ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 7/15 ojú ìwé 25
  • Ikú Ni Àbájáde tí Àwọn Ayẹyẹ Ọjọ́-Ìbí Ti Fi Sílẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ikú Ni Àbájáde tí Àwọn Ayẹyẹ Ọjọ́-Ìbí Ti Fi Sílẹ̀
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 7/15 ojú ìwé 25

Ikú Ni Àbájáde tí Àwọn Ayẹyẹ Ọjọ́-Ìbí Ti Fi Sílẹ̀

AYẸYẸ àwọn ọjọ́-ìbí ni ọ̀pọ̀ ènìyàn lónìí ti kà sí àṣà ṣákálá tí kò léwu. Ṣùgbọ́n Bibeli kò fi àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ yìí hàn bí èyí tí ó ṣètẹ́wọ́gbà. Fún ohun kan, Ìwé Mímọ́ kò fi ẹ̀rí kankan hàn pé èyíkéyìí nínú àwọn olùṣòtítọ́ ìránṣẹ́ Ọlọrun ṣe ayẹyẹ ọjọ́-ìbí.

Àwọn ọjọ́-ìbí méjì péré tí Bibeli mẹ́nubà jẹ́ tí àwọn alákòóso tí wọ́n jẹ́ ọ̀tá Ọlọrun. Ayẹyẹ kọ̀ọ̀kan ní ìpànìyàn nínu, débi pé àwọn àlejò yóò lè máa ronú lórí ikú ẹni tí ó ti ba ọba nínú jẹ́. Nínú àpẹẹrẹ àkọ́kọ́, Farao, ọba Egipti, pa olórí alásè rẹ̀. (Genesisi 40:​2, 3, 20, 22) Alákòóso Egipti náà ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà àsè náà nítorí pé inú ti bíi sí ìránṣẹ́ rẹ̀. Nínú àpẹẹrẹ kejì, Herodu, oníwà pálapàla alákòóso Galili, bẹ́ orí Johannu Arinibọmi gẹ́gẹ́ bí ojúrere sí ọmọbìnrin kan tí ijó rẹ̀ níbi àsè náà wù ú. Wo irú ìran akóninírìíra tí ó jẹ́!​—⁠Matteu 14:​6-⁠11.

Síbẹ̀ ǹjẹ́ Bibeli kò ha ti kórí àfiyèsí jọ sí àwọn ọjọ́-ìbí méjì tí ó dáyàtọ̀ gan-⁠an bí? Kò rí bẹ́ẹ̀. Òpìtàn Ju àtijọ́ náà Josephus fihàn pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí kìí ṣe àrà-ọ̀tọ̀. Ó kọ àkọsílẹ̀ àwọn àpẹẹrẹ ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn ti àṣà ìpànìyàn fún ìdárayá nígbà ọjọ́-ìbí.

Fún àpẹẹrẹ, àwọn kan ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìparun Jerusalemu ní 70 C.E., nígbà tí 1,000,000 àwọn Ju ṣègbé tí a sì kó 97,000 tí ó làájá lẹ́rú. Ní ọ̀nà Romu, ọ̀gágun Titus ti Romu kó àwọn Ju ẹrú rẹ̀ lọ sí etíkun Kesarea tí ó wà nítòsí.

Josephus kọ̀wé pé: “Nígbà tí Titus dúró sí Kesarea, ó ṣayẹyẹ ọjọ́-ìbí Domitian arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú ògo-ẹwà tí ó kàmàmà, tí ó sì ṣekúpa iye tí ó ju 2,500 ẹlẹ́wọ̀n lọ nínú eré pẹ̀lú àwọn ẹranko ẹhànnà àti iná. Lẹ́yìn èyí ó lọ sí Berytus [Beirut], ìlú tí Romu ń gbókèèrè ṣàkóso ní Phoenicia, níbi tí ó ti ṣayẹyẹ ọjọ́-ìbí baba rẹ̀ nípa pípa púpọ̀ síi nínú àwọn tí ó múlẹ́rú níbi ìṣàfihàn gígọntiọ.”​—⁠Ìwé The Jewish War, VII, 37, tí a túmọ̀ láti ọwọ́ Paul L. Maier nínú ìwé Josephus: The Essential Writings.

Kò yanilẹ́nu pé ìwé atúmọ̀ ọ̀rọ̀ náà The Imperial Bible-Dictionary ṣàlàyé pé: “Àwọn Heberu tí ó kẹ́yìn wo ayẹyẹ àwọn ọjọ́-ìbí gẹ́gẹ́ bí apákan ìjọsìn ìbọ̀rìṣà, kan tí a fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gan-⁠an nípasẹ̀ àwọn ohun tí wọ́n rí níbi àwọn ààtò tí ó wọ́pọ̀ tí ó sopọ̀ mọ́ àwọn ọjọ́ wọ̀nyí.”

Àwọn Kristian olùṣòtítọ́ ti ọ̀rúndún kìn-⁠ín-ní kì yóò ti nífẹ̀ẹ́ sí lílọ́wọ́ nínú àṣà tí Bibeli fihàn lọ́nà òdì tó báyìí tí àwọn ará Romu sì ń ṣayẹyẹ rẹ̀ lọ́nà tí ó dáyàfoni. Lónìí, àwọn Kristian olóòótọ́ ríi pé àwọn àkọsílẹ̀ Bibeli nípa àwọn ọjọ́-ìbí wà lára àwọn ohun tí a kọ tẹ́lẹ̀ fún kíkọ́ wọn. (Romu 15:⁠4) Wọ́n yẹra fún ṣíṣe ayẹyẹ àwọn ọjọ́-ìbí nítorí àwọn ààtò bẹ́ẹ̀ ń fi ìjẹ́pàtàkì tí kò yẹ fún onítọ̀hún. Èyí tí ó tún ṣe pàtàkì, àwọn ìránṣẹ́ Jehofa ń fọgbọ́n ronú dáradára lórí bí Bibeli ṣe fi àwọn ọjọ́-ìbí hàn lọ́nà òdì.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Gbọ̀ngàn eré ìdárayá Kesarea

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́