ́n ní 1975 àwọn olùwá-ibi-ìsádi wọ̀nyí ni a rán padà sí Malawi, níbi tí wọ́n ti níláti dojúkọ inúnibíni síwájú síi. Ọ̀pọ̀ nínú wọn ni a fi sí àwọn ibùdó ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́. Ní àárín rúkèrúdò yìí, wọ́n wọ́gilé orúkọ Watch Tower Society lórí àkọsílẹ̀ àwọn orúkọ ètò-àjọ àfàṣẹtìlẹ́yìn tí a tẹ́wọ́gbà lábẹ́ òfin ní Malawi. Láti ìgbà náà wá ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa àti àwọn ètò-àjọ wọn tí a tẹ́wọ́gbà lábẹ́ òfin ti wà lábẹ́ ìfòfindè ní ilẹ̀ yẹn.
Láìka gbogbo ìdàgbàsókè wọ̀nyí sí, àwọn Ẹlẹ́rìí kò ránró. Wọn kò gbé àwùjọ ènìyànkénìyàn dìde tàbí kí wọ́n ṣe rúkèrúdò ìwà-ipá lòdìsí ìjọba. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọn fi tàdúràtàdúrà di ojúṣe Kristian wọn mú láti fi ọlá àti ọ̀wọ̀ yíyẹ hàn fún “àwọn aláṣẹ” ìjọba “tí ó wà ní ipò gíga.” (Romu 13:1-7; 1 Timoteu 2:1, 2) Àwọn Ẹlẹ́rìí náà tún di àwọn ọ̀pá ìdíwọ̀n gíga ti gbígbé gẹ́gẹ́ bí Kristian tí a làsílẹ̀ nínú Bibeli mú, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ fi àpẹẹrẹ ìwà títayọlọ́lá lélẹ̀.
Pẹ̀lú òmìnira tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ rígbà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní Malawi ti pinnu láti máa báa lọ ní wíwàásù àwọn òtítọ́ Bibeli láìsinmi, “ní àkókò tí ó wọ̀.”—2 Timoteu 4:2.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
M. G. Henschel pẹ̀lú ìdílé Beteli ní Malawi ní àwọn ọdún 1960