Ìbèèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ní Matteu 3:7, èéṣe tí Bibeli “New World Translation” fi lo ọ̀rọ̀ gígùn náà “tajúkán rí” dípò kí ó lo “rí” bí ó ṣe wà nínú ọ̀pọ̀ àwọn ìtumọ̀ Bibeli mìíràn?
Níti gàsíkíá, èyíkéyìí nínú ìtumọ̀ náà ni a lè lò tí kì yóò sì ṣàìtọ̀nà. Kìí sìí ṣe gbogbo èdè ni ó lè fi ìrọ̀rùn sọ adùn tí ó wà nínú èdè Griki ìpilẹ̀ṣẹ̀ jáde nínú irú ọ̀ràn yìí. Ṣùgbọ́n bí Bibeli New World Translation of the Holy Scriptures ní èdè Gẹ̀ẹ́sì ṣe sọ ọ̀rọ̀ inú Matteu 3:7 gbé adùn tí ó wà nínú ọ̀rọ̀ èdè Griki náà yọ. A kà pé: “Nígbà tí [Johannu Oníbatisí] tajúkán rí ọ̀pọ̀ lára awọn Farisi ati Sadusi tí ń wá sí ìbatisí, ó wí fún wọn pé: ‘Ẹ̀yin àmújáde-ọmọ paramọ́lẹ̀, ta ni fi tó yín létí lati sá kúrò ninu ìrunú tí ń bọ̀?’”
Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ, ọ̀pọ̀ Bibeli wulẹ̀ sọ pé Johannu “rí” awọn Farisi ati Sadusi tí wọ́n ń jáde wá sí ibi tí ó ti ń batisí àwọn Ju. Bí ó ti wù kí ó rí, Bibeli ha ní in lọ́kàn pé Johannu rí i tí èyí ń ṣẹlẹ̀ fún ìwọ̀n àkókò kan bí, bí ẹni pé ó ń wò ó fún àkókò kan tí a sì wá sún un lẹ́yìn náà láti sọ̀rọ̀ lórí àgàbàgebè ipa-ọ̀nà wọn? Ìtumọ̀ náà “rí” lè ṣamọ̀nà sí irú òye yẹn. Ní tòótọ́, èrò ìtumọ̀ yẹn ni a fihàn gbangba nínú ìtumọ̀ tí Ferrar Fenton ṣe, èyí tí ó sọ pé: “Ṣugbọn ní ṣíṣàkíyèsí ọ̀pọ̀ lára awọn Farisi náà . . .”
Iṣẹ́ tí atọ́ka ọ̀rọ̀-ìṣe èdè Griki náà ń ṣe ni a ń pè ní ti ìlò ọ̀rọ̀-ìṣe tí kò ní òpin pàtó. Ìlò ọ̀rọ̀-ìṣe tí kò ní òpin pàtó ń sọ̀rọ̀ nipa ìgbésẹ̀ onígbà kúkúrú, nígbà tí atọ́ka ọ̀rọ̀-ìṣe ti ohun tí a ń ṣe lọ́wọ́ ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbésẹ̀ tí ó ń bá a nìṣó (láti máa ṣe) tí atọ́ka ọ̀rọ̀-ìṣe àṣetán sì jẹ́ ìgbésẹ̀ kan tí ó ti parí (tí a ti ṣe). Nítorí náà ohun tí ọ̀rọ̀-ìṣe tí kò ní òpin pàtó ti inú Matteu 3:7 ń tọ́ka rẹ̀ ni pé Johannu Oníbatisí ní àkókò kan rí àwọn Farisi àti àwọn Sadusi tí wọ́n ń bọ̀, tàbí “tajúkán rí” wọn. Ní kété tí ó ti ṣe bẹ́ẹ̀, ó dáhùnpadà, gẹ́gẹ́ bí a ti kà á ní ẹsẹ̀ 7 sí 12.
Ọ̀pọ̀ àwọn àpẹẹrẹ ni ó wà nínú èyí tí a ti lo atọ́ka ọ̀rọ̀-ìṣe tí kò ní òpin pàtó pẹ̀lú èrò ìtumọ̀ yìí. Mímọ̀ tí a bá mọ adùn rẹ̀ lè ṣamọ̀nà wa sí jíjèrè ìmọ̀lára tí ó túbọ̀ dọ́ṣọ̀ sí i fún ohun tí Bibeli ń sọ.
Fún àpẹẹrẹ, Matteu 9:9 (NW) sọ pé: “Bí ó ti ń kọjá lọ lati ibẹ̀, Jesu tajúkán rí ọkùnrin kan tí à ń pè ní Matteu tí ó jókòó ní ọ́fíìsì owó-orí, ó sì wí fún un pé: ‘Di ọmọlẹ́yìn mi.’ Lójú ẹsẹ̀ ó dìde ó sì tẹ̀lé e.” Jesu kò níláti lo àkókò gígùn ní ṣíṣàkíyèsí Matteu, bẹ́ẹ̀ sì ni kò níláti ṣàkíyèsí Matteu léraléra. Jesu tajúkán rí Matteu, Ó sì gbégbèésẹ̀.
Awọn àpẹẹrẹ méjì nìyẹn níti ìṣọ́ra tí Bibeli New World Translation lò ní ìsopọ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀-ìṣe Griki atọ́ka àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ tí kò ní òpin pàtó. Gbé àwọn ibi jíjọra tí ó ti farahàn yẹ̀wò, kí o sì kíyèsí awọn adùn mìíràn tí ìwọ yoo rí:
“Wàyí o, nígbà tí ó dé ilé olùṣàkóso naa tí ó sì tajúkán rí awọn afunfèrè ati ogunlọ́gọ̀ ninu ìdàrúdàpọ̀ aláriwo, Jesu bẹ̀rẹ̀ sí í wí pé: ‘Ẹ kúrò níbẹ̀, nitori ọmọdébìnrin kékeré naa kò kú, ṣugbọn ó ń sùn ni.’”—Matteu 9:23, 24, NW.
“Nígbà tí wọ́n tajúkán rí i tí ó ń rìn lórí òkun, awọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ dààmú, wọ́n wí pé: ‘Ìran-abàmì kan ni!’ Wọ́n sì ké jáde ninu ìbẹ̀rù wọn. Ṣugbọn ní kíámásá Jesu sọ̀rọ̀ sí wọn pẹlu awọn ọ̀rọ̀ wọnyi: ‘Ẹ mọ́kànle, emi ni.’”—Matteu 14:26, 27, NW.
“Wàyí o ọ̀kan lára awọn onípò-àṣẹ alága sinagọgu, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jairu, wá, nígbà tí ó sì tajúkán rí [Jesu], ó wólẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀ ó sì pàrọwà fún un ní ọ̀pọ̀ ìgbà, wí pé: ‘Ọmọbìnrin mi kékeré wà ní ipò tí ó légbákan. Iwọ yoo ha jọ̀wọ́ wá kí o sì gbé ọwọ́ lé e.’”—Marku 5:22, 23, NW.
“Bí ó ti súnmọ́ ibodè ìlú-ńlá naa [ti Naini], họ́wù, wò ó! wọ́n ń gbé ọkùnrin kan tí ó ti kú jáde, ọmọkùnrin bíbí kanṣoṣo ìyá rẹ̀. Yàtọ̀ sí èyí, opó ni oun. Ogunlọ́gọ̀ tí ó tóbi pupọ lati ìlú-ńlá naa tún wà pẹlu rẹ̀. Nígbà tí Oluwa sì tajúkán rí i, àánú rẹ̀ ṣe é, ó sì wí fún un pé: ‘Dẹ́kun sísunkún.’”—Luku 7:12, 13, NW.
“Nitori naa, nígbà tí Maria dé ibi tí Jesu wà tí ó sì tajúkán rí [Jesu], ó wólẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀, ó wí fún un pé: ‘Oluwa, kání o ti wà níhìn-ín ni, arákùnrin mi kì bá tí kú.’ Nitori naa, Jesu, nígbà tí ó rí i tí ó ń sunkún ati awọn Júù tí wọ́n bá a wá tí wọ́n ń sunkún, ó kérora ninu ẹ̀mí ó sì dààmú.”—Johannu 11:32, 33, NW.
Bí ìwọ yóò bá fẹ́ láti ka àwọn àpẹẹrẹ mìíràn sí i, wo Iṣe 7:23-25; 9:39, 40; 21:32; 28:3-5; àti 1 Johannu 5:16. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ lè túbọ̀ ṣàlàyé bí o ti lè tẹ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli tí wọ́n nítara lọ́rùn tó lati jẹ́ kí òye wọn nípa àwọn ohun tí a kọ sínú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun túbọ̀ gbòòrò, tàbí jinlẹ̀ sí i.