‘Ẹ Máṣe Kárísọ Gẹ́gẹ́ Bí Àwọn Yòókù Ti Ń Ṣe’
ÌWỌ ha ti fìgbàkan ṣàkíyèsí bí òdòdó kan ṣe ń dàbí ẹni pé ó rọ pọ́jọ́ lẹ́yìn tí ó bá la ìjì líle kan ja bí? Ìran kan tí ń múni káàánú lọ́nà kan ṣá ni ó jẹ́. Ó ṣetán, ó ti ṣeé ṣe kí òjò àrọ̀ọ̀rọ̀dá náà ti lé àìníye àwọn ẹranko àti ènìyàn—àwọn ẹ̀dá tí wọ́n lókun ju òdòdó èyíkéyìí lọ—láti máa sá dìgbàdìgbà ní wíwá ibì kan láti forí pamọ́ sí. Síbẹ̀, òdòdó náà dúró síbẹ̀, ó fìdímúlẹ̀ gbọn-in-gbọn-in, ní dídojúkọ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìrunú ojú-ọjọ́ náà. Ní báyìí, ó ṣì dúró síbẹ̀, ó rọ pọ́jọ́ ṣùgbọ́n kò ṣẹ́, ó ń fi okun tí ń bẹ lábẹ́ ìrísí ẹlẹgẹ́ tí ó ní hàn. O lè ṣe kàyéfì, bí o ṣe fẹ́ràn rẹ̀ tó, bóyá ó lè jèrè agbára rẹ̀ padà kí ó sì na orí rẹ̀ rèterète sójú ọ̀run lẹ́ẹ̀kan síi.
Bí ó ṣe rí gẹ́lẹ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn nìyẹn. Ní àwọn àkókò onídààmú yìí, a ń dojúkọ gbogbo onírúurú ìjì líle. Ọrọ̀-ajé tí kò fararọ, ìsoríkọ́, ìlera tí ń jórẹ̀yìn, ìpàdánù olólùfẹ́ ẹni nínú ikú—irú àjàyíká ìjì bẹ́ẹ̀ ń fẹ́ lu gbogbo wa nígbà kan tàbí òmíràn, ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo ìgbà ni a lè yẹra fún wọn gẹ́gẹ́ bí òdòdó kan kò ti lè fa ara rẹ̀ tu kí ó sì wá ibìkan forí pamọ́ sí. Ó ń runi lọ́kàn sókè láti rí àwọn kọ̀ọ̀kan tí ó jọbí ẹni pé wọ́n rí kùrẹ̀jẹ̀ wẹ̀ǹpẹ̀ tí wọ́n ń fi okun yíyanilẹ́nu hàn tí wọ́n sì ń farada irú ìkọlù bẹ́ẹ̀. Ọgbọ́n wo ni wọ́n ń rí dá sí i? Lọ́pọ̀ ìgbà ìgbàgbọ́ ni kọ́kọ́rọ́ náà. Iyèkan Jesu Kristi, Jakọbu, kọ̀wé pé: “Ṣé ẹ mọ̀ pé nígbà tí ìgbàgbọ́ yín bá kẹ́sẹjárí dídojúkọ irúfẹ́ àdánwò bẹ́ẹ̀, agbára láti faradà á ni ìyọrísí rẹ̀.”—Jakọbu 1:3, Today’s English Version.
Ìrètí ni kọ́kọ́rọ́ mìíràn. Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí ikú bá mú olólùfẹ́ ẹni lọ, ìrètí lè mú ìyàtọ̀ gígadabú wá nínú ayé àwọn alásẹ̀yìndè. Aposteli Paulu kọ̀wé sí àwọn Kristian ní Tessalonika pé: “Awa kò fẹ́ kí ẹ ṣe aláìmọ̀ nipa awọn wọnnì tí wọ́n ń sùn ninu ikú; kí ẹ má baà kárísọ gan-an gẹ́gẹ́ bí awọn yòókù tí kò ní ìrètí ti ń ṣe pẹlu.” (1 Tessalonika 4:13, NW) Bí ó tilẹ̀ dájú pé àwọn Kristian ń kẹ́dùn nítorí ikú, ìyàtọ̀ wà. Wọ́n ní ìmọ̀ pípéye nípa ipò tí àwọn òkú wà àti ìrètí àjíǹde.—Johannu 5:28, 29; Iṣe 24:15.
Ìmọ̀ yìí ń fún wọn ní ìrètí. Ní ìyọrísí, ìrètí yẹn ń dín ẹ̀dùn-ọkàn wọn kù ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀. Ó ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lo ìfaradà, àti ní àwọn ọ̀nà mìíràn. Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, bí òdòdó kan lẹ́yìn ìji-líle, wọ́n lè gbé orí wọn sókè kúrò nínú ẹ̀dùn-ọkàn kí wọ́n sì tún padà rí ìdùnnú àti àṣeyọrí nínú ìgbésí-ayé.