ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 4/1 ojú ìwé 3-4
  • Ìsìn Ọ̀rọ̀ Àìgbọdọ̀sọ Ha Ni Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìsìn Ọ̀rọ̀ Àìgbọdọ̀sọ Ha Ni Bí?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Isin Eyikeyii Ha Dara Tó Bi?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ṣíṣe Isin Mimọgaara fun Lilaaja
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016
  • Jija Àjàbọ́ Kuro Ninu Isin Èké
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 4/1 ojú ìwé 3-4

Ìsìn Ọ̀rọ̀ Àìgbọdọ̀sọ Ha Ni Bí?

“Ọ̀RỌ̀ méjì wà tí n kì í jíròrò: ìsìn àti ìṣèlú!” Èyí jẹ́ ìdáhùnpadà ìgbà gbogbo nígbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa bá ń bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa Bibeli. Ojú-ìwòye náà sì yéni.

Nígbà tí àwọn ènìyàn bá ń jiyàn lórí ìṣèlú, ọkàn ìbínú lè ru sókè kí aáwọ̀ sì jẹyọ. Ọ̀pọ̀ ni kì í jẹ́ kí a fi ìlérí asán tan àwọn jẹ wọ́n sì ti mọ̀ pé kìkì ohun tí àwọn olóṣèlú ń wá ní ọ̀pọ̀ ìgbà ni agbára, òkìkí, àti owó. Ó ṣeni láàánú pé, àìfohùnṣọ̀kan wọn lórí ọ̀ràn ìṣèlú máa ń yọrí sí ìwà-ipá nígbà mìíràn.

O lè ronú pé, ‘Ṣùgbọ́n ohun kan náà kò ha jẹ́ òtítọ́ nípa ìsìn bí? Ìgbóná-ọkàn nípa ìsìn kò ha ti tannáran ọ̀pọ̀ ìforígbárí lóde òní bí?’ Ní Northern Ireland, ìsìn Roman Katoliki àti Protẹstanti ti ń bá ara wọn ṣorogún tipẹ́. Ní àwọn orílẹ̀-èdè Balkan, àwọn mẹ́ḿbà Ṣọ́ọ̀ṣì Orthodox Ìlà-Oòrùn, Roman Katoliki, àti àwọn mìíràn ń jìjàdù fún àgbègbè ìpínlẹ̀. Kí ni ìyọrísí rẹ̀? Ìwà-ìkà àti inú burúkú.

Ọ̀pọ̀ ń gbìyànjú láti fi èrò-ìgbàgbọ́ tiwọn alára àti ti àwọn ìdílé wọn pamọ́, nítorí pé a ti fi ikú halẹ̀ mọ́ wọn. Ní Africa, àwọn ọ̀rúndún ìkóguntini ìsìn láàárín àwọn ènìyàn Kristẹndọm àti àwọn alágbàwí ìsìn ilẹ̀-òkèèrè àti ti ìbílẹ̀ pẹ̀lú ti sún àwọn òbí láti fún àwọn ọmọ wọn ní orúkọ méjì tí ń mú ìwọ̀n ààbò díẹ̀ wá, àṣà kan tí ń bá a lọ lónìí. Nípa bẹ́ẹ̀, ọmọdékùnrin kan lè pe ara rẹ̀ ní mẹ́ḿbà ṣọ́ọ̀ṣì kan tàbí kí ó sọ pé òun jẹ́ ti ìsìn mìíràn nípa lílo ọ̀kan nínú orúkọ náà. Nígbà tí èrò-ìgbàgbọ́ ìsìn ẹnì kan bá lè ná an ní ẹ̀mí rẹ̀, abájọ tí ó fi ń lọ́ra láti jíròrò nípa ìsìn ní gbangba.

Ní ojú àwọn ẹlòmíràn, ọ̀rọ̀ àìgbọdọ̀sọ ni ìsìn jẹ́ àní bí ẹ̀mí wọn kò tilẹ̀ sí nínú ewu. Wọ́n ń bẹ̀rù pé sísọ̀rọ̀ nípa èrò-ìgbàgbọ́ wọn pẹ̀lú ẹnì kan tí ó ní ìgbàgbọ́ tí ó yàtọ̀ yóò yọrísí àríyànjiyàn tí kò nítumọ̀. Síbẹ̀ àwọn mìíràn gbàgbọ́ pé gbogbo ìsìn ni ó dára. Wọ́n sọ pé, níwọ̀n bí ohun tí ẹnì kan gbàgbọ́ bá ti tẹ́ ẹ lọ́rùn, sísọ̀rọ̀ nípa ìyàtọ̀ jẹ́ ohun tí kò wúlò.

Àwọn ògbóǹtagí akẹ́kọ̀ọ́ nípa bí ìsìn ti rí ni ẹnu wọn kò kò láàárín ara wọn. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica jẹ́wọ́ nínú ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ rẹ̀, “The Study and Classification of Religions” (Ẹ̀kọ́ Ìsìn àti Pípín In sí Ìsọ̀rí), pé: “Ṣàṣà . . . ni ìgbà tí ìṣọ̀kan tí ì wà láàárín àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nípa bí [ìsìn] ti rí . . . Nípa báyìí, kókò ọ̀rọ̀ náà, jákèjádò ìtàn rẹ̀, ní awuyewuye nínú.”

Ìwé atúmọ̀-èdè kan túmọ̀ ìsìn gẹ́gẹ́ bí “ìsọjáde èrò-ìgbàgbọ́ ènìyàn àti ìfọ̀wọ̀hàn fún agbára kan tí ó ju ti ẹ̀dá lọ tí a mọ̀ pé ó jẹ́ ẹlẹ́dàá àti alákòóso àgbáyé.” Èyí yóò béèrè pé kí ìsìn kó ipa pàtàkì nínú ìgbésí-ayé. Nítòótọ́, ìsìn ti jẹ́ kókó abájọ ti gbogbogbòò nínú dídarí ìtàn ẹ̀dá ènìyàn. Ìwé gbédègbéyọ̀ Oxford Illustrated Encyclopedia of Peoples and Cultures sọ pé: “Kò tíì sí ẹgbẹ́ àwùjọ kankan tí kò tí ì wá bí ìgbésí-ayé yóò ṣe wà létòlétò tí yóò sì ní ìtumọ̀ nípasẹ̀ irú ìsìn kan.” Nítorí ó wémọ́ àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì bí ‘wíwà létòlétò’ àti “ìtumọ̀” ìgbésí-ayé, dájúdájú ìsìn yóò ní ẹ̀tọ́ sí ohun mìíràn ju ìjiyàn lọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ ní jíjíròrò—ìyẹn ni pé, gbígbé e yẹ̀wò fínnífínní—pẹ̀lú ẹlòmíràn. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ta ni, ohun rere wo ni ó sì lè ti inú rẹ̀ jáde?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́