Akérékorò
ROBERT, ọ̀dọ́mọkùnrin kan láti Canada, rìn káàkiri Europe ní wíwá ète rẹ̀ nínú ìgbésí-ayé kiri. Ó rí ohun púpọ̀ tí ó mú kí ó nímọ̀lára àìnírètí nípa ọjọ́-ọ̀la.
Nígbà tí ó jókòó nínú ilé àrójẹ kan ní Seville, Spania, a fún Robert ní ìwé-àṣàrò-kúkúrú kan tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tẹ̀jáde. Lákọ̀ọ́kọ́, Robert ń ṣiyèméjì. Ó wí pé: “Síbẹ̀síbẹ̀ mo kà á. Èmi kò lè ṣàlàyé rẹ̀, ṣùgbọ́n mo nímọ̀lára pé rẹ́gí ṣe rẹ́gí. Lákòókò ìrìn-àjò mi, mo ti rí ọ̀pọ̀ oríṣiríṣi ìsoríkọ́ àti ìṣubú ẹ̀dá ènìyàn, ìjákulẹ̀ sì bá mi nítorí àìtóótun mi láti yí àwọn nǹkan padà. Lẹ́yìn kíka ìwé-àṣàrò-kúkúrú náà, mo ṣe kàyéfì pé, ‘Ó ha lè ṣeé ṣe kí “ayé titun” yìí wà bí?’ Lẹ́yìn náà, mo ronú pé, ‘Bẹ́ẹ̀ni, bóyá ó lè ṣeé ṣe.’”
Pẹ̀lú ìrètí tí a sọ dọ̀tun, Robert kọ̀wé sí ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní Canada, ní bíbèèrè pé kí ẹnì kan wá bẹ òun wò bí òun bá padà délé kí ó sì ran òun lọ́wọ́ láti lóye Bibeli.
Láìsí iyèméjì, ọ̀rọ̀ tí a sọ jáde lágbára. Bí ó ti wù kí ó rí, máṣe fojú kéré agbára ìhìn-iṣẹ́ tí a tẹ̀ sínú ìwé láé. Bí ó ti wù kí ó kéré tó, àwọn ìtẹ̀jáde tí a gbékarí Bibeli ní agbára ìfanimọ́ra. Wọ́n ń nípa lórí èrò-inú àti ọkàn-àyà, ní fífúnni ní ìrètí dídánilójú fún ọjọ́-ọ̀la.—Heberu 4:12.