Abrahamu—A Sin Ín Síhìn-ín, Síbẹ̀ Ó Wàláàyè Kẹ̀?
Fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún, àwọn Ju, Mùsùlùmí, àti àwọn Kristian ti rìnrìn-àjò lọ sí ibí yìí.
Ìwọ lè ṣèbẹ̀wò síbẹ̀ ní ìlú-ǹlá Hebroni ìgbàanì, ní gúúsù Jerusalemu. Ilé-lílò yìí ni a ń pè ní Haram el-Khalil àti Ibojì Àwọn Babańlá. Bẹ́ẹ̀ni, Èyí ni a gbà ní ibi púpọ̀ pé ó jẹ́ ibi ìsìnkú àwọn babańlá náà Abrahamu, Isaaki, àti Jakọbu, àti ìyàwó ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn Sara, Rebeka, àti Lea pẹ̀lú.
Rántí láti inú Bibeli pé nígbà tí Sara aya rẹ̀ àyànfẹ́ kú, Abrahamu ra ihò kan àti ilẹ̀ díẹ̀ ní Makpela nítòsí Hebroni gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìsìnkú. (Genesisi 23:2-20) Lẹ́yìn náà, Abrahamu pẹ̀lú ni a sin síhìn-ín, gẹ́gẹ́ bíi ti àwọn mẹ́ḿbà ìdílé yòókù. Ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn náà, Herodu Ńlá kọ ilé ràgàjì kan yíká ilẹ̀ ìsìnkú àtọwọ́dọ́wọ́ náà, èyí tí àwọn aṣẹ́gun yí ìgbékalẹ̀ rẹ̀ padà tí wọ́n sì mú tóbi síi, lọ́nà tí ń gbé àwọn ìgbàgbọ́ ìsìn tiwọn yọ.
Bí o bá ti ń wọlé, ìwọ yóò rí àwọn cenotaph (ohun-ìrántí tàbí ibojì tí ó ṣófo) mẹ́fà. Àwòrán inú àkámọ́ náà fí èyí tí ó jẹ́ ti Isaaki, ọmọkùnrin Abrahamu hàn. Àwọn ihò abẹ́ ilẹ̀ tí a ti lò láti rí ọ̀nà gbà dé ibi àwọn nǹkan tí ó wà nísàlẹ̀ wà nítòsí rẹ̀. Àwọn olùṣèwádìí ti rí àwọn iyàrá níbi tí ó ti ṣeéṣe kí a sin ọ̀pọ̀ àwọn egungun òkú ìgbàanì sí.
Abrahamu ńkọ́? Bí a bá sin-ín sínú ihò kan tí ń bẹ nísàlẹ̀ ilẹ̀ ìsìnkú yìí, a jẹ́ pé ó ti kú tipẹ́tipẹ́, àbí? Ọ̀pọ̀ àwọn olùṣèbẹ̀wò yóò gbà bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀ wòlíì kan tí ó tóbi ju Abrahamu lọ sọ pé ní èrò ìtumọ̀ kan Abrahamu ṣì wàláàyè. Báwo? Kí ni èyí sì níí ṣe pẹ̀lú ìgbàgbọ́ rẹ?
Jọ̀wọ́ ka ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ náà “Àwọn Olólùfẹ́ Rẹ tí Wọ́n Ti Kú—Níbo Ni Wọ́n Wà?” (Ojú-ìwé 3) Ó gbé ohun tí wòlíì ńlá náà sọ nípa wíwà tí Abrahamu wàláàyè jáde, ìsọfúnni tí ó lè níyelórí lọ́pọ̀lọpọ̀ fún ìwọ àti ìdílé rẹ.