ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 3/15 ojú ìwé 8-9
  • Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa Káàkiri Ayé—Zambia

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa Káàkiri Ayé—Zambia
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹgbẹ́ Àwọn Ará Kárí Ayé fún Mi Lókun
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Àrùn Éèdì Ní Áfíríkà—Àyípadà Rere Wo Ni Ẹgbẹ̀rúndún Tuntun Fẹ́ Mú Wá?
    Jí!—2000
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 3/15 ojú ìwé 8-9

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa Káàkiri Ayé—Zambia

PẸ̀TẸ́LẸ̀ salalu, tí ó ní gegele wà lórí òkè gogoro tí ó ga ní 1,200 mítà, tí orí rẹ̀ sì tẹ́ pẹrẹsẹ—Zambia nìyí, orílẹ̀-èdè kan tí ń bẹ ní àárín gbùngbùn ìhà gúúsù Africa. Ní àríwá ìlà-oòrùn, Òkè-Ńlá Muchinga fi 2,100 mítà ga. Odò Zambezi ńlá, tí ń sán àrá oníran àpéwò lórí Omi-Atòkè-Tàkìtì-Wálẹ̀ ti Victoria tí gbogbo ayé mọ̀, ni ó di èyí tí ó pọ̀jù lára bodè gúúsù orílẹ̀-èdè tí a filẹ̀ kámọ́ yìí. Onírúurú ẹ̀dá ni ó wà láàárín àwọn ènìyàn náà, tí wọ́n ní iye tí ó ju 70 ẹ̀yà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lọ. Èdè mẹ́jọ pàtàkì ni wọ́n ń sọ níhìn-ín, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ sì tún wà.

Ní 1911 èdè mìíràn bẹ̀rẹ̀ síí fìdí múlẹ̀ tí ó sì ń tàn kálẹ̀ ní Zambia. Àwọn àlejò mú àwọn ẹ̀dà Studies in the Scriptures wọlé, láti ìgbà náà sì ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti bẹ̀rẹ̀ síí sakun láti mú “èdè mímọ́ gaara” ti òtítọ́ Bibeli náà gbòòrò síi ní Zambia. (Sefaniah 3:9, NW) Àwọn ìgbàgbọ́ tí kò bá ìwé mímọ́ mu nípa ipò tí àwọn òkú wà jẹ́ ìpènijà pàtàkì. Ẹ wo bi àbájáde rẹ̀ ti ń mú òmìnira wá, nígbà tí àwọn ènìyàn bá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ tí wọ́n sì rí bí ẹ̀kọ́ èké ti sọ wọ́n dẹrú!—Johannu 8:32.

Fún àpẹẹrẹ, arábìnrin olùṣòtítọ́ kan ròyìn pé: “Nígbà tí ẹ̀gbọ́n ìyá mi kú lójijì, ìyá mi, tí ó jẹ́ ògbóǹtagì mẹ́ḿbà United Church ti Zambia, di ẹni tí a pinlẹ́mìí. Lẹ́yìn ààtò ìsìnkú ọlọ́sẹ̀ kan, mo padà lọ sí abúlé láti rí bí ó ti ń ṣe sí. Nígbà tí mo dé ibẹ̀, mo rí ọkùnrin àgbàlagbà kan nínú ilé, nígbà tí ó sì lọ tán, mo béèrè ẹni tí ó jẹ́ lọ́wọ́ ìyá mi àgbà. Ó sọ pé babaláwo ni. Ìyá mi ń wéwèé láti háyà rẹ̀ láti gbẹ̀san ikú ẹ̀gbọ́n rẹ̀ kí ẹ̀mí òkú náà baà lè sinmi. Bí ó ṣe sọ ọ́ gan-an, ó gbàgbọ́ pé ní báyìí ó ‘kàn ń rìn gbéregbère kiri ni.’

“Ìyá mi àgbà ṣàlàyé síwájú síi pé wíwá mi jẹ́ ìbùkún nítorí pé àwọn ẹbi ń wá owó tí wọn yóò san fún babaláwo náà. Ó ní kí n dáwó, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ mo ṣàlàyé fún un pé gẹ́gẹ́ bí Kristian, èmi kò lè kópa. Mo fọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ láti inú Orin Dafidi 146:4, tí ó fi hàn pé àwọn òkú kò ní èrò kankan—nítorí náà kò sí ọkàn kankan tí ‘ń rìn gbéregbère kiri.’ A tún gbé Romu 12:19 yẹ̀wò, tí ó tọ́ka sí kókó náà pé ti Jehofa ni ẹ̀san kì í ṣe tiwa. Lẹ́yìn náà, mo sọ fún màmá mi nípa ìrètí àjíǹde tí Jesu sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ nínú Johannu 5:28, 29. Ìgbàgbọ́ mi tí ó lágbára nínú àwọn ìlérí Ọlọrun wú u lórí. Láìpẹ́ ó bẹ̀rẹ̀ síí kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú Ẹlẹ́rìí kan ó sì tẹ̀síwájú lọ́nà tí ó yára kánkán. Ó já gbogbo ìdè pẹ̀lú ìsìn rẹ̀ àtijọ́ ó sì fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ rẹ̀ sí Ọlọrun hàn nípa ìrìbọmi. Nísinsìnyí ó ti di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa.”

Arábìnrin mìíràn ròyìn pé: “Mo lọ sí ibi ìsìnkú aya ẹ̀gbọ́n mi. Nígbà tí mo débẹ̀, mo bá ẹ̀gbọ́n mi àti ìbátan mi tí wọ́n ń febi pa ara wọn. Wọn kò tí ì jẹun láti ọjọ́ tí aya ẹ̀gbọ́n mi ti kú. Nígbà tí mo béèrè ìdí, wọ́n dáhùn pé gẹ́gẹ́ bí àṣà, wọn kò gbọdọ̀ dá iná láti se oúnjẹ. Mo yọ̀ọ̀da láti se oúnjẹ, ṣùgbọ́n àwọn kan lára mẹ́ḿbà ìdílé bẹ̀rù pé bí mo bá tẹ òfin àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ yìí lójú, gbogbo wa yóò ya wèrè!

“Mo ṣàlàyé pé gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, mo ní ọ̀wọ̀ fún ohun tí Bibeli sọ nínú Lefitiku 18:30 èmi kì í sìí tẹ̀lé àwọn àṣà tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu. Mo wá fi ìwé pẹlẹbẹ náà Ẹmi Awọn Oku hàn wọ́n. Pẹ̀lú èyí pákáǹleke náà rọlẹ̀, mo sì lọ se oúnjẹ fún ẹ̀gbọ́n mi àti àwọn ènìyàn tí ó kù. Ìgboyà tí mo ní jọ àwọn mọ̀lẹ́bí olóògbé náà lójú wọ́n sì gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli síwájú síi. Wọ́n ti di akéde tí kò tí ì ṣèrìbọmi báyìí, gbogbo ẹbí náà pátá sì ń retí láti ṣe ìrìbọmi láìpẹ́.”

Ẹ wo bí inú wa ti dùn tó nígbà tí èdè mímọ́ gaara òtítọ́ bá dojú ìdàrúdàpọ̀ ìsìn èké dé, pàápàá àwọn èrò tí ó ti fẹsẹ̀múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in tí ó ti mú àwọn aláìmọwọ́mẹsẹ̀ lẹ́rú! Pẹ̀lú ìbùkún Jehofa, èdè mímọ́ gaara náà ń tàn kálẹ̀ ní Zambia, àní bí ó ti rí jákèjádò ayé.—2 Korinti 10:4.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 9]

ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ NÍPA ORÍLẸ̀-ÈDÈ

Ọdún Iṣẹ́-Ìsìn 1994

GÓŃGÓ IYE ÀWỌN TÍ Ń JẸ́RÌÍ: 82,926

ÌṢIRÒ-ÌFIWÉRA: Ẹlẹ́rìí 1 sí 107

ÀWỌN TÍ WỌ́N PÉSẸ̀ SÍBI ÌṢE-ÌRÁNTÍ: 363,372

ÌPÍNDỌ́GBA ÀWỌN AKÉDE TÍ WỌ́N JẸ́ AṢÁÁJÚ-Ọ̀NÀ: 10,713

ÌPÍNDỌ́GBA ÀWỌN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BIBELI: 108,948

IYE TÍ A BATISÍ: 3,552

IYE ÀWỌN ÌJỌ: 2,027

Ọ́FÍÌSÌ Ẹ̀KA: LUSAKA

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Ilé lílò ti ẹ̀ka Watch Tower lẹ́yìn ìlú Lusaka

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Wíwàásù ní Shimabala, gúúsù Lusaka

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́