Ìwọ Ha Rántí Bí?
O ha ti ha ronú jinlẹ̀ lórí àwọn ìtẹ̀jáde Ilé-Ìṣọ́nà ti àìpẹ́ yìí bí? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, yóò rọrùn fún ọ láti rántí àwọn ohun tí ó tẹ̀lé e yìí:
▫ Ìyàtọ̀ pàtàkì wo ni ó wà láàárín ènìyàn àti àwọn ẹranko?
Ìyàtọ̀ pàtàkì sinmi lórí ìgbékalẹ̀, agbára, àti ìṣiṣẹ́ ọpọlọ. Nínú àwọn ẹranko, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ìṣiṣẹ́ ọpọlọ wọn ni a ti ṣètò rẹ̀ silẹ̀ nínú ohun tí a wá ń pè ní ọgbọ́n àdánidá. Èyí kò rí bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀dá ènìyàn. Ọlọrun fi òmìnira ìfẹ́-inú jíǹkí ènìyàn. (Owe 30:24-28)—w-YR 4/15, ojú-ìwé 5.
▫ Ipa wo ní orin kíkọ kó nínú ìjọsìn àwọn ọmọ Israeli nínú tẹ́ḿpìlì?
Orin, ní pàtàkì àwọn akọrin, wà ní ipò pàtàkì nínú ìjọsìn, kò fi dandan jẹ́ láti gbin awọn ọ̀ràn Òfin tí ó wúwo jù sínilọ́kàn, bíkòṣe láti fúnni ní ẹ̀mí tí ó yẹ fún ìjọsìn. Ó ran awọn ọmọ Israeli lọ́wọ́ láti fi ẹ̀mí ìtara jọ́sìn Jehofa. (1 Kronika 23:4, 5; 25:7)—w-YR 5/1, ojú-ìwé 10, 11.
▫ Irú àfiyèsí wo ni àwọn ọmọ nílò láti ìgbà ọmọdé jòjòló?
Àwọn òbí níláti fun àwọn ọmọ àṣẹ̀ṣẹ̀bí wọn ní èyí tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ àfiyèsí ìgbà gbogbo. Paulu kọ̀wé pé: “Láti ìgbà ọmọdé jòjòló ni ìwọ ti mọ ìwé mímọ́, èyí tí ó lè sọ ọ́ di ọlọgbọ́n fún ìgbàlà.” (2 Timoteu 3:15, NW) Nítorí náà àfiyèsí àwọn òbí tí Timoteu rígbà, àní láti ìgbà ọmọdé jòjòló pàápàá, jẹ́ tẹ̀mí pẹ̀lú.—w-YR 5/15, ojú-ìwé 11.
▫ Kí ni àwọn àmì mẹ́rin tí ó jẹ́rìí síi pé Bibeli ní ìhìn-iṣẹ́ Ọlọrun fún aráyé nínú?
(1) Ìwàlárọ̀ọ́wọ́tó. Bibeli wà lárọ̀ọ́wọ́tó fun nǹkan bí ìpín 98 nínú ọgọ́rùn-ún olùgbé ayé. (2) Ìjótìítọ́ Ọ̀rọ̀-Ìtàn. Bibeli ní àwọn òtítọ́ inú ọ̀rọ̀-ìtàn nínú, kìí ṣe àwọn ìtàn àròsọ tí kò ṣeé fi ẹ̀rí tì lẹ́yìn. (3) Ìgbéṣẹ́. Awọn àṣẹ àti ìlànà rẹ̀ lànà ìgbésí-ayé kan silẹ̀ tí ó ń mú àǹfààní wá fún àwọn wọnnì tí wọ́n bá dìrọ̀ mọ́ wọn. (4) Àsọtẹ́lẹ̀. Ó jẹ́ ìwé kan tí ó sọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́-ọ̀la lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́.—w-YR 6/1, ojú-ìwé 8, 9.
▫ Ẹrù-Iṣẹ́ wo ni ó ń bá mímọ ìsìn tí ó tọ̀nà rìn?
Gbàrà tí a bá ti dá ìsìn tí ó tọ̀nà mọ̀ yàtọ̀, a gbọ́dọ̀ kọ́ ìgbésí-ayé wa yí i ká. Ó jẹ́ ọ̀nà ìgbésí-ayé kan. (Orin Dafidi 119:105; Isaiah 2:3)—w-YR 6/1, ojú-ìwé 13.
▫ Èéṣe tí ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bibeli fi ṣe pàtàkì gan-an?
Àìní wà fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun láti sọ ayọ̀ àti okun wọn dọ̀tun láti ọjọ́ dé ọjọ́ nípa wíwá àwọn apá-ìhà titun tàbí apá-ìhà tí ó túbọ̀ jinlẹ̀ nínú òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Ní ọ̀nà yìí wọ́n ń báa nìṣó ní ríru ara wọn sókè nípa tẹ̀mí.—w-YR 6/15, ojú-ìwé 8.
▫ Kí ni ọ̀rọ̀ naa “ẹ̀ṣẹ̀” túmọ̀sí gẹ́gẹ́ bí a ṣe lò ó nínú Bibeli?
Nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀-ìṣe, àwọn ọ̀rọ̀ Heberu àti Griki naa tí a sábà máa ń lò fún “ẹ̀ṣẹ̀” nínú Bibeli túmọ̀sí “kùnà,” ní èrò ìtumọ̀ ti kíkùnà tàbí ṣíṣàì lé góńgó, àmì, tàbí ohun àfojúsùn kan bá. Tọkọtaya ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́ kùnà ògo Ọlọrun, ní kíkùnà ète tí a torí rẹ̀ dá wọn ní àwòrán Ọlọrun. Ní èdè mìíràn, wọ́n dẹ́ṣẹ̀. (Genesisi 2:17; 3:6)—w-YR 6/15, ojú-ìwé 12.
▫ Èéṣe tí kò fi bọ́gbọ́nmu pàápàá láti ka ìwé àwọn apẹ̀yìndà?
Díẹ̀ lára ìwé àwọn apẹ̀yìndà ń gbé èké kalẹ̀ nípasẹ̀ “ọ̀rọ̀ dídùn-dídùn” àti “ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.” (Romu 16:17, 18; 2 Peteru 2:3) Gbogbo ìwé àwọn apẹ̀yìndà wulẹ̀ máa ń ṣòfíntótó tí ó sì ń banijẹ́. Kò sí ohun kan tí ń gbéniró níbẹ̀.—w-YR 7/1, ojú-ìwé 12.
▫ Greece ha ni ibi tí ìjọba dẹmọ ti bẹ̀rẹ̀ bí?
Ní Greece ìjímìjí, kìkì àwọn ìpínlẹ̀ adájọbaṣe díẹ̀ ní wọ́n lo ìjọba dẹmọ, àní nínú àwọn wọ̀nyí kìkì àwọn ọkùnrin ni wọ́n ń dìbò. Èyí fihàn pé ìdámẹ́rin nínú márùn-ún àwọn olùgbé ibẹ̀ ni kò kópa. Agbára káká ni ìyẹn fi jẹ́ ìṣàkóso ọwọ́-ènìyàn-ni-ọlá-àṣẹ-wà tàbí dẹmọ!—w-YR 7/1, ojú-ìwé 16.
▫ Kí ní ń mú kí ìgbéyàwó Kristian kẹ́sẹjárí?
Nígbà tí ọkọ àti aya bá bọ̀wọ̀ fún ojú-ìwòye Ọlọrun nípa ìgbéyàwó tí wọ́n sí sakun láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú Ọ̀rọ̀ rẹ̀. (Efesu 5:21-33)—w-YR 7/15, ojú-ìwé 10.
▫ Báwo ni ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé rẹ ṣe lè jẹ́ èyí tí ó gbádùn mọ́ni?
Gbìyànjú láti jẹ́ kí gbogbo àwọn ọmọ kópa. Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ ṣe kedere kí ó sì gbéniró, ní fífi pẹ̀lú ìmọrírì gbóríyìn fún àwọn ọmọ rẹ fún ìkópa wọn. Máṣe wulẹ̀ kárí àkójọpọ̀-ọ̀rọ̀ ṣùgbọ́n gbìyànjú láti dé inú ọkàn-àyà àwọn ọmọ rẹ.—w-YR 7/15, ojú-ìwé 18.
▫ Kí ni ohun tí gbólóhùn ọ̀rọ̀ naa: “Nígbà tí wọ́n bá ń wí pé, àlàáfíà àti àìléwu” túmọ̀sí? (1 Tessalonika 5:3)
Kíyèsi pé Bibeli kò sọ pé “àlàáfíà àti àìléwu” yóò tó àwọn orílẹ̀-èdè lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n bí ó ti wù kí ó rí wọn yóò máa sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ lọ́nà ṣíṣàrà-ọ̀tọ̀, ní fífi ẹ̀mí nǹkan yóò dára àti ìdánilójú tí a kò tíì nírìírí rẹ̀ títí dí báyìí hàn. Ṣíṣeéṣe tí ó wà pé kí ọwọ́ tẹ àlàáfíà àti àìléwu súnmọ́lé ju ti ìgbàkígbà rí lọ.—w-YR 8/1, ojú-ìwé 6.
▫ Dárúkọ àwọn ọ̀nà mẹ́ta tí Jehofa gbà fi ìfòyebánilò hàn.
Jehofa ti fihàn pé òun jẹ́ ẹni tí ó ṣetán láti dáríjì. (Orin Dafidi 86:5) Ó máa ń fi ìmúratán hàn láti yí àwọn ìgbésẹ̀ rẹ̀ padà bí àwọn àyíká-ipò titun ti ń dìde. (Wo Jona, orí 3.) Bákan náà, Jehofa ti fihàn pé òun ń fòyebánilò nínú ọnà tí ó ń gbà lo ọlá-àsẹ. (1 Awọn Ọba 22:19-22)—w-YR 8/1, ojú-ìwé 12-14.