Òmìnira Kúrò Lọ́wọ́ Ìbẹ̀rù Kù Sí Dẹ̀dẹ̀!
BÍ Ó tilẹ̀ jẹ́ pé ènìyàn ń gbé nínú ìbẹ̀rù láti ìgbà ìbí títí lọ dé sàréè, a lè fi pẹ̀lú ìgbọ́kànlé wọ̀nà fún àkókò kan ní ọjọ́ iwájú tí kò jìnnà mọ́ nígbà tí Ìjọba Ọlọrun nípasẹ̀ Kristi Jesu yóò mú gbogbo ìjìyà kúrò títíláé—títíkan ikú àti àìsàn. Ìwé ìròyìn yìí ti fi ohun tí a béèrè fún hàn láti lè jàǹfààní láti inú àwọn ìpèsè onífẹ̀ẹ́ ti Ọlọrun. Bí ìwọ yóò bá gba ìsọfúnni síwájú síi tàbí bí ìwọ yóò bá fẹ́ kí ẹnìkan kàn sí ọ láti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́ pẹ̀lú rẹ, jọ̀wọ́ kọ̀wé sí Watch Tower, P.M.B. 1090, Benin City, Edo State, tàbí sí àdírẹ́sì tí ó ṣe wẹ́kú tí a tò sí ojú-ìwé 2.