Àwọn Olólùfẹ́ Rẹ tí Wọ́n Ti Kú Níbo Ni Wọ́n Wà?
NǸKAN dojúrú fún Alec. Láàárín ọ̀sẹ̀ kan, ó pàdánù méjì nínú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ọ̀kan nínú wọn, Nevil, kú nítorí ọgbẹ́ ọta ìbọn. Èyí èkejì, Tony, kú nínú ìjàm̀bá mọ́tò. Àwọn ìbéèrè tí kò yọ ọ́ lẹ́nu rí wá di èyí tí ó dààmú ọmọdékùnrin ẹni ọdún 14 ará South Africa náà. Ó ṣe kàyéfì pé, ‘Èéṣe tí àwọn ènìyàn fi níláti máa kú? Kí ni ó sì ń ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ikú?’
Bí ó ti ń lọ síbi ètò-ìsìnkú Nevil, Alec fi pẹ̀lú òtítọ́-inú nírètí pé òun yóò rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí. Ó rántí pé, “Ṣùgbọ́n àlùfáà náà wulẹ̀ kà láti inú ìwé kan ni ó sì sọ pé Nevil ti lọ sí ọ̀run. Lẹ́yìn náà, lẹ́bàá sàréè, ó sọ pé a ń dúró de àjíǹde. Kò yé mi mọ́. Bí Nevil bá wà ní ọ̀run, báwo ni òun ṣe lè máa dúró de àjíǹde?”
Nígbà tí ó ṣe ní ọjọ́ kan náà yẹn, Alec lọ síbi ètò-ìsìnkú Tony. Ètò ìsìn aláàtò-àṣà náà ni wọ́n ṣe ní èdè kan tí òun kò lóye. Síbẹ̀, wọ́nranwọ̀nran tí àwọn aṣọ̀fọ̀ kan ń ṣe mú kí Alec gbàgbọ́ pé a kò fún wọn ní ìtùnú kankan. Ó ṣàlàyé pé, “Ní alẹ́ ọjọ́ yẹn ọkàn mi gbọgbẹ́ gidigidi. Ó tojúsú mi èmi kò sì mọ ohun tí ǹ bá ṣe. Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè pèsè ìdáhùn tí ń tẹ́nilọ́rùn sí àwọn ìbéèrè mi. Fún ìgbà àkọ́kọ́ nínú ìgbésí-ayé mi, mo ṣe kàyéfì níti gidi bóyá Ọlọrun kan wà.”
Lọ́dọọdún àràádọ́ta-ọ̀kẹ́, bíi ti Alec, ń pàdánù àwọn olólùfẹ́ wọn nínú ikú. Ìwé 1992 Britannica Book of the Year ṣàlàyé pé, “Kárí-ayé, iye ikú tí ó wáyé ní 1991 jẹ́ 50,418,000.” Ẹ sì wo àwọn àràádọ́ta-ọ̀kẹ́ mìíràn síi tí wọ́n ti kú láti ìgbà náà wá? Ronú nípa alagbalúgbú omijé tí àwọn alásẹ̀yìndè náà tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ sun! Ohun tí ó tún fikún ìbànújẹ́ wọn ni ìdàrúdàpọ̀ tí àwọn ojú-ìwòye tí ó forígbárí nípa ikú ń mú wá.
Nípa báyìí, ọ̀pọ̀ ènìyàn gẹ́gẹ́ bíi ti Alec, di ẹni tí a ṣì lọ́nà wọ́n sì ń ṣiyèméjì bí ìdí èyíkéyìí kan bá wà fún ìrètí nínú ìwàláàyè ọjọ́-ọ̀la kan lẹ́yìn ikú. Gẹ́gẹ́ bí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopedia of Religions ti sọ, “nínú gbogbo sànmánì, àwọn ènìyàn onírònújinlẹ̀ ti ya araawọn sọ́tọ̀ kúrò lára ọ̀pọ̀ ènìyàn, . . . ní ṣíṣiyèméjì nípa bí ọkàn tàbí ìwàláàyè ẹnìkan ṣe lè dá wà lọ́tọ̀ kúrò lára ọpọlọ àti ara ẹni náà.”
Ó dùnmọ́ni pé, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ tí a mẹ́nukàn lókè yìí gbà pé àbá èrò-orí ìsìn nípa ọkàn kan tí kò lè kú tí ó wàláàyè lẹ́yìn òde ara kò ní ìtìlẹ́yìn nínú Bibeli. Lóòótọ́, ní àwọn ibi mélòókan, Bibeli tọ́kasí “ọkàn” ẹnìkan gẹ́gẹ́ bí èyí tí ń fi ara tí ó ti kú sílẹ̀ tí ó sì tún ń padà síbẹ̀, ṣùgbọ́n nínú àwọn àpẹẹrẹ ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí “ọkàn” ni a lò ní ìtumọ̀ ti “ìwàláàyè,” tí a pàdánù tàbí tí a jèrè padà. (Genesisi 35:16-19; 1 Awọn Ọba 17:17-23) Lọ́pọ̀ ìgbà jùlọ, ọ̀rọ̀ náà “ọkàn” ní a lò nínú Bibeli láti ṣàpèjúwe àwọn ẹ̀dá tí wọ́n ṣeéfojúrí tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́ran ara àti ẹ̀jẹ̀, bẹ́ẹ̀ni, àwọn ẹ̀dá alààyè. (Genesisi 1:20; 2:7) Nípa báyìí, Bibeli sọ ní àsọtúnsọ pé ọkàn ń kú. (Esekieli 18:4, 20; Iṣe 3:23; Ìfihàn 16:3) Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sọ pé ní gbàrà tí àwọn ọkàn bá ti kú, wọn “kò mọ ohun kan.”—Oniwasu 9:5, 10.
Ní ìdàkejì, Bibeli ní àkọsílẹ̀ nípa àwọn òkú tí a mú padàbọ̀ sí ìyè. Nínú ọ̀ràn ti Lasaru, èyí ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí ó ti kú fún ọjọ́ mẹ́rin. (Johannu 11:39, 43, 44) Ṣùgbọ́n kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn tí wọ́n kú ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún tàbí ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn? Ǹjẹ́ ìfojúsọ́nà wọn fún ìwàláàyè ọjọ́ iwájú béèrè pé kí Ọlọrun ji ara kan náà tí wọ́n ní nígbà tí wọ́n kú dìde bí?
Bẹ́ẹ̀kọ́. Irú èrò bẹ́ẹ̀ kò sí ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ohun tí ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn ohun tín-ín-tìn-ìn-tín tí ó parapọ̀ jẹ́ ara òkú kan. Láìpẹ́ láìjìnnà, díẹ̀ nínú àwọn ohun tín-ín-tìn-ìn-tín wọ̀nyí ni àwọn ewéko yóò fà sínú, èyí tí àwọn ẹ̀dá mìíràn yóò jẹ tí yóò sì di apákan ara wọn.
Èyí ha túmọ̀sí pé kò sí ìrètí kankan fún àwọn ènìyàn tí wọ́n ti kú tipẹ́ bí? Bẹ́ẹ̀kọ́. Ẹlẹ́dàá àgbáyé wa tí ó lọ salalu ní agbára ìrántí gígadabú, aláìláàlà. Nínú agbára ìrántí rẹ̀ pípé, ó ní agbára láti ṣe ìtọ́júpamọ́ àkópọ̀ ànímọ́ àti àwọn ìwà àbímọ́ni ti ẹ̀dá ènìyàn èyíkéyìí tí ó ti kú tí òun yàn láti rántí. Ju bẹ́ẹ̀ lọ, Jehofa Ọlọrun ní agbára náà láti ṣe àtúndá ara ènìyàn pẹ̀lú àkójọ òfin apilẹ̀ àbùdá náà gan-an tí ó jẹ́ ti ẹnìkan tí ó ti wàláàyè rí. Ó tún lè ṣe ìdápadà agbára ìrántí àti àkópọ̀ ànímọ́ ẹni náà tí òun rántí, bí Abrahamu.
Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún lẹ́yìn ikú Abrahamu, Jesu Kristi fúnni ní ìdánilójú yìí: “Níti pé a ń jí àwọn òkú dìde, Mose tìkáraarẹ̀ sì ti fihàn ní ìgbẹ́, nígbà tí ó pe Oluwa ní Ọlọrun Abrahamu, àti Ọlọrun Isaaki, àti Ọlọrun Jakọbu. Bẹ́ẹ̀ni òun kìí ṣe Ọlọrun àwọn òkú bíkòṣe ti àwọn alààyè: nítorí gbogbo wọn wàláàyè fún un.” (Luku 20:37, 38) Yàtọ̀ sí Abrahamu, Isaaki, àti Jakọbu, àràádọ́ta-ọ̀kẹ́ àwọn ẹ̀dá ènìyàn mìíràn tí wọ́n ti kú wàláàyè nínú agbára ìrántí Ọlọrun, tí wọ́n ń dúró de àjíǹde tí ń bọ̀wá náà. Bibeli mú kí ó dánilójú pé, “Àjíǹde òkú ń bọ̀, àti ti olóòótọ́, àti ti aláìṣòótọ́.”—Iṣe 24:15.
Ní ọ̀sẹ̀ díẹ̀ lẹ́yìn tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ ẹ́, Alec rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè rẹ̀. Ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ṣe ìbẹ̀wò sí ilé rẹ̀ ó sì fi ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sọ nípa ikú àti nípa àjíǹde hàn án. Èyí tu Alec nínú ó sì mú kí ìgbésí-ayé rẹ̀ ní ìtumọ̀ titun.
Ìwọ pẹ̀lú yóò ha fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ púpọ̀ síi nípa ìrètí àjíǹde tí a gbékarí Bibeli bí? Fún àpẹẹrẹ, àjíǹde tí ó pọ̀ jùlọ yóò ha wáyé ní ọ̀run tàbí lórí ilẹ̀-ayé bí? Kí sì ni ẹnìkan gbọ́dọ̀ ṣe láti jèrè ìtẹ́wọ́gbà Ọlọrun kí ó sì nírìírí ìmúṣẹ ìlérí àgbàyanu Rẹ̀ pé àwọn ènìyàn ni a lè tún sopọ̀ṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn olólùfẹ́ tí wọ́n ti kú?