“Tìyanu-tìyanu ni a dá mi”
“NÍBO ni mo ti wá?” Èyí jẹ́ ìbéèrè kan tí ọ̀pọ̀ jùlọ awọn ọ̀dọ́mọdé ń béèrè lati ìgbà dé ìgbà. Nígbà tí awọn ọmọ naa bá dàgbà, ìbéèrè wọn sábà máa ń jinlẹ̀ síi: “Níbo ni ìwàláàyè ti ṣẹ̀ wá?” Ìbéèrè yii ni a ti jíròrò fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún, ọ̀pọ̀ awọn onímọ̀-ìjìnlẹ̀ sì ń wo ẹfolúṣọ̀n ní lọ́wọ́lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí ìdáhùn tí ó lọ́gbọ́n ninu jùlọ sí àdìtú naa nipa ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìwàláàyè. Ní pàtàkì, àlàyé awọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n ni pé ìwàláàyè wáyé lọ́nà èèṣì.
Ní nǹkan bíi 3,000 ọdún sẹ́yìn, Ọba Dafidi kọ̀wé pé: “Tẹ̀rù-tẹ̀rù ati tìyanu-tìyanu ni a dá mi.” (Orin Dafidi 139:14) Bí a ti túbọ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ síi nipa ìwàláàyè, bẹ́ẹ̀ ni a túbọ̀ ń rí òtítọ́ tí ń bẹ ninu awọn ọ̀rọ̀ wọnnì tó. Níti tòótọ́, onímọ̀-ìjìnlẹ̀ physics náà Fred Hoyle kọ̀wé pé: “Bí awọn onímọ̀ nipa ìṣesí-àwọn-ohun-abẹ̀mí ṣe ń ṣàwárí lọ́pọ̀lọpọ̀ síi nípa bí ìwàláàyè ti díjú lọ́nà tí ń múni kún fún ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ tó, ó ṣe kedere pé awọn ṣíṣeéṣe naa pé kí ó ti pilẹ̀ṣẹ̀ lọ́nà èèṣì kéré jọjọ débi pé a lè gbójúfò wọn dá pátápátá. Kò níláti jẹ́ pé ìwàláàyè ti wáyé lọ́nà èèṣì.”
Nitori naa kí ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìwàláàyè? Awọn ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ méjì tí ó ṣáájú ninu ìwé ìròyìn yìí jíròrò ìbéèrè yẹn. Bí iwọ yoo bá fẹ́ lati gba ìsọfúnni síwájú síi, jọ̀wọ́ kọ̀wé sí Watch Tower, P.M.B. 1090, Benin City, Edo State, tabi sí àdírẹ́sì tí ó ṣe wẹ́kú tí a tò sí ojú-ìwé 2.